Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí mẹ́jọ lórí jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ọbalayé gbé ní Ekiti

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti ni awọn ti mu afurasi mẹjọ lori bi awọn amokunṣeka ẹda kan ṣe ṣekupa ọbalaye meji ni ipinlẹ naa ati bi awọn ajinigbe ṣe ji awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan ni ipinlẹ naa laipẹ yii.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, ọwọja ikọlu awọn ajinigbe atawọn amokunṣika ẹda ni ipinlẹ Ekiti ti di eyi to n kọ ọpọlọpọ lominu.

Ni ọjọ kọkadinlọgbọn, awọn agbebọn kan gbẹmi lẹnu ọbalaye meji kan ni ipinlẹ naa – Onimojo ilu Imojo, ba Ọlatunde Oluṣọla ati Ẹlẹsun ti Ẹsun Ekiti, Ọba Babatunde Ogunṣakin.

Bakan naa ni awọn ajinigbe tun kọlu ọkọ bọọsi to n ko awọn akẹkọọ ile ẹkọ kan ti wọn si ko akẹkọọ marun un, olukọ mẹta ati dẹrẹba to wa ọkọ naa.

Ninu ọrọ to sọ lọjọ Aiku, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa lasiko ti agbajọpọ awọn oṣiṣẹ agbofinro kanlu awọn igbo Emure Ekiti, igbo Isẹ/Ọgbẹsẹ siEmure Ile ni ipinlẹ Ondo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu ṣalaye pe Awọn ọlọpaa, ati ikọ amọtẹkun lati ipinlẹ Ekiti ati Ondo, fijilante, ọlọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ agbẹkọya ni wọn lọwọ ninu mimu awọn afurasi naa.

Awọn afurasi ti ọwọ tẹ naa ni Yaya Sumaila, Idrisu Abubakar, Hassan Abudullahi, Abudullahi Abudullahi, Haruna Abubakar, Usman Abudullahi, Haruna Sule ati Babusa Alhaji Lede ti ọwọ ba ninu igbo kijikiji Ayedun/Ayebọde Ekiti ni agbegbe ikọle.

Ìjọba Ekiti sọ̀rọ̀ lórí àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé
Aworan Gomina ipinlẹ Ekiti

Gomina Biọdun Oyebanji ti ipinlẹ Ekiti ti dupẹ lọwọ Aarẹ orileede Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu, awọn oṣiṣẹ eleto aabo patapata ati gbogbo ọmọ Ekiti lori itusilẹ awọn akẹkọọ ti wọn wa lahamọ awọn ajinigbe.

Oyebanji lo sọrọ idupẹ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Ọlayinka Oyebọde fi lede laarọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun 2024.

Atẹjade yi tẹ awọn akọroyin lọwọ laipẹ si igba ti awọn akẹkọọ ọhun gba itusilẹ.

Laipẹ yii ni awọn ajinigbe da awọn akẹkọọ ileẹkọ alakọbẹrẹ ti Apostolic Faith to wa niluu Emure Ekiti lọna, ti wọn si ji wọn gbe pẹlu awakọ bọọsi ati awọn olukọ wọn.

Gomina nigba to n ba awọn akẹkọọ ati awọn obi wọn yọ, sọ pe asiko ti to lati tubọ gbajumọ ọrọ eto aabo nipinlẹ naa.

Oyebanji sọ pe awọn ajinigbe yii pa awakọ bọọsi to ko awọn ọmọ yii lasiko ijinigbe naa si ahamọ wọn.

Bakan naa lo paṣẹ pe ki Kọmiṣana feto ilera nipinlẹ Ekiti, Dokita Oyebanji Filani ko awọn akẹkọ naa lọ si ile iwosan olukọni to wa niluu Ado-Ekiti fun itọju to peye

Fonran fidio to wa niṣalẹ yi lo ṣafihan awọn akẹkọọ to moribọ lọwọ ajinigbe.

Àkọlé fídíò, Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ekiti padà gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Gomina ṣalaye pe awọn ko ni sinmi lati ṣawari awọn aṣekupani to gbẹmi awọn oriade meji ni ipinlẹ naa.

O rọ awọn araalu lati ma sun gbagbera ni paapa ki wọn si yara ta awọn agbofinro lolobo ti wọn ba kẹfin awọn to n rin kurekurẹ layika wọn.

Aworan awọn akẹkọọ to bọ lọwọ ajinigbe

Oríṣun àwòrán, BBC

Báyìí láwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ekiti ṣe padà gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Aworan awọn akẹkọọ́ to gba itusilẹ lọwọ ajinigbe

Iroyin to n tẹwa lọwọ bayii sọ pe awọn ọmọ ileẹkọ the Apostolic Faith Apostolic Montessori School Emure Ekiti ti won jigbe ti gba itusilẹ.

Awọn ọmọ ileẹkọ naa moribọ kuro ni akata awọn ajinigbe ni deede ago meji oru ọjọ isinmi Aiku.

Ọkan lara awọn molebi ọmọ ti wọn jigbe ati osise ọgba ile iwe naa fidi rẹ mulẹ fun akoroyin wa.

Awọn ti wọn jigbe yii, akẹkọọ marun un, olukọ obinrin meji ati awakọ ni wọn ko si ọwọ awọn ajinigbe nigba ti wọn n dari ile ẹkọ pada nirọlẹ ọjọ Aje to kọja.

BBC ti ri fọnran fidio to ṣafihan awọn to gba itusilẹ yi eleyi ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa fi sọwọ si akọroyin wa.

Ninu fọnran yi, awọn akẹkọọ naa ati olukọ wọn bu taki pẹlu eruku.

Awọn kan dori kodo ṣugbọn ko si ẹni to jọ pe o ni apa kankan lara ninu wọn.

Dirẹba padanu ẹmi rẹ lọwọ awọn alaburu

Iroyinti ṣaaju tan kalẹ lori ayelujara lale ọjọ Ẹti pe awọn ajinigbe ti tu awọn ọmọ ile ẹkọ naa silẹ leyin ọjọ mẹrin ni akata wọn.

Nigba ti BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn osise ile ẹkọ naa, oṣiṣẹ ọhun ti ko fẹ ki a da orukọ oun fidi rẹ mulẹ pe irọ tojina si otọ ni iroyin naa.

Amọ bayii awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa ti fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹkọọ yi ti gba itusilẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti bakan naa fidi ọrọ yi mulẹ.

Alex Abutu to jẹ alukoro ọlọpaa sọ pe gbogbo awọn to wa ni akata ajinigbe lo ti gba itusilẹ bayii.

Amọ o sọ pe dirẹba ọkọ naa ko dari pada laaye.

O ni awọn fura si pe awọn ajinigbe naa lo ṣeku pa.

Abutu ko sọrọ boya wn koju awọn ajinigbe naa ni ki wọn to tu awọn akẹkọọ yi silẹ tabi wọn san owo idoola ẹmi.

Aworan awọn olukọ ati akẹkọọ ti ajinigbe ji gbe l'Ekiti

Ijinigbe ti gbogo ni Naijiria bayii

Ọrọ ijinigbe lẹnu lọọlọ yi ti wa fẹ peleke lorileede Naijiria.

Bi awọn alaburu yi ṣe n ji awọn akẹkọọ, bẹẹ naa ni wọn tun ji awọn oriade gbe.

Laarin ọṣẹ to kọja yi, awọn ajinigbe ṣeku pa Kabiyesi kan ni ipinlẹ Kwara ti wọn si tun ji olori rẹ ati eeyan kan gbe salọ.

Eleyi n waye ni ko pẹ sigba ti awọn ajinigbe mii soro ni ipinlẹ Ekiti nipa pipa awọn oriade meji ni aafin wọn ti wọn si na papa bora.

Jakejado Naijiria ni irufẹ iṣẹlẹ yi ti n waye pẹlu awọn ipenija aabo mii eleyi to mu ki awọn onwoye maa ke gbajare si ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣada lori iṣẹlẹ yii.