Mbumba di ààrẹ Namibia tuntun lẹ́yìn ikú Geingob

Aworan Nangolo Mbumba

Oríṣun àwòrán, X/The Brief

Igbakeji Aarẹ ati adele aarẹ lorilẹede Namibia, Nangolo Mbumba ni wọn kede gẹgẹ bii Aarẹ tuntun fun orilẹede Namibia lẹyin ti Aarẹ Hage Geingob jade laye ni ile iwosan.

Mbumba, ẹni to jẹ igbakeji aarẹ tẹlẹ se iburawọle naa ni ile ijọba, to si di Aarẹ kẹrin fun orilẹede Namibia.

Bakan naa ni Netumbo Nandi Nandi Ndaitwah naa se iburawọle gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ lẹsẹkẹsẹ.

Ninu ọrọ rẹ lẹyin eto iburawọle, Aarẹ Mbumna kan sara si Aarẹ ana to di oloogbe, to si sapejuwe rẹ gẹgẹ olori awọn to tun orilẹede Namibia se nipasẹ ofin ilu ati oṣelu.

Ni bayii, Mbumba yoo lewaju fun orilẹede Namibia fun oṣu mẹsan an ki eto idibo Aarẹ to waye.

Ààrẹ Namibia jáde láyé, Wo ohun márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀

Aworan Hage Geingob

Oríṣun àwòrán, Hage Geingob/BBC

Aarẹ orileede Namibia, Hage Geingob ti jade laye.

Geingob, ẹni ọdun mejilelọgọrin jade laye nibi to ti n gba itọju fun aisan jẹjẹrẹ to n ba finra lati bi ọdun meloo kan sẹyin.

Ile iwosan kan to wa ni ilu Windhoek ni Geingob ku si, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Igbakeji Aarẹ, Nangolo Mbumba lo kede iku Aarẹ Geingob laarọ oni, ọjọ Aiku, Sannde.

“Lẹgbẹ rẹ ni iyawo rẹ, Madame Monica Geingos ati awọn ọmọ rẹ.”

Oṣu to kọja ni wọn kede sita fun gbogbo araalu wi pe aisan jẹjẹrẹ n ba oloogbe naa finra.

Ṣaaju ni ileeṣẹ aarẹ ti kede sita wi pe Aarẹ naa yii maa lọ si ilẹ Amẹrika lati lọ gba itọju, ṣugbọn ti yoo pada si Namibia lọjọ keji, oṣu keji.

Ọdun 2015 ni Geingob di aarẹ, to si tun ti bẹrẹ saa keji rẹ to gbẹyin ko to di pe o jade laye.

Geingob, lọdun to kọja lọ fun iṣẹ abẹ, ati pe ọdun 2014 lo ṣalaye wi pe oun yoo bọ kuro lọwọ aisan jẹjẹrẹ yii.

Inu oṣu kọkanla ni orileede Namibia fẹẹ ṣe eto idibo lati yan aarẹ miran.

Ẹgbẹ oṣelu Swapo to ti n ṣe ijọba latigba ti wọn ti gba ominira lọdun 1990 ti yan Arabinrin Nandi-Ndaitwah gẹgẹ bi ọmọ oye ti yoo ṣoju wọn lasiko eto idibo miran.

Nandi-Ndaitwah to jẹ igbakeji olootu ijọba ni yoo jẹ aarẹ obinrin akọkọ, iyẹn wọn ba dibo yan an.

Taa ni Hage Geingob?

  • Ọdun 2015 ni Geingob di Aarẹ orilẹede Namibia, to si jade laye ni saa keji rẹ.
  • Ẹni ọdun mejilelọgọrin ni Aarẹ naa ko to jade laye.
  • Oun ni aarẹ kẹta fun orilẹede Namibia
  • Ọdun mẹtadinlọgbọn ni Geingob fi ṣe atipo ni orilẹede Botswana, Amẹrika ati Ilẹ UK, nibi to ka iwe gboye PHD ni imọ oṣelu.
  • O pada si orilẹede Namibia ni ọdun 1989, to si jẹ olootu ijọba Namibia to pẹ ju lori ijọba.