Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ, àwọn ọmọọba yọ àwọn afọbajẹ lóyè ní Ipetumodu, ta ní yóò yan ọba tuntun?

Oríṣun àwòrán, @BRITOCURRENCY
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí olóde kò kú, ìta rẹ̀ kò le hu kórikó.
Níṣe ni ọ̀rọ̀ oyè Apetumodu ti ìlú Ipetumodu ní ìpínlẹ̀ Osun tún gba ọ̀nà míì yọ pẹ̀lú ìpàdé táwọn afọbajẹ àtàwọn ọmọ oyè ìlú náà ṣe.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹsàn-án ni ìpàdé wáyé láàárín àwọn Afọbajẹ ìlú Ipetumodu àtàwọn ọmọọba ìlú náà lórí ohun tí yóò wáyé lórí ọ̀rọ̀ oyè ọba ìlú náà.
Ẹ ó rántí pé láìpẹ́ yìí ni ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ju Ọba Joseph Oloyede tó jẹ́ Apetumodu ìlú Ipetumodu si ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin fẹ́sùn pé ó ṣe èrú owó lásìkò tí àìsàn COVID-19 ń bá gbogbo ayé fínra.
Láti ìgbà náà ni awuyewuye ti ń wáyé lórí kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lórí ìtẹ́ Apetumodu?
Báwọn kan ṣe ń bèèrè pé ṣe ìtẹ́ náà yóò wà lófo tí Ọba Oloyede yóò fi parí sáà rẹ̀ lẹ́wọ̀n ni àwọn míràn ní wọ́n gbọdọ̀ yan ọba míì láti má jẹ̀ ẹ́ kí ìtẹ́ ọba wà lófo.
Èyí ló bí ìpàdé tó wáyé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun láàárín àwọn afọbajẹ àtàwọn ọmọọba ìlú Ipetumodu láti mọ ohun tí ó kàn fún wọn.
Olóyè Sunday Adedeji tó jẹ́ Asalu ìlú Ipetumodu tó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn afọbajẹ ìlú náà sọ fún BBC News Yorùbá pé, oṣooṣù ni àwọn máa ń ṣe ìpàdé náà lórí ọ̀rọ̀ ọba náà.
"Àwọn afọbajẹ méjì ló kù láyé nínú àwa mẹ́rin, àwọn méjì ti kú, ó ku àwa méjì.
"Ohun tí wọ́n sọ ni pé àwa méjéèjì tí a kù, àwọn yọ wá gẹ́gẹ́ bí afọbajẹ."
Olóyè Adedeji ṣàlàyé pé àwọn ọmọọba sọ fún àwọn níbi ìpàdé náà pé àwọn kò fẹ́ àwọn mọ́ gẹ́gẹ́ bí afọbajẹ, pé wọ́n máa yan àwọn ẹlòmíràn láti rọ́pò wọn.
Ó ní ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró báyìí ni pé àwọn ọmọọba ni yóò yan ọba míì fúnra wọn.
Kí lọ fà á tí àwọn ọmọọba fi yọ àwọn afọbajẹ nípò?
Ọ̀kan lára àwọn ọmọọba ìlú Ipetumodu, Olaboye Ayoola sọ fún BBC News Yoruba pé àwọn ìdílé méjéèjì ìyẹn ìdílé Fagbemokun àti Aribile tó ń jẹ oyè Apetumodu ló pe ìpàdé tó wáyé náà.
Ayoola ní gbogbo àwọn ọmọọba ni wọ́n bínú tí wọ́n sì di ẹ̀bi bí wọn kò ṣe tíì mọ odó tí wọ́n máa da ọ̀rúnlá sí lórí ọ̀rọ̀ oyè Apetumodu sí ru àwọn afọbajẹ.
Ó ní èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ọmọọba ti sọ fún àwọn afọbajẹ pàápàá olóyè Sunday Adedeji láti kọ̀wé sí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun láti kéde ipò Apetumodu gẹ́gẹ́ bí èyí tó ṣófo nígbà tí ìròyìn ti gbòde pé Amẹ́ríkà ti sọ ọba wọn sẹ́wọ̀n.
Ó sọ pé olóyè Adedeji kọ̀ láti ṣe èyí pẹ̀lú àlàyé pé àyàfi tí òun bá rí ìwé láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ọba náà ti wà lẹ́wọ̀n.
Ó ní èyí ló mú kí àwọn ọmọọba fi dìbò pé àwọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú olóyè Adedeji mọ́ gẹ́gẹ́ bí afọbajẹ ìlú Ipetumodu tí òun náà sì gbà bẹ́ẹ̀ pé oyè Asalu ni òun yóò máa jẹ́, òun kò gbà láti jẹ́ Afọbajẹ ìlú náà mọ́.
Ó fi kun pé níbi ìpàdé náà ni wọ́n tún ti fẹnukò pé àwọn kò ní ṣe ayẹyẹ ọdún Ipetumodu tó máa ń wáyé ní ọdọọdún àyàfi tí wọ́n bá yan Apetumodu míì.
Kí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Osun sọ?
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí Kọmíṣánnà fún ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Osun, Dosu Babatunde sọ pé ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti bèèrè fún ìwé ìdájọ́ lórí ọba Joseph Oloyede.
Babatunde ní láì bá ṣe pé àwọn rí ìwé ìdájọ́ láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àwọn kò ní lè gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí ọ̀rọ̀ náà.
"A ti kọ̀wé sí iléeṣẹ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó wà ní Nàìjíríà láti rí ìwé tí wọ́n fi ṣe ìdájọ́ ọba náà, ìgbésẹ̀ tí à ń gbé lọ́wọ́ yìì nìyẹn."
Ipò wo ni àwọn oníṣẹ̀ṣe kọ sí ọ̀rọ̀ yìí?
Ifagbenusola Atanda, tó jẹ́ Asiwaju Awo Agbaye ṣàlàyé pé Ifa ló máa ń yan ọba ní ayé àtijọ́ láti mọ ọmọ oyè tí ọba bá kàn ní ìdílé kan.
Ó ní ìgbà tí ojú ṣàájú bẹ̀rẹ̀ láàárín ilé sí ilé ni ìjọba gbé òfin kalẹ̀ láti ṣe òfin láàárín àwọn ìdílé tó ń jọba.
Ó wòye pé lóde òní, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yan ọba tán ó pọn dandan láti máa dá ifa fún ọba ní gbogbo ìgbà láti ri pé àwọn tí wọ́n bá ń sà sí ọba kò ní wá sí ìmúṣẹ.
Ó fi kun pé tí irúfẹ́ èyí kò bá máa wáyé fún ọba nígbà gbogbo, kò sí bí Ifa ṣe lè fọ rere tó lórí onítọ̀hún kó tó jẹe ọba, ọ ṣeéṣe kí ìṣubú wà fún ọba bẹ́ẹ̀ lórí ìtẹ́.
Asiwaju Awo Agbaye ní ohun tó wáyé ní ìlú Ipetumodu gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìṣẹ̀ṣe ṣe là á kalẹ̀ fún ẹni tó bá jẹ́ ọba, kò yẹ kí ọba náà de ipò mọ́ àti pé ó nílò láti ṣe ètùtù láti bẹ àwọn alálẹ̀ nítorí àbùkù ló ti kó bá ààyè náà.
Ó ní ipò ọba jẹ́ ipò tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òrìṣà, tó sì jẹ́ pé ó ní àwọn ìwà tí èèyàn gbọdọ̀ máa bá lọ́wọ́ ẹni tó bá di ipò ọba mú nílẹ̀ Yorùbá.















