Ẹ wo ìgbésẹ̀ tí àwọn afọbajẹ ìlú Ipetumodu fẹ́ gbé lẹ́yìn tí ọba wọn dèrò ẹ̀wọ̀n l'Amẹrika

Ọba Joseph Oloyede pẹlu ade lori, ilẹkẹ lọrun ati agbada funfun.

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Ọmọ Naijiria ati ilẹ Amẹrika ni Joseph Oloyede, to jẹ ẹni ọdun mejilelọgọta, to si n gbe niluu Medina, to wa ni Ohio orilẹede Amerika, ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

‎ Olori awọn afobaje niluu Ipetumodu, Oloye Afolabi Adedeji, ti sọ pe iroyin to ni Apetu ti ilu Ipetumodu nipinlẹ Osun, Ọba Joseph Oloyede, ti dero ẹwọn lorilẹede Amẹrika.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni iroyin naa jade, eyi to ṣalaye pe Ile ẹjọ kan l'Amẹrika ju Ọba Oloyede si ẹwọn ọdun mẹrin lori ẹsun lilu jibiti owo iranwọ Covid-19 ti iye rẹ le ni miliọnu mẹrin dọla.

Amọ, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, olori awọn afọbajẹ ni iyanlẹnu ni iroyin

naa jẹ fun oun nitori oun ati ori ade naa si ji sọrọ ni ibẹrẹ ọsẹ yii.

Oloye Adedeji ni ko si igbesẹ kankan ti awọn oloye le gbe bayii, nitori awọn n duro de nnkan ti ijọba ipinlẹ Osun yoo ṣe.

Oloye naa ni awọn ti fi ọrọ ọhun to komiṣana to wa fun yiyan ọba ni ipinlẹ Osun leti.

O ni nnkan ti komiṣana sọ ni pe, awọn ni lati ri iwe ẹjọ to sọ ọba Oloyede si ẹwọn ni orile-ede Amẹrika ki awọn to mọ igbesẹ to kan lati gbe.

‎‎Ilu Ipetumodu kii yan adele ọba, awọn oloye ni yoo maa ṣe eto isakoso ilu lọ titi ijọba yoo fi sọ igbesẹ to kan lori ọrọ Ọba Oloyede to wa lẹwọn l'Amẹrika.

Ọrọ lori aafin ti Ọba Oloyede wo lulẹ

Ile ori oke fẹgbẹ kan ile ilẹ nibi ti Ọba Joseph Oloyede n kọ aafin igbalode si niluu Ipetumodu
Àkọlé àwòrán, Olori awọn afọbajẹ ilu Ipetumodu ni igbimọ to n ṣiṣẹ lori kíkọ aafin igbalode naa yoo tẹsiwaju iṣẹ wọn nitori owo si wa nilẹ lati maa ba iṣẹ naa lọ.

Lori ọrọ aafin ti ọba Oloyede wo lulẹ lati kọ aafin igbalode, Oloye Adedeji ni igbimọ to n ṣiṣẹ lori kíkọ aafin igbalode naa yoo tẹsiwaju iṣẹ wọn nitori owo si wa nilẹ lati maa ba iṣẹ naa lọ.

‎Oloye Adedeji wa rọ gbogbo ọmọbibi Ipetumodu ati gbogbo awọn to n gbe ilu naa pe ki wọn ma ṣe fa wahala lori nnkan to ṣẹlẹ.

Ọrọ idile afọbajẹ keji niluu Ipetumodu

Olaboye Ayoola to wa lati idile Keji to n jọba nilu Ipetumodu, salaye pe, ko si ohun ti eeyan ba fi ọna eeru ko jọ, ti yoo tọjọ.

Ọgbẹni Ayoola ni eleyii lo fa ohun to sẹlẹ si ilu Ipetumodu bayii lori ọrọ ọba Oloyede.

‎''Idile wa ni ọba kan nigba naa, ti gbogbo ara ilu Ipetumodu si mọ pe idile wa ni ọba tọ si. Sugbọn awọn afobajẹ sọ pe idile wa ko ni owo lọwọ.

‎Ko si ẹni to fọwọ si yiyan Ọba Joseph Oloyede si ipo ọba ninu gbogbo idile Aribile lapapọ.

Wọn fi ọwọ ọla gba idile Aribile loju nigba naa ni.

‎Ohun ti awọn afobajẹ ṣe nigba naa lo ti di egan fun gbogbo ọmọbibi ilu Ipetumodu bayii,'' Ọgbẹni Ayoola lo sọ bẹẹ.

Ki ni araalu ilu Ipetumodu sọ lori ọba wọn to dero ẹwọn?

Ọkan lara ọmọ ilu Ipetumodu (ti a fi orukọ bo ni aṣiri) sọ pe eti kunkun awọn afobajẹ nigba ti wọn fi Ọba Olyede joye lo fa itiju fun gbogbo ọmọ ilu Ipetumodu bayii.

‎O ni ariwo Ifa ko mu talaka fi jẹ ọba mọ, awọn onidọla ni Ifa n mu lode oni ni awọn afobajẹ n pa nigba naa.

‎Onitọhun ni, to ba jẹ pe Ifa ni awọn afobajẹ fi yan ọba lasiko naa ni, nnkan ko ni ri bo ṣe ri lonii.

‎''Bi a ba pinnu lati gba Ọba Oloyede pada to ba de lati ọgba ẹwọn, awa araalu jẹri ijọba wi pe, wọn ko ni gba lati jẹ ki o pada si ori apere naa mọ.''

‎O ni oun gba awọn afobajẹ ni imọran pe ki wọn pada si idi isẹṣe lati maa fi Ifa yan ọba sori ipo.

"Ko yẹ ki wọn ko ọrọ Ifa danu nipa yiyan ọba sori itẹ ki iru idojutini to waye bayii ni Ipetumodu ma ba waye mọ lọjọ iwaju."