Àlàyé nípa ọdún Amólè, tó jẹ́ ọjọ́ tí ìlú yóò kó ọjà ẹnikẹ́ni tó bá ṣí ṣọ́ọ̀bù

Deji ti Ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi to wọ agbada pẹlu fila lori ati ilẹkọ lọrun

Oríṣun àwòrán, Micheal Adeyeye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọdun Amole ti waye niluu Akure, nipinlẹ Ondo, nibi ti ẹnikẹni ko ti gbọdọ ṣi ṣọọbu tabi ta ọja kaakiri ilu naa.

Gẹgẹ bii aṣa ilu Akure, ko si ẹni to gbọ ṣi ṣọọbu tabi ọja lasiko ọdun naa titi ti ọdun ọhun yoo fi pari.

Asiko ọdun naa lawọn oloye ilu fi maa n korajọ lati ṣetutu ti wọn yoo si gbadura fun alaafi ati itẹsiwaju ilu Akure.

Awọn ti ofin ṣọọbu titi yii ko kan

Agbẹnusọ Deji ti iku Akure, Micheal Adeyeye sọ ninu atẹjade kan pe gbogbo ṣọọbu lo gbọdọ wa ni titi pa amọ ọrọ naa ko kan awọn ṣọọbu kan.

Atẹjade naa ni "Titi pa awọn ile itaja yii jẹ ọkan lara awọn aṣa ti a gbọdọ tẹle lasiko ọdun Amole.

"Ko ni si aye fun ṣiṣi ọja, ṣọọbu, awọn ile itaja igbalode, tabi awọn ọja iwaju ile lasiko ọdun naa.

"A rọ gbogbo olugbe ilu Akure, awọn iyalọja atawọn to ni ṣọọbu lati tẹle aṣẹ yii lasiko ọdun naa.

"Bo tilẹ jẹ pe ọrọ yii ko kan awọn ṣọọbu ti wọn ti n ta oogun, afin ko ni faye gba ohunkohun to jọ mọ ọja tita tabi owo ṣiṣe."

Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn to ba kọti ọgbọin si aṣẹ yii?

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ Kabiesi Deji ti ilu Akure, o ni ẹnikẹni to ba kọti ikun si aṣẹ naa yoo padanu ọja rẹ.

O ni "Ọdun yii yatọ si ọdun Dududu, amọ o fẹ jọ ara wọn.

"Niṣe ni wọn maa ko ọja ẹni to ba tapa si aṣẹ to rọ mọ ọdun yii."

Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati maṣẹ kọ eti ikun si aṣẹ kaa ki gbogbo nnkan le lọ bo ṣe yẹ.

Ipa ti ọdun yii ni lara awọn oniṣowo

Wayi o, awọn oniṣowo kan nilu Akure ti bẹrẹ si n sọrọ lori ipa ti aṣa ọja titi yii n ko lori owo wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe oṣu to kọja ni wọn ṣe ọdun Aheregbe niluu Akure yii kan naa nibi ti wọn ti gbe agadagodo si gbogbo ṣọọbu ilu naa.

BBC Yoruba kan si ọgbẹni Duduyemi Julius, to jẹ ọkan lara oniṣowo to n ẹrọ ibaraẹnisọrọ niluu Akure, o ni ṣọọbu ti wọn ti pa yoo ṣe akoba fun owo oun .

Duduyemi sọ fun BBC Yoruba pe "Ootọ ni o, a o ṣi ṣọọbu lonii, wọn ti ba ọja jẹ fun wa lonii.

"Owo to yẹ ki a pa wọle lonii yi ti lọ niyẹn.

"Amọ ṣa, kii ṣe igba akọkọ ti wọn maa ti ọja ree, ọdọdun ni wọn maa n ti ọja, ṣebi ọjọ kan pere ni."