Ìrìnàjò ayé mi le débi í pé, ẹ ò le fí mi yangàn - Baba Londoner

Àkọlé fídíò,
Ìrìnàjò ayé mi le débi í pé, ẹ ò le fí mi yangàn - Baba Londoner

Odu ti ti kii ṣe aimọ fun oloko ni gbajumọ oṣere, Muyiwa Adegoke ti ọpọ ololufẹ rẹ tun mọ si Baba Londoner tabi Muyiwa Londoner.

Ẹni ti ko ba mọ ọ fun bo ṣe ma n paayan lẹẹrin, yoo mọ ọ fun bo ṣe ma n fi oko ọrọ ati eebu dani laraya ninu awọn ere to n ṣe.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agba oṣere yii, o sọ fun BBC bo ṣe bẹrẹ irinajo rẹ l'agbo ere tiata ati ibi to de duro.

Baba Londoner - o wọ aṣọ dudu pẹlu igo loju rẹ ati ẹgba ọrun
Àkọlé àwòrán, Muyiwa Adegoke 'Londoner' gbajumọ fun eebu ati awada ṣiṣe ninu ere

Alagba Muyiwa Adegoek sọ fun BBC News Yoruba pe ibẹrẹ igbeaye oun nira pupọ, debii pe oun kii ṣe ẹni to ṣe e fi yangan ni awujọ.

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Muyiwa Londoner sọ pe ọjọ ti pẹ ti oun ti n ṣe iṣẹ tiata, amọ oun ko fi bẹẹ kawe.

"Ko sẹ ni to le fi mi yangan nigba ti mo ṣi n jẹ 'Muyiwa' nitori pe mo n san-na-ni ara gan an."

Bakan naa lo ṣapejuwe iṣẹ tiata gẹgẹ bi igi ọpẹ, to ni oriṣiriṣi ẹya ti ọpọ eeyan le ko ipa to ba wọn mu.

Lori bo ṣe ma n paayan lẹẹrin, o ni wahala ati idaamu ti awọn ọmọ Naijiria n koju pọ, ti oun si ma n fi ere oun tu wọn ninu.

O ni oun fẹran iṣẹ tiata debi i pe, oun o sọ fun awọn ọmọ oun pe ki wọn o fi posi oku oun ya fiimu ṣaaju isinku.