Àìrí iṣẹ́ ṣe kọ́ ló sọ mi di ẹni tó ń ṣẹ̀fẹ̀ lórí ayélujára- Folagade Banks

Àkọlé fídíò, Mama Deola
Àìrí iṣẹ́ ṣe kọ́ ló sọ mi di ẹni tó ń ṣẹ̀fẹ̀ lórí ayélujára- Folagade Banks

Adẹrinpoṣonu to n gba oriṣi ọna da awọn eeyan lara ya ni Folagade Banks ti ọpọ eeyan mọ si Mama Deola, lori ayelujara.

Idi ni pe bi ọkunrin naa ba ṣe tiṣa ninu ẹfẹ rẹ lonii, o le di lọla ko ṣe akọrin ẹmi, o si tun le ṣe obi to n buru mọ awọn ọmọ rẹ nile, tabi ọlọja ti ko gba gbẹrẹ fun onibaara.

Ninu iforowewọ to ṣe pẹlu BBC News Yoruba, Mama Deola ṣalaye irinajo rẹ to fi di ẹni to n sọrọ pawo lori ayelujara, bo ṣe jẹ pe o niṣẹ to n ṣe tẹlẹ ko too di sọrọsọrọ ati adẹrinpoṣonu.

"Ọdun 2020 ni mo bẹrẹ si i ṣe 'content' lori ayelujara., lasiko ti aisan Korona bẹ silẹ ti ijọba si ni ki kaluku duro sile rẹ.

''Mo fẹ ohun ti yoo le da awon eeyan lara ya lasiko ti wọn wa nile nitori aisan Corona ni mo ṣe bẹrẹ ọrọ sisọ lori ayelujara''

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Folagade Banks ṣalaye pe ohun ti yoo maa da awon eeyan lara ya lasiko igbele aisan Corona nigba naa lo mu oun bẹrẹ si i ṣe awọn fidio ẹfẹ ọlọkan o jọkan.

Mama Deola fi kun un pe oun ni iṣẹ ti oun ṣe latilẹ, ko too di pe oun bẹrẹ ẹfẹ.

Nipa bo ṣe n to gbogbo awon ipa ọlọkan-o-jọka pọ, Folagade sọ pe iwoye awọn ohun to n ṣẹlẹ lawujọ kọọkan loun fi n ṣe e.

O ni boun ba wo iṣe awon olukọ, awọn iya ninu ile, akọrin ni ṣọọṣi ati bẹẹ bẹẹ lọ, oun yoo to o pọ, yoo si di odidi.

Iṣẹ naa rọ ọ lọrun gẹgẹ bo ṣe wi, nitori ko nilo lati ṣẹṣẹ maa wa ẹṣọ sori ati ọrun ko too ṣe ẹfẹ apanilẹrin-in, bakan naa ni ko nilo a n mura gẹgẹgẹ.

Nigba to n fun awọn ọdọ nimọran nipa jijapa, Mama Deola sọ pe ẹni to ba ni oun to fẹ lọọ ṣe nilẹ okeere lo pe fun, o ni ẹni ti ko ti mọ ohun kan pato ti yoo ṣe nibẹ ko ba kuku wo ohun to le ṣe ni ayika rẹ ni Naiiria, ti owo to fẹẹ fi japa yoo si di owo oriire nla fun nilẹ yii.

Ju gbogbo ẹ lọ, o gba wọn nimọran lati wo ohun ti wọn ba ri i pe o jẹ wọn lọwọ, o si ṣiṣẹ fun wọn bii ẹlẹran ara.