Àjẹ́ Jesu ni mí, ẹ yé sọ mi l'ókúta nígboro nítorí àjẹ́ tí mò ń ṣe nínú fíìmù - Ajirotutu

Ajirotutu n inu aṣọ to fi n ko ipa ajẹ ninu fiimu

Oríṣun àwòrán, Ajirotutu

Àkọlé àwòrán, O ni iṣẹ tiata ko faye gba oun lati kọju si ẹkọ oun lasiko naa bo tilẹ jẹ ọmọ ile ẹkọ to mọ iwe daadaa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Esther Oluwaranti Moradeke ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Iya Ajirotutu ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri nidi iṣẹ naa.

Inu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle FeelrightNews TV lo ti sọrọ naa.

Arabinrin ọhun to maa n ko ipa iya ajẹ lọpọ igba ninu ere sọ pe, ipa ti oun n ko naa gan an lo jẹ ki awọn eeyan kan maa wo oun gẹgẹ bii ajẹ nitootọ.

Ajirotutu, to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Osun ni ẹsin mẹtẹẹta ti awọn eeyan tẹwọgba ni Naijiria l'oun n ṣe ti oun si gbagbọ ninu rẹ.

Bi mo ṣe bẹrẹ ere ori itage

Nigba to n sọrọ lori bo ṣe di ẹni to yan iṣẹ tiata laayo, o ni iṣẹ naa kii ṣe iṣẹ to wu oun ni ibẹrẹ pẹpẹ amọ ẹgbọn oun kan, Alhaji Ganiyu, ti awọn eeyan mọ si Ojikutu lo mu oun de inu iṣẹ naa.

O ni "Alhaji Ganiyu, to jẹ ọkọ Iya Ibeji ọmọ arayele, to tun jẹ ọkọ Ato a ṣẹku... mi o tii di sisi tan ti wọn ti n mu wa kiri."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọdun 1972 nigba ti wọn ṣi maa n ṣe ere ori itage nikan ni oun bẹrẹ si n darapọ mọ awọn agba ọjẹ to mu oju oun mọ idi iṣẹ ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, baba oun ko fẹran iṣẹ naa amọ ẹgbọn oun ọhun maa n mu oun kiri.

O ni iṣẹ naa ko faaye gba oun lati kọju si ẹkọ oun lasiko naa bo tilẹ jẹ pe, ọmọ to mọ iwe daadaa ni oun.

"Ohun ti oju mi ri gẹgẹ bii ẹni to n ṣe ajẹ ninu ere"

Ajirotutu sọ pe oniruuru iwa buruku lawọn eeyan wu si oun latari ipa ti oun n ko ninu ere.

O ni "Mi o le royin, ti mo ba ni ki n maa sọ, ilẹ yoo kun, ilẹ yoo faya, ti a ba da sodo ko ni ṣan.

"Ti mo ba n lọ loju titi wọn a ni iya ajẹ oooo, oloṣi.

"Mo ti de ibi kan ri ti wọn lẹ mi lokuta.

"Wọn bẹrẹ si n lẹ mi lotuka ki n to o sa wọ inu ṣọọbu oniṣọọbu ti mo ni ẹ gba mi, mi o ni ajẹ, ẹ jọọ ẹ ṣaanu mi, mi o ni ajẹ.

"Bi mo ṣe n sọ yii, bi oju ṣe la to yii, wọn o tii dẹkun ati maa pe mi ni ajẹ."

"Mi o ki n ṣe ajẹ o, ajẹ Jesu ni mi."

Ajirotutu sọ siwaju si pe asiko kan wa ti oun fi wa ninu igbekun aisan fun odidi ọdun kan ati oṣu meji, bẹẹ lo tun mẹnuba iṣoro bo ṣe padanu awọn ọmọ rẹ atawọn iṣoro mii.

O pari ọrọ rẹ pe ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin oun atawọn akẹgbẹ ohun to maa n ṣe ajẹ ninu fiimu.

Lẹyin naa lo gba awọn akọroyin ori ayelujara nimọran lati dẹkun ati maa gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa oun lọna ati tete pa wo si apo ara wọn.