Ṣé ìjọba Osun lè pe ìjọba àpapọ̀ lẹ́jọ́ lórí owó ìjọba ìbílẹ̀ bí?

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke
Ijọba ipinlẹ Osun ti pe ẹjọ kan tako adajọ agba ní Naijiria, Lateef Fagbemi (SAN), nile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lori ẹsun pe o gbẹsẹle owo to yẹ fun ijọba ibilẹ ọgbọn to wa nipinlẹ naa.
Igbẹjọ tuntun yii lo n waye lẹyin ti ijọba ipinlẹ ọhun kọkọ wọgile ẹjọ to pe ṣaaju lori ọrọ kan naa.
Adajọ agba nipinlẹ Osun atawọn agbẹjọro míì to ko sodi bíi Mike Ozekhome (SAN) ati Musibau Adetunbi (SAN), n bẹ ile ẹjọ to ga julọ naa pe ko kan an nipa fun ijọba apapọ ko jọwọ owo ipinlẹ naa to gbẹsẹle.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ni o lodi si ofin bi ijọba apapọ ṣe gbẹṣẹle owo to yẹ fun idagbasoke atawọn eeyan ijọba ibilẹ ti ọrọ ọhun kan.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, adajọ agba Naijiria kọ eti ikun si idajọ ile ẹjọ giga ilu Osogbo lọdun 2025 pe awọn alaga ijọba ibilẹ ti ilu dibo yan lọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun 2025 yii ni ojulowo awọn ti ipo naa tọ si.
Ijọba Osun sọ pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2025 ni adajọ agba Naijiria, AGF, kọ iwe kan pe ki ijọba apapọ gbẹsẹle owo naa titi ti rogbodiyan to n waye lawọn ijọba ibilẹ Osun yoo fi pari.
Amọ wọn ni igbesẹ naa ko lẹsẹ nilẹ nitori pe idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ti yanju ọrọ naa lẹyin to wọgile eto idibo ijọba ibilẹ ti ijọba ana ṣe lọdun 2022.
N jẹ ijọba ipinlẹ Osun le pe ijọba apapọ lẹjọ?
Lẹyin igbesẹ ijọba ipinlẹ Osun lati pe ẹjọ yii ni awọn eniyan kan n beere pe njẹ ijọba ipinlẹ lagbara lati pe ijọba apapọ lẹjọ ni Naijiria.
Eredi ree ti BBC Yoruba fi kan si amofin Oluwasegun Kofoworola lati tan imọlẹ si ọrọ naa.
Kofoworola ni ijọba ipinlẹ Osun le pe ìjọba apapọ lẹjọ amọ o loju irufẹ ọrọ ti ijọba ipinlẹ le pe ijọba apapaọ lẹjọ si.
Nigba to n sọrọ nipa ọrọ ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria le da si, o ni ile ẹjọ naa le joko lori ọrọ to ba wa laarin ijọba ipinlẹ ati ìjọba apapọ, laarin ijọba ipinlẹ meji ati lori ọrọ ile igbimọ aṣofin agba ati ijọba apapọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, abala 232(1) iwe ofin Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999 lo fidi ọrọ yii mulẹ.
Amofin Kofoworola sọ pe "Lori ọrọ yii, ofin ko sọrọ lori ẹjọ laarin ijọba ibilẹ ati ijọba àpapọ̀ nitori ijọba ìbílẹ̀ ni ọrọ yii kan gbọngbọn, ijọba ibilẹ lo yẹ ko gba ile ẹjọ lọ pe wọn gbesẹ le owo oun nitori kii ṣe owo ijọba ipinlẹ ni wọn gbẹsẹlẹ."
"Ti a ba wa wo ọrọ yii daada, lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ṣe da si ọrọ adajọ agba Naijiria ati awọn adajọ agba awọn ijọba ipinlẹ ni Naijiria to si dajọ pe ki ijọba ibilẹ maa gba owo rẹ taara lọwọ ijọba apapọ, o n tumọ si pe ile ẹjọ to ga julọ naa le da si ọrọ to wa nilẹ yii.
"Fun idi eyii, ijọ ipinlẹ Osun le pe ijọba apapọ lẹjọ lorukọ ijọba ibilẹ to wa labẹ rẹ.
"Ile ẹjọ to ga julọ ni Naiijiria si gbọdọ gbọ ẹjọ naa latari pe ile ẹjọ ọhun ti kọkọ gbọ ẹjọ to rọ mọ owo naa ṣaaju ko to paṣẹ pe ki ijọba apapọ maa san owo ijọba ibilẹ sinu apo iṣuna rẹ taara."












