Ìjọba Eko wó ọjà Alaba Rago, àwọn oníṣòwò faraya

Awọn eeyan to n wo ọja Alaba Rago lẹyin ti ijọba Eko wo

Oríṣun àwòrán, x/@AbbaM_Abiyos

Àkọlé àwòrán, Ijọba Eko ti ni eredi wiwo ọja naa ko ṣẹyin igbesẹ lati tun kọ ko le ba igba mu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn oniṣowo ni ọja Alaba Rago, to wa ni ijọba ibilẹ Ojo, nipinlẹ Eko ti n beere fun owo itubu lọwọ ijọba ipinlẹ naa lẹyin to wo ọja ti wọn ti n ṣowo.

Ọja naa ti ọpọ awọn oniṣowo ibẹ wa lati Ariwa Naijiria, sọ pe awọn dukia to le ni ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira lo ṣofo nibẹ.

Awọn oniṣowo naa tun fẹsun kan awọn kan lara wọn pe wọn pawọpọ pẹlu ijọba Eko lati wo ọja ọhun lẹyin ti wọn ti kọkọ fẹnuko lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba fun atunṣe ọja naa.

Wọn ni ijọba Eko gbodọ san owo gba mabinu fun awọn lati lọ fi wa owo ṣe lagbegbe mii.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, wọn ko ṣẹ ijọba bẹẹni wọn ko wu iwa ọdaran kankan ki ijọba to ṣa deede bẹrẹ si n wo ọja naa, nitori naa o gbọdọ fun awọn lowo gba, mabinu.

Agbẹnusọ awọn oniṣowo ọhun, Adamu Katagum sọ pe "Wọn ba dukia ti owo rẹ le ni ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira jẹ, lai kọkọ kilọ fun wa tẹlẹ, koda wọn ko gba wa laaye lati ko awọn dukia wa kuro nibẹ.

"Gbogbo ibi ti a ti n ta awọn nnkan bii irẹsi, ẹwa, agbado ati awọn nnkan mii ni wọn da wo.

"Wọn wo ile alaja mẹta ti a n ko ẹru si, to fi mọ ile alaja meji mii.

"A beere fun ẹtọ wa latari pe a ki n ṣe alejo nibi, awa atawọn obi wa si ti n gbe nibi o ti le ni aadọta ọdun ṣeyin."

Ọkan lara awọn oniṣoro ti ọrọ naa kan, Bala Kofar Sabuwa, sọ pe ijọba fi awọn pe awọn alainilelori to n gbe lẹba ọna, o si wo awọn ṣọọbu awọn.

Sabuwa ṣalaye pe "Ọrọ yii ti da rogbodiyan silẹ nibi, awọn kọlọrọsi ti ya bo ṣọọbu awọn eeyan wa ti wọn si n ji awọn ọja ko nibẹ latari igbesẹ ijọba ọhun."

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 ni ijọba Eko bẹrẹ si n wo ọja Alaba Rago titi di ogunjọ oṣu kan naa.

Lati ọdun to kọja ni ijọba Eko ti fẹ wo ọja naa amọ olori awọn Hausa nipinlẹ naa, Aminu Yaro Dogara da si ọrọ ọhun.

Ọja naa jẹ ọkan pataki ti wọn ti n ta awọn ohun jijẹ atawọn ohun ọsin lati ariwa Naiijiria.

Ijọba Eko ti ni eredi wiwo ọja naa ko ṣẹyin igbesẹ lati tun un kọ ko le ba igba mu.