Ìdí tí Ààrẹ Tinubu fi fòfin de títa èso òrí sílẹ̀ òkèèrè fún oṣù mẹ́fà

Aworan eso ori ati ori ti wọn fa jade to funfun

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti buwọlu fifofin oṣu mẹfa de gbigbe eso ti wọn fi n ṣe ori jade fun tita si oke okun.

Ọjọ Iṣẹgun ni ileeṣẹ aarẹ fi ikede na sita, ti wọn si ni yoo bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ.

Ijọba sọ pe oun gbe igbesẹ naa lati mu alekun ba sise rẹ ni ẹsẹ kuku ati lati jẹ ki ẹka eso naa gbooro si.

Wọn tun ni afojusun wa pe yoo pawo owo toto $300m wọle lọdun fun ijọba apapọ.

Igbakeji aarẹ, Kashim Shettima to kede igbesẹ naa, sọ pe ko wa fun titako ofin karakata agbaye ṣugbọn lati lo anfaani eso lati pese iṣẹ ati ọrọ fun araalu ni ẹsẹkuku.

Shettima ṣalaye pe awọn gbe igbesẹ naa lati le mu ki eroja to to wa fun awọn ileeṣẹ labẹle, ti yoo si mu ki owo to n wọle si apo awọn eeyan to n gbe ni igberiko, pọ si.

"Igbesẹ yii yoo sọ Naijiria di orilẹede to n ta ori, ororo rẹ ati awọn nnkan mii ti wọn n ri lara eso ori, si ilẹ okeere,, dipo eso nikan to n ta sibẹ lọ."

Lori pipese iṣẹ ati mimu owo wọle, igbakeji aarẹ ni, "Naijiria n pese ida ogoji ninu ọgọrun un ori ni agbaye, sibẹsibẹ, ida kan ni ipin wa ni ọja agbaye to jẹ $6.5b.

Igbesẹ yii yoo pa owo toto $300m wọle lọdọọdun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ Aarẹ fi lede fun awọn akọroyin, igbakeji aarẹ ni bo tilẹ jẹ pe orilẹede Naijiria lo n pese ida ogoji ori l'agbaye, ti a ko si ri ọpọ ere jẹ pẹlu yii ko bojumu.

Shettima ni fifi ofin gbigbe awọn eso yii lọ si oke okun yoo pese anfaani fun orilẹede Naijiria lati pa owo to to $300m owo dọla si apo lọdun.

"Eyi ko jẹ itẹwọgba. A ni erongba lati pa owo to to $300m wọle lọdun, to ba si ti di ọdun 2027, a o ti ni to ilọpo mẹwaa alekun. Erongba wa ree."

Igbakeji aarẹ Shettima salaye pe ifofin de lo jẹ igbimọpọ awọn ẹka ijọba lati se ohun to tọ ni ilana lati pawo si apo ijọba.

"Ijọba ko ti ilẹkun; a n si ilẹkun ohun rere ni. Aarẹ w ani orilẹede Brazil, ti orilẹede mejeeji si gba lati gbe ori wa ni Naijiria ati ororo wọle si ọja Brazil. Igbesẹ yii yoo lo oṣu mẹta lati pari," igbakeji ṣalaye.

"Lonii, a n gbin eso ẹka ti yoo pese ọpọ anfaani fun ọpọ ọdun paapa fun awọn obinrin wa, fun eto ọrọ aje wa ati orilẹede Naijiria lapapọ ni ọja agbaye.

Saaju ki igbakeji aarẹ to sọrọ, minisita fun eto ọgbin ati idabobo ounjẹ, Sẹnetọ Abubakar Kyari, ṣalaye pe orilẹede Naijiria yoo jẹ ọpọ ere ninu fifofin de tita eso ori silẹ okeere..

"A n pese 350,000 tọnu ori lọdun kaakiri awọn ipinlẹ to le ni ọgbọn, ti a si n gbero lati lekun ni tọọnu 900,000. Sibẹsibẹ, ere wa ko pọ ni ọja agbaye.

"Eto The Rapid Assessment of the Shea Value Chain, ti ajọ PFSCU gbe kalẹ, ẹka ileeṣẹ ijọba to n risi karakata pẹlu ibasepọ pẹlu ẹka ijọba to n risi iṣẹ ọgbin, pese ẹri nla lati ti igbesẹ aarẹ lẹyin."

Gẹgẹ bii minisita ṣe ṣalaye, ayẹwo yii fihan pe Naijiria n padanu tọọnu ori to to 90,000 lọdun ni ipasẹ bi awọn kan se n gbe sita ni ọna ti ko tọ ọ.