Ìjọba Naijiria ṣí ojú òpó tí aráàlú fi le dá ojúlówó olùkọ́ mọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati le ni akọsilẹ kikun nipa awọn olukọ, ki wọn si tun le mọ awọn eyi to fi orukọ silẹ ti wọn si jẹ ojulowo lorilẹede yii, ijọba apapọ Naijiria ti ṣe ifilọlẹ oju opo kan ti yoo maa ri si eyi ati idagbasoke eto ẹkọ.
Oju opo naa ti wọn ṣi niluu Abuja ni ẹgbẹ Teachers Registration Council of Nigeria (TRCN) ati ajọ to n fi owo ran eto ẹkọ lọwọ ni UK ( United Kingdom–funded Partnership for Learning for All in Nigeria), ṣe agbatẹru rẹ.
Nigba to n ṣalaye lori igbesẹ naa niluu Abuja lọjọ Aje, ọjọ karundinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2025, Minisita eto ẹkọ, Ọmọwe Tunji Alausa, sọ pe ijọba gbe e kalẹ lati yi bi nnkan ṣe n ri lẹka ẹkọ pada ni.
Alausa sọ pe ko si orilẹede to le gunke agba kọja ohun ti awọn olukọ ibẹ ba mọ.
O ni oju opo tuntun yii ki i ṣe fun imọ ẹrọ nikan, ṣugbọn fun awọn olukọ paapaa lati ba igba yi, ki wọn dagba ninu imọ fun ọjọ ọla.
Gẹgẹ bo ṣe wi, oju opo yii ni wọn yoo ti maa fi orukọ silẹ nirọrun, gba iwe aṣẹ ti wọn yoo si tun ti maa ṣe isọdọtun iwe aṣẹ naa kaakiri Naijiria.
"Yoo tun fun wọn ni anfaani nipa eto idanwo to ba yẹ ki wọn ṣe, yoo ṣe igbelewọn itẹsiwaju awọn tiṣa pẹlu.
"Ohun to da le lori ni: Jijẹ akọṣẹmọṣẹ tiṣa, nini imọ ẹrọ igbalode, ṣiṣe iṣiro iṣẹ wọn, ṣiṣe deede ati biba awọn akẹgbẹ wọn lagbaaye dọgba."
Bẹẹ ni Minisita eto ẹkọ, Tunji Alausa,sọ.
"Kò sí tíṣà tí yóò ríṣẹ́ gbà lọ́dọ̀ ìjọba tàbi ilé ìwé àdáni mọ́ láì gba ẹ̀kọ́ iṣẹ́ tó yè kooro''
Bakan naa ni Minisita eto ẹkọ ṣalaye nipa eto ẹkọ to pọn dandan kan ti wọn fẹẹ bẹrẹ fun awọn olukọ.
Alausa sọ pe idanilẹkọọ naa jẹ dandan fun awọn tiṣa, nitori bi wọn yoo ṣe maa huwa lai kọja ohun ti ofin wi lo wa fun un.
O fi kun un pe tiṣa kankan ti ko ba gba idanilẹkọọ naa ko ni i ri iṣẹ olukọ gba nileewe ijọba ati ti aladaani mọ .
Ayẹwo finni-finni nipa ohun ti oluko naa n gbe bọ lati ibi to ti n ṣiṣẹ tẹlẹ yoo tun waye pẹlu, gẹgẹ bo ṣe sọ.
O fi kun un pe awọn ileewe aladaani naa gbọdọ maa yẹ akọsilẹ olukọ wọ, ṣe o wa ni ibamu pẹlu ofin tuntun TRCN.
"Eyi ki i ṣe ifiyajẹni, idaabobo ni. O n waye lati da aabo bo awọn ọmọ wa, ki ẹkọ to yẹ ki wọn gba nileewe ma si ṣe fo wọn ru"
Bẹẹ ni Alausa ṣalaye.
"Gbogbo òbí ló ní ààfààní láti wádìí báyìí, bóyá tíṣà tó fi orúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ TRCN ló ń kọ́ ọmọ wọn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́"
Ninu ọrọ tirẹ, Alabojuto Teachers Registration Council of Nigeria (TRCN), Ọmọwe Ronke Soyombo, sọ pe oju opo tuntun yii yoo ran akọsilẹ iye olukọ lọwọ.
Soyombo ni yoo tun fopin si iṣoro ọdun gbọọrọ ti awọn olukọ maa n koju ki wọn too ri iwe ẹri wọn gba.
"Pẹlu oju opo yii, awọn tiṣa kaakiri Naijiria le fi orukọ silẹ nitọrun, wọn le yẹ esi idanwo wọn wo ki wọn tun tẹ ẹ jade sinu iwe lai tiẹ daamu rara."
Ọmọwe Soyombo lo ṣalaye bẹẹ.
O ni TRCN ti n ṣiṣẹ lorii bi esi idanwo ti i ṣe Professional Qualifying Examination (PQE), yoo ṣe maa jade laaaarin ọsẹ kan pere, ti awọn tiṣa yoo si tete maa ri iwe ẹri wọn gba lẹsẹkẹsẹ.
"Gbogbo obi lo ni anfaani lati wadi bayii, boya tiṣa to fi orukọ silẹ lọdọ TRCN lo n kọ ọmọ wọn tabi bẹẹ kọ.
Nigba ti yoo ba fi di oṣu Kẹwaa, ajọ naa yoo ṣi oju opo Artificial Intelligence (AI) rẹ, bi Soyombo ṣe wi, eyi ti yoo ran iṣẹ awọn tiṣa lọwọ, ti awọn akẹkọọ naa yoo si gbadun ẹkọ bo ṣe sọ.
Olugbani-nimọran agba lati British High Commission, Ian Attfield, naa fi kun un pe ilana tuntun yii yoo ran akọsilẹ awọn tiṣa lọwọ, iwuri yoo ṣi wa fun wọn lati ṣe iṣẹ wọn.
"Tiṣa pọ loriṣiiriṣii— tiṣa agbegbe, awọn tiṣa to n kọmọ nilee ijọsin lati ọwọ ara wọn, ati awọn tiṣa ileewe olowo pọọku ti ọpọ wọn ko kunju oṣunwọn, eto tuntun yii tumọ si pe awọn naa gbọdọ darapọ, ki wọn si ri iwuri."
Attfield lo sọ bẹẹ.
O fi da wọn loju pe ijọba UK, nipasẹ ọfiisi rẹ ti i ṣe Foreign, Commonwealth and Development Office, yoo maa tẹsiwaju ninu iranlọwọ to n ṣe fun atunto eto ẹkọ Naijria.














