Wọ́n hú okú èèyàn mẹ́sàn-án jáde l'áginjù pásitọ̀ tí àwọn ọmọ ìjọ rẹ́ n gbààwẹ̀ láti dé ọ̀run

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọn tun ti hu oku eeyan mẹsan an jade ninu awọn iboji tuntun ti wọn fura pe o niiṣe pẹlu ile ijọsin kan to n fi ebi 'fa ọkan awọn ọmọ ijọ sunmọ ọrun'.
Ọdun 2023 ni aṣiri ẹgbẹ olujọsin naa kọkọ tu ninu aginju Shakahola, to wa ni tosi ilu Malindi, orilẹede Kenya.
Ko din ni oku irinwo eeyan ti wọn ri lọdun naa, eyi ti ko tii fẹ si iru rẹ ri.
Awọn alaṣẹ sọ pe oku awọn eeyan naa lo ṣe e ṣe ko jẹ ti awọn ọmọlẹyin pasitọ kan, Paul Mackenzie, ti wọn lo n rọ awọn eeyan naa lati fi ebi pa ara wọn titi doju iku, ki wọn le ri ọrun rere wọ.
Oṣu Keje to kọja ni ile ẹjọ tun paṣẹ pe ki wọn lọ hu ilẹ lati tun wa oku awọn eeyan. Eyi waye lẹyin ti awọn ọmọde kan tun dawati, eyi to bi iwadii tuntun.
Awọn ọlọpaa sọ pe ọwọ ti tẹ eniyan mọkanla to ni nnkan ṣe pẹlu iṣẹlẹ naa, ti mẹta lara wọn si jẹ ọmọ ẹyin Mackenzie lasiko ti aṣiri ipaniyan Shakahola Forest waye.
Oku awọn eeyan ti wọn tun ṣẹṣẹ ri yii dabi pe o n fidi ifura ijọba mulẹ pe, ẹgbẹ ẹlẹsin abami naa ṣi n ṣiṣẹ ibi wọn.
Ninu oṣu Kẹrin, minisita fun ọrọ abẹle, Kipchumba Murkomen, sọ pe awọn eeyan kan n fi ẹsun kan pe, Ọgbẹni Mackenzie ṣi n ba awọn ọmọ ẹyin rẹ sọrọ lati inu ọgba ẹwọn to wa, pẹlu foonu.
Ọgbẹni Mackenzie ti ọwọ ijọba tẹ lọdun to kọja, to si ni oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan, ni iroyin sọ pe o sọ fun awọn ọmọlẹyin rẹ pe wọn yoo tete de ọrun, ti wọn ba dẹkun lati maa jẹun.
Gẹgẹ bi iroyin ti AFP gbe jade, ile ẹjọ Mombasa to n gbọ ẹsun rẹ ti so ẹjọ rọ ni ibẹrẹ oṣu yii, nitori "awọn ẹri tuntun to n jade".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọbọ to kọja ni wọn ti kọkọ ri oku eeyan mẹrin kan ti wọn hu jade ni abule Kwa Binzaro to wa nitosi aginju Shakahola, ki wọn tun to o ri mẹrin mii lọjọ Ẹti.
Onimọ niap ẹya ara, Richard Njoroge, sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe awọn ṣi n hu ilẹ, nitori pe aginju naa tobi pupọ.
"A bẹ awọn araalu to ti padanu eeyan wọ̀n tabi to fura pe awọn ẹbi tabi ọrẹ wọn ti dawati, lati lọ si ileewosan Malindi, lati ṣe iranwọ fun ayẹwo DNA."
Ireti wa pe wọn o tun gbẹ iboju mejidinlogun mii lọjọ aje.
Ileeṣẹ eto idajọ ni Kenya sọ loṣu Keje pe awọn gbagbọ pe awọn eeyan ti wọn sin oku wọn lo ṣe e ṣe ko ku nitori ebi tabi tori pe wọn fun wọn lọrun pa nitori pe wọn n tẹle ilana ẹsin ti ko bojumu.
Ọkan lara awọn ajafẹtọ ọmọniyan, Hussein Khalid, alaṣẹ Vocal Africa, to wa nibi ti wọn ti hu oku jade lọjọbọ, sọ pe ọkan lara awọn ilẹ isinku naa mu ifura dani nitori pe o jọ pe awọn eeyan kan ti hu oku to wa ninu rẹ kuro, to si jẹ pe aṣọ ati awọtẹlẹ awọn ọmọde ati obinrin lo wa ninu koto naa.
O ni eyi fihan pe o ṣe e ṣe ko jẹ ọmọde tabi obinrin ni wọn sin sibẹ tẹlẹ
Bi Paul Mackenzie ṣe wọ gau

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin naa, to pe ara rẹ ni pasitọ ti sọ pe ohun ko jẹbi ẹsun iku awọn eeyan naa ti wọn fi kan oun.
Apapọ oku eeyan 429 ni awọn alaṣẹ wu jade lọdun 2023, nibi ti wọn sin wọn si lagbegbe Shakahola, ti ọmọde si wa lara wọn.
A gbọ pe ṣe ni Mackenzie sọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ, Good News International Church, pe ki wọn lọ sibi ti wọn ku si naa lati maa reti opin aye to fẹ de.
Nigba ti wọn de ibẹ, ọpọ wọn lo gba awẹ titi doju iku lọna ati wọn iọba ọrun, ti a si gbọ pe ijọ naa lo sin lara oku awọn eeyan ọhun.
Ọkan lara awọn oṣojumi koro sọ fun BBC pe ijọ naa sọ fun awọn pe ki wọn bẹrẹ si n gbawẹ lati oṣu Kinni ọdun to kọja ki awọn le ri ọrun wọ.
Amọ Mackensie ti fesi pe ijọba ko le so oku awọn eeyan mọ oun lọrun nitori lati ọdun 2019 ni oun ti gbe ijọ naa ti pa.
Ṣaaju ni awọn agbofinro ti kọkọ bẹ ile ẹjọ pe ko fun awọn laaye lati tẹsiwaju lati fi Mackenzie si atimọle titi ti awọn yoo fi pari iwadii wọn.
Wayi o, wọn ni awọn ti ni ọpọ ẹri lati gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ bayii.
Yatọ si ẹjọ oku awọn ọmọ ijọ ti Mackenzie n jẹ, oun atawọn afurasi to ku tun n jẹjọ lori ẹsun fifi iya jẹ ọmọde lọna aitọ.














