Ọ̀dọ́bínrin Bidemi kú sílé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ Yinka l'Osun, Yinka dèrò àhámọ́, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan awọn ọlọpaa ipinlẹ niwaju ọọfiisi wọn

Oríṣun àwòrán, Osun State Police Command/X

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaa obinrin kan ati ọlọpaa obinrin meji
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọ fun BBC Yoruba wi pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iku to pa ọdọbinrin Bidemi Omole nile ọrẹkunrin rẹ, Yinka, niluu Esa-Oke nipinlẹ Osun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba lalẹ ana ọjọ Aiku ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ti a wa yii.

Iṣẹlẹ naa ni a gbọ pe o ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Ẹti to kọja nigba ti Bidemi de si ile Yinka.

Ohun ti a tun gbọ ni pe iṣẹlẹ yii mu ki ibẹru-bojo gbalẹ lagbegbe ti Yinka gba ile si niluu Esa-Oke.

Ki ni ọlọpaa sọ lori iku Bidemi Omole?

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe ''lalẹ ọjọ Ẹti to kọja ni Bidemi de si ile ọrẹkunrin rẹ, Yinka niluu Esa-Oke.

Yinka sọ fun wa pe o fẹ rẹ Bidemi diẹ lalẹ ọjọ naa, eyi lo si jẹ ki o maa bii.

Lẹyin naa ni Yinka sọ fun awa ọlọpaa wi pe oun atawọn eeyan kan gbe Bidemi digba digba lọ sile iwosan lati du ẹmi rẹ.

Amọ, Yinka sọ pe nile iwosan ti wọn gbe ọdọbinrin naa lọ lawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe Bidemi ti jẹ Ọlọrun ni pe.''

''Ọrẹkunrin Bidemi ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun''

DSP Ojelabi ko ṣai fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba wi pe Yinka to jẹ ọrẹkunrin Bidemi nikan ni afurasi tọwọ ọlọpaa ti tẹ bayii lori iku ọdọbinrin naa.

''Ọrẹkunrin Bidemi ti wa ni ahamọ wa, a si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa iku ọdọbinrin ọhun.''

Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ ọlọpaa bo ya Yinka yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ, DSP Ojelabi ni ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ ṣe iwadii wọn tan lati mọ ohun to ṣokunfa iku Bidemi ki wọn to maa sọrọ gbigbe ọrẹkunrin oloogbe naa lọ sile ẹjọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe laarọ ọjọ keji ọjọ Satide ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ yii ni wọn to mu ẹjọ naa wa sọdọ awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ ọhun.

Ohun ti a tun gbọ ni pe Bidemi n mura lati lọ fun iṣọ-oru ni ṣọọṣi kan ni lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye.

DSP Ojelabi fikun ọrọ rẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣayẹwo oku ọdọbinrin lati mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ gan an.