"Lóòótọ́ ni mò ń mófo nínú tẹ́tẹ́ bọ́ọ̀lù tí mò ń ta, àmọ́, mi ò lè fi í sílẹ̀"

Aworan awọn ọkunrin nile tẹtẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi awọn ọkunrin kan duro lawọn mii jokoo ni ṣọọbu ti wọn ti n ta tẹtẹ bọọlu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbiyanju Musa pẹlu tẹtẹ bọọlu tita ti jẹ kí o di ẹni tí gbogbo eeyan n fi ṣe ẹlẹya ni adugbo rẹ niluu Kaduna lapa ariwa orilẹede Naijiria.

Musa mọ bọọlu gba daadaa lati igba ewe rẹ, ọpọ eeyan lo si maa n wo o gẹgẹ bii ẹni tí yoo gba bọọlu jẹun.

Eyi lo jẹ ko rìnrìn ajo lati ilu Kaduna lọ si ilu Eko ki o lè lanfaani lati maa gba bọọlu nibi ti gbogbo aye yoo ti maa ri i.

Ti ọmọdekunrin kan ba ti gbera lati apa ariwa Naijiria lọ si guusu, awọn eeyan ariwa maa n ri igbesẹ yii gẹgẹ bi ọna lati jẹ ki ala iru ọdọ bẹẹ wa si imuṣẹ.

Amọ, ọrọ ko ri bẹẹ fun Musa nitori nnkan mii to yatọ si bọọlu gbigba tawọn ẹbi rẹ atawọn eeyan mọ ọn mọ lo bẹrẹ si ni ṣe niluu Eko.

Dipo ki Musa gbiyanju sii lati le lanfaani ati lọ gbabọọlu loke okun, ni ṣe ni Musa lọ kọ bi wọn ṣe n ta tẹtẹ lori bọọlu afẹsẹgba niluu Eko.

Bayii ni Musa ṣe di ilumọọka lori tẹtẹ tita, bo tilẹ jẹ ofo lo mu lọgba igba to ti ta tẹtẹ.

Musa ni o ṣoro foun lati dẹkun tẹtẹ tit abo tilẹ jẹ pe oun ti padanu owo gọbọi lori tẹtẹ tita.

Bi Musa ṣe bẹrẹ tẹtẹ tita l'Eko

Nigba to n ṣalaye bo ti bẹrẹ tẹtẹ tita, Musa ni ''ololufẹ bọọlu gidi ni mi.

Amọ, dipo ki n maa gba bọọlu, idi tẹtẹ tita lori bọọlu ni mo ba ara mi.

Mo ro wi pe bọọlu gbigba yoo mu ayipada rere ba igbe aye mi nigba ti mo kọkọ bẹrẹ si ni gba bọọlu, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Ọrẹ mi kan toun naa jẹ agbabọọlu lo mi wọ inu tẹtẹ tita.

''Koda, mo gba bọọlu de orilẹede Niger Republic, ṣugbọn nipinlẹ Eko ni ọrẹ mi ti sọ fun mi lọjọ kan pe ki n sin oun lọ si ṣọọbu kan.

N14,000 ni wọn fun ọrẹ mi yii nigba ti a de ṣọọbu naa, nibẹ lo ti sọ fun mi pe oun toun jẹ nibi tẹtẹ ni owo naa.

O tun wa sọ fun mi pe emi naa yoo maa jẹ owo ti mo ba le maa tẹtẹ lori bọọlu,'' Musa ṣalaye.

Diẹ loku ki tẹtẹ tu igbeyawo mi ka - Musa

Musa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ọrẹ oun kilọ foun pe o maa nira lati fi tẹtẹ tita silẹ ti eeyan ba ti le bẹrẹ rẹ tan.

''N18,000 ni kọkọ jẹ nigba t imo bẹrẹ si ni ta tẹtẹ, mo si tun jẹ N6,000 nigba keji; N1,000 pere ni mo jẹ nigba ti mo ta tẹtẹ fun igba kẹta.

Lẹyin igba naa ni mi o jẹ owo kankan mọ fun igba pipẹ, ọpọ eeyan lo maa n jẹwo daadaa nigba ti wọn ba kọkọ bẹrẹ tẹtẹ tita.

Amọ, to ba ti dun mọ wọn tan ni wọn ko ni ri owo jẹ mọ bii ti tẹlẹ.''

Musa ni oun tẹsiwaju tẹtẹ tita nigba toun pada si ilu Kaduna lati ilu Eko.

''Mi o mọ idi ti mi o fi le fi tẹtẹ tita silẹ, bo tilẹ jẹ pe n ko ri ere nibẹ.

Koda diẹ loku ki tẹtẹ tu igbeyawo mi ka, ti mo si bura lati ma de idi rẹ mọ, ṣugbọn ni gbogbo igba ni mo n pada lọ sibẹ,'' Musa ṣalaye.

Musa sọ pe imọran ti baba oun foun ni pe ki oun maa gbadura pe ki Eleduwa ran oun lọwọ lati fi tẹtẹ silẹ.

Ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu pọun ni iwadii sọ pe ogunlọgọ eeyan n lo lagbaaye lati fi ta tẹtẹ.