NAFDAC kìlọ̀ nípa ayédèrú mílíìkì Cowbell tó kún inú ọjà, bí o ṣe lè dá a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Nafdac
Ajọ to n gbogun ti ayederu ounjẹ ati oogun ni Naijiria , NAFDAC, ti ke gbajare sita pe ayederu miliiki Cowbell ti gba igboro kan.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ ni NAFDAC ti sọ ọrọ naa lọjọ Satide.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, miliiki "Our Milk" to jẹ ti Cowbell ni awọn kan n ṣe ayederu rẹ bayii.
NAFDAC sọ pe ileeṣẹ Promasidor Nigeria Ltd to n pese, to si n ta Cowbell lo ti fi ọrọ naa to oun leti pe ayederu miliiki naa to fara jọ ojulowo rẹ ti kun inu ọja.
Iwọn giramu mejila (12g), to wa ninu ọra pelebe, ni ayederu miliiki ọhun to si n lo orukọ ati awọ Cowbell to fi mọ nomba idanimọ NAFDAC wọn, yoo si ṣoro fun eeyan lati da ojulowo mọ si ayederu yii ayaafi ti ẹni naa ba wo o finifini.
Promasidor Nigeria Ltd ni awọn ko mọ nnkankan nipa ayederu miliiki naa, awọn kọ lo n po o bẹẹ kii ṣe awọn lo n pin kaakiri.
Ileeṣẹ naa sọ siwaju si pe ọdun 2023 ni dẹkun lati maa ṣe Cowbell ti wọn kọ "Our Milk'' si lara, ti wọn si rọpo rẹ pẹlu "Our Creamy Goodness" ti wọn n lo bayii.
Bi o ṣe le da ayedery miliki Cobell "Cow Milk" giramu mejila mọ ninu ọja

Oríṣun àwòrán, NAFDAC
- Miliiki inu rẹ ko farajọ miliiki daadaa
- Akọle "Our Milk" atijọ ni wọn lo si ayederu naa
- Ti o ba wo ara ayederu miliiki naa, irisi ọda ti wọn fi kọ ọ jẹ 'ink' kii ṣe ẹrọ 'laser'
- Ọwọ lasan ni wọn fi ṣe ibi ti o ti le ja milili naa lẹgbẹ rẹ, kii ṣe ẹrọ igbalode
Ewu to wa ninu mimu ayederu miliiki Cowbell

Oríṣun àwòrán, NAFDAC
NAFDAC ṣalaye pe ewu nla lo wa ninu mimu ayederu miliki Cowbell naa fun ilera ẹni to ba mu u.
Lara ewu ti NAFDAC mẹnuba ni mimu majele lai mọ ati jijẹ awọn ohun ti wọn po pọ lai ṣe ọfintoto rẹ ṣaaju.
Wọn ni eyii le ṣakoba fun ifun ati ẹdọforo, o le mu ki eeyan maa bi, o tun le yọri si iku pẹlu.
Ewu nla tun ni fun awọn ọmọde atawọn alaboyun.
Ti o ba ti ṣawari ayederu miliki naa lagbegbe rẹ, NAFDAC ni ki o pe ẹrọ 0800-162-3322 tabi kọ iwe si [email protected].















