Peter Rufai wọ káà ilẹ̀ sùn nílùú Eko

Àkọlé fídíò, Peter Rufai wọ káà ilẹ̀ sùn nílùú Eko
Peter Rufai wọ káà ilẹ̀ sùn nílùú Eko

Wọn ti sin oku oku agbaọjẹ agbabọolu to tun jẹ aṣọle fun ikọ Supoer Eagles fun ọpọ ọdun, Peter Rufai niluu Eko.

Ọpọ mọlẹbi, ọrẹ, ojulumọ atawọn akọroyin lo peju sibi eto isinkin ọhun.

Ilẹ isinku to wa lagbegbe Ikoyi, niluu Eko ni wọn sin Dodomayana si, gẹgẹ bii ọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e nigba aye rẹ.

Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni Rufia ko to dagbere faye lọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2025 yii.

Oloogbe naa ti kọkọ ṣaisan fun akoko diẹ ko to pada fi aye silẹ nile iwosan kan niluu Eko.

Ikọ agbabọọlu Super Eagles lo kọkọ kede iku rẹ loju opo X wọn.

Aworan ọmọbinrin Peter Rufai to gbe aworan oloogbe naa lọwọ ni iboji rẹ to wa ni Ikoyi, niluu Eko
Àkọlé àwòrán, Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni Rufia ko to dagbere faye lọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2025 yii

A ko le gbagbe baba wa titi lai - Ọmọ Peter Rufai

Nibi eto isinku naa lawọn ọmọ Rufai ti sọrọ nipa igbe aye rẹ atawọn ohun ti wọn ko le gbagbe nipa rẹ titi lai.

Ọkan lara awọn ọmọ rẹ obinrin to ba BBC sọrọ sọ pe o ṣoro lati degbere fun baba oun.

O ni "Baba mi jẹ eeyan daadaa, o jẹ ẹni ti ki n gba igbakugba ati ẹni to maa n lọ jẹjẹ tirẹ."

"Ni bayii ti baba mi ti jade laye, mo le sọ pe mọ fẹran baba (ati iya mi ti oun naa ti di oloogbe) ni bayii ti emi naa ti di obi. A maa saaro rẹ gidi."

Aworan iboju Peter Rufai ni Ikoyi, niluu Eko
Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn ọmọ rẹ obinrin to ba BBC sọrọ sọ pe o ṣoro lati degbere fun baba oun

Taribo West sọ oko ọrọ si ijọba Naijiria ati ijọba Eko

Ẹwẹ, ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ gba bọọlu fun Naijiria, Taribo West ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Naijiria bi wọn ko ṣe bikita nipa oloogbe ọhun.

Taribo West sọ pe o ṣeni laanu pe niṣe lawọn akẹgbẹ rẹ atawọn ẹbi n wa owo kiri lasiko to n ṣaisan.

O ni oun ko ni gba ki ọmọ oun gba bọọlu fun Naijiria lai latari aibikita ijọba si awọn to ti gbe ogo rẹ larugẹ nigba aye wọn.