Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Peter Rufai, ohun táwọn èèkàn ń sọ nípa rẹ̀

Aworan Peter Rufai

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Peter Rufai, ọkan gboogi ninu awọn asọle fun ẹgbẹ agbaboolu Nigeria, Super Eagles, to tun jẹ olokiki fun ere bọọlu ni ilẹ adulawọ padanu ẹmi rẹ lọjọ kẹta oṣu keje ọdun 2025, ti ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu kaakiri agbaye si n ṣe idaro rẹ.

Akọni ti yoo ṣoro fun ọpọ lati gba ni Rufia jẹ pẹlu bi o ti ṣe gba Super Eagles silẹ ni ọpọ igba lasiko idije ere bọọlu.

Dodomayani ni ọrukọ ti ọpọ akẹgbẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ ma n pe, to si jẹ ọkan lara agbabọọlu Nigeria to gbe ẹgbẹ naa sita fun araye lati ri.

Peter Rufai wa lati idile Ọba

Inu idile Oba ni won bi Peter Rufai si lọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹjọ ọdun 1963 ni Oshodi, nipinlẹ Eko. Baba rẹ jẹ ọkan lara Oba to jẹ ni Idimu.

Ọpọ lo n ro pe yoo bọ sipo awọn Baba rẹ ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba to kọ lati tẹwọgba ipo yii nitori ifẹ rẹ fun ere bọọlu.

Rufia gba bọọlu fun ọpọ kilọbu ni Yuroopu

Aworan Peter Rufia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Rufai bẹrẹ si ni gba bọọlu rẹ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Stationery Stores ati Femo Scorpions ko to di pe o lọ Oke okun. O gba bọọlu fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu kan lorilẹede Benin (Dragons de l'Ouémé), niluu Belgium (Lokeren, Beveren), ni Netherlands (Go Ahead Eagles), Portugal (Farense, Gil Vicente), ati ni Spain (Hércules, Deportivo La Coruña), to si ni ọpọ iriri kaakiri agbaye.

O ran ẹgbẹ agbabọọlu SC Farense lọwọ lati kopa ninu UEFA Cup

Ni saa ere idaraya 1994–95, Rufai ko ipa nla lati ran ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Portugal SC Farense lọwọ lati kopa fun igba akọkọ ninu idije UEFA Cup qualification. O fi ọpọ itan lelẹ lasiko naa.

Oun ni asọle akọkọ fun Nigeria ninu idije ife ẹyẹ agbaye

Rufai gba bọọlu fun orilẹede Nigeria fun igba marundinlaadọrin, to si jẹ asọle akọkọ fun ikọ Super Eagles ninu idije ife ẹyẹ agbaye ni ọdun 1994 ati 1998.

Bakan naa lo ko ipa ribiribi ni ọdun 1994 lasiko ife ẹyẹ ile adulawo to wa ni orilẹede Tunisia.

Pẹlu bi o ṣe jẹ goolu, Rufai jẹ goolu fun Super Eagles

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pe ki Gooli mi awọn lo jẹ ohun ti ko ki n fi bẹ waye. Ṣugbọn Rufia ni oreọfẹ yii lati mi awọn fun orilẹede rẹ. O gba pẹnariti fun Nigeria lasiko ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Ethiopia lọdun 1993.

Wọn ma n pe ni "Dodo Mayana"

Ọpọ awọn awọn ololufẹ rẹ lo ma n pe ni "Dodo Mayana" nitori bi o ṣe ma n fo lọ mu bọọlu ati bi o ṣe ma dena de bọọlu lati ma wọ awọn.

Ọrukọ naa ni ọpọ n pe titi to fi jade laye.

O pada si ile ẹkọ fun imọ ọlukọ

Lẹyin igba ti Rufia fẹyinti lẹnu iṣẹ ere bọọlu, o pada si yara ikawe ni ọdun 2023, to si lọ si ile ẹkọ ni National Institute for Sports ni ile Eko lati iwe ẹri fun olukọni.

O da ile ẹkọ ere bọọlu Staruf Football Academy silẹ

O fẹran idagbasoke awọn ọdọ, Rufai da ile ẹkọ Staruf Football Academy silẹ niluu Eko.

O jẹ eeyan to n ṣe igbalarugẹ ile ẹkọ ati ere idaraya , to si n rọ awọn obi pe ki wọn ṣe igbalarugẹ awọn ọmọ wọn ti wọn nifẹẹ ere idaraya.

Adepoju, Onigbinde, Odegbami sọrọ nipa oloogbe

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn akẹgbẹ oloogbe Peter Rufia ti bọ sita lati sọ nipa igbesi aye oloogbe ati awọn mọnigbagbe to wa laaarin wọn.

Ọpọ wọn ni wọn fi ibanujẹ jẹ ọkan wọn nigba ti wọn ba BBC sọrọ lori igbesi aye oloogbe naa.

Adegboye Onigbinde, olukọni fun ikọ Super Eagles ni oun o le gbagbe bii oloogbe ṣe ọkan ninu gba bọọlu fun orilẹede Nigeria.

Onigbinde ni iwa irẹlẹ ni Oloogbe jẹ ohun to mu tayọ lasiko to n gba bọọlu.

O wa aladura pe ki Ọlọrun duro ti mọlẹbi ati ọrẹ ti oloogbe naa fi silẹ.

Mutiu Adepoju, agbabọọlu Nigeria tẹlẹ ri nigba kan ri iku Peter Rufia lo jẹ ajalu nla fun agbo ere bọọlu.

O ni mọ iyi oloogbe naa bi o ṣe ma n ki oun pe oun ni agbara lati jẹ goolu pẹlu ori ju ẹsẹ oun lọ.