Ẹ wo oríkì ìdílé Sunday Igboho tó tún fẹ́ ki orí àgbà méjì bọ koto lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ́ sí Ooni

Sunday Igboho ninu aafin Ile Ife lasiko abẹwo lọjọ Abamẹta to kọja, Igboho joko si ẹsẹ Ooni ti awọn mejeji si wọ aṣọ funfun

Oríṣun àwòrán, Femi Awe

Àkọlé àwòrán, Nigba ti Igboho de Ile-Ife, ọgọọrọ eeeyan lo yi ka ti wọn si n ki i ni mẹsan an mẹwaa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Sunday 'Igboho' Adeyemo ti ṣabẹwo si Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, nibi to ti tọrọ aforijin lọwọ rẹ fun ọrọ to sọ nipa rẹ sẹyin.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 ni Igboho gbe igbesẹ naa.

Yatọ si Ooni, Igboho tun ti ṣabẹwo si awọn ori ade mii nilẹ Yoruba lẹyin to pada si Naijiria lati atipo rẹ ni orilẹede Germany.

Ki lo gbe Igboho lọ si aafin Ooni?

Nigba ti Igboho de Ile-Ife, ọpọlọpọ eeeyan lo yi i ka, ti wọn si n ki i ni mẹsan an-mẹwaa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, niṣe lo lọ sibẹ lati lọ tuuba lọwọ Oniriṣa fun awọn ọrọ kobakungbe kan to ti sọ nipa rẹ ṣaaju asiko yii.

Igboho ni "Yoruba sọ pe ẹnu ti igbin ba fi bu oriṣa, ẹnu naa ni yoo fi gbolẹ niwaju rẹ... mo wa siwaju ooṣa lonii, ẹnu mi wọ, mo wa fi ẹnu gbolẹ niwaju ooṣa."

Lẹyin naa lo dọbalẹ siwaju Ooni to si fi ẹnu gbolẹ niwaju rẹ.

Igboho sọ pe oun ko mọ pe Ooni yoo pọn oun le bo ṣe ṣe fun oun, inu oun si dun pe o gba oun tọwọ-tẹsẹ.

Ọrọ wo ni Igboho sọ l'aafin Ooni to tun fẹ da wahala silẹ?

Sunday Igboho dọbalẹ niwaju Ooni lati bẹbẹ

Oríṣun àwòrán, Femi Awe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kete lẹyin abẹwo naa ni ẹnu tun n kun Igboho pe o ri Alaafin ilu Oyo fin ninu ọrọ to sọ nigba to wa ni Ile Ife.

Bo tilẹ jẹ pe Igboho ti sọ pe ọrọ naa ko ri bi awọn kan ṣe n sọ kiri, ibere ti ọpọ eeyan n bere ni pe ki ni ohun to sọ gan-an to n da wahala silẹ.

Nigba ti Igboho wa ni aafin Ooni ni wọn fun ni ẹrọ gbohungbohun lati sọrọ niwaju Ooni, asiko naa lo ki ara rẹ pẹlu oriki ẹbi rẹ, eyi yii gan-an lo fẹ da wahala silẹ.

Lasiko to n ki ara rẹ, Igboho ni "Iya kan n ki mi nibi nisinyi, ori mi n wu.

"O ni lade-lade-lade, Alaafin ko le pitan ko ni ti awọn baba mi bawo, o ṣeewọ.

"Emi ni wọn maa n ki ni ọmọ lade-lade-lade, Alaafin o lade, ade baba mi ni wọn gba ti wọn gbe fun Alaafin.

"Ori ade ọmọ alade odi, ọmọ alade ṣẹṣẹ ẹfun...."

Lẹyin ọrọ Igboho yii ni ẹnu bẹrẹ si n kun pe o n fi ohun ranṣẹ si Alaafin ilu Oyo, Ọba Abimbola Owoade.

Ti ẹ ko ba gbabe, ọrọ kan ti n ja nilẹ tẹlẹ laarin Ooni ati Alaafin lori ẹni to ju ninu awọn agba ọba ilẹ Yoruba meji ọhun.

Mi o bu Alaafin, mi o to bẹ, oriki ile wa lasan ni mo n ki – Igboho

Wayi o, Igboho ti jade sọrọ pe oun ko bu Alaafin, bẹẹ ni oun ko si mọọmọ gbe igbesẹ lati ri ori ade naa fin lasiko abẹwo oun si Ile-Ife.

Ninu fidio kan to fi lede loju opo ayelujara rẹ, Igboho sọ pe oun ko le ri Alaafin fin ati pe oriki agbo ile awọn ni oun n ki, eyii ti Alaafin funra rẹ mọ.

O ni "Alaafin kii ṣe ọba kekere ti maa maa bu wọn; mi o bu wọn o, Kabisi, mi o jẹ bu yin o, mi o ṣe bẹẹ oo.

"Ki n ṣe pe mo bu baba wa Alaafin, ki ni mo fẹ bu wọn fun?

"Ki alaafia wa laarin gbogbo ẹyin baba wa, ni awa n gbadura."

O pari ọrọ rẹ pe ki Alaafin darijin oun nitori oun ko to lati ṣe irufẹ nnkan bẹẹ laye.