Bola Tinubu gbé owó ńlá fún èmi àti Adebayo Faleti torí ipa tí a kó nínú eré Saworo Ide - Lere Paimo

Oloye Lere Paimo jókòó sórí àga nínú aṣọ Damaski agbada àti fìlà to jẹ́ aláwọ̀ goolu àti omi aro. Ó sì tún fi ìlẹ̀kẹ̀ si ọrùn nígbà tí àwọn koríko rẹsurẹsu wá ní ilẹ ibi tí wón jókòó sí.

Oríṣun àwòrán, Lere Paimo

Àkọlé àwòrán, Oloye Lere Paimo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà ni èdè Yorùbá, Olóyè Lere Paimo tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ẹ̀dá Oníléọlá, tí ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nnkan nípa ìgbésí ayé rẹ.

Lere Paimo, lásìkò tó ń kopa ninu ifọrọwerọ pẹlu Jeff Owolewa lórí ayélujára sọ̀rọ̀ nípa àwọn sinimá tó ti kopa ninu rẹ àti ibasepọ rẹ pẹlu awọn èèkàn ìlú ni awujọ bíi Oloye Olusegun Obasanjo àti Aare Bola Tinubu.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bó ṣe ni imisi láti kọ ìtàn eré tíátà tó sọ di gbajumọ, eyiun ere Ogbori Elemoso, Lere Paimo ni òun ká ìwé ìtàn kan nípa idasilẹ ìlú Ogbomoso èyí tí Ọjọgbọn N.D Oyerinde kọ ni.

"Soun tí Ogbomoso tó wà lórí ìtẹ́ tí ń kó owó tó tó ₦500m jọ láti ṣe sinimá Ogbori Elemoso"

Lere Paimo tún sọ̀rọ̀ nípa bí sinimá náà ṣe sọ di olókìkí lagbo isẹ tíátà.

"Ọfà tí mo lo nínú eré Ogbori Elemoso jẹ ọfà tí bàbá bàbá mi fi ja ogún Jalumi, ọfà náà sì wà nínú yàrá mi di asiko yii.

Lootọ ni mo bá Bàbá náà láyé àmọ́ ó papoda lọ́dún 1952.

Ọfà náà ni emi àti Elemoso lo nínú eré náà.

Ere Ogbori Elemoso náà lókìkí pupọ, tí Soun tó gbesẹ, Ọba Jimoh Oyewumi Ajagungbade Kẹta si fi òye dá mi lọla pé òun gbádùn isẹ ti mo ṣe."

Eda Onileola ni lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, ètò tí ń lọ lọ́wọ́ láti tún Ogbori Elemoso ṣe sínú sinimá ìgbàlódé.

" Soun to wa lori oyè lọ́wọ́ lọ́wọ́ gan pé mi pé àwọn fẹ́ ka tún sinimá Ogbori Elemoso ṣe, kí àwọn ọdọ wá lè mọ ìtàn.

Wọn tí kò àwọn èèyàn jọ láti ṣiṣẹ lórí rẹ, àwọn èèyàn náà sì ti pé mi láti wá nínú sinimá náà.

Wọn tí ń kó owó tó tó ₦500,000,000 jọ láti fi ṣe sinimá Ogbori Elemoso, mo sì ti sọ fún wọn pé owo naa yoo tó, yóò sì sẹ̀ku, àdúrà mi ni pé kó soju ẹmi wa."

"Kii ṣe pé Duro Ladipo ní oogun kankan lo ṣe ń yọ iná lẹ́nu bíi Sango àmọ́ pẹlu agbára àwọn àgbà tí àtijọ́, ni wọn fi ń ṣe bẹ́ẹ̀"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀dá Onileola tún ṣàlàyé nípa ẹ̀bùn tó ní èyí tó fi máa ń paarọ ohun rẹ.

O ni oun máa ń sọ̀rọ̀ bíi elegun, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ń tọ òun wà pé àwọn fẹ́ wá wo iṣẹ́ lọdọ òun, tí òun kò sì mọ nípa rẹ.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ààrẹ tẹ̀lẹ́ nílẹ̀ Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo, àgbà òṣèré tíátà náà ni ọrẹ tímọ́tímọ́ ni Obasanjo àti ọ̀gá òun, Duro Ladipo, tó sì máa ń wà ọ̀gá òun wá sílè.

"Obasanjo máa ń rọ ọ̀gá mi pé kò tọju mi daadaa nítorí òun fẹ́ràn ipa tí mo máa ń kó nínú eré.

Lẹyin ti ọ̀gá mi kú tán, mo sì máa ń lọ sílé Obasanjo ni Ota àti Abeokuta láti lọ bẹ wọn wo,mo sì máa ń sún síbẹ̀."

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ibasepọ ọ̀gá rẹ àti òun náà, ó ní ọ̀gá òun mú òun mọ́ra bí àbúrò rẹ̀ torí Mama rẹ tí rọ ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

"Ní ọjọ́ kan Mama ọ̀gá mi béèrè pé nibo ni ile wa nilu Ogbomoso, mo sì ní ilé Ikoyi Ẹ̀ṣọ́ ni Oke Òṣupà ni.

Mama sọ pé ilé tí òun bí Duro Ladipo sí nìyẹn torí àwọn tó bá wá sí ilé ìwòsàn Baptist máa ń sún mọju nile wá, nítorí náà, máa ní èmi kii ṣe ọmọṣẹ oga mi mọ, bikoṣe àbúrò rẹ̀, ọga mi náà sì fa mi mọ́ra."

Bákan náà, Eda Onileola ni ọ̀gá oun Duro Ladipo ni akíkanjú pupọ, ọmọ ojisẹ Ọlọhun ni òun náà, ìṣẹ olùkọ́ sì lo ń ṣe tẹ́lẹ̀, kò tó bẹ̀rẹ̀ ere tíátà.

" Kii ṣe pé ó ní oogun kankan lo ṣe ń yọ iná lẹ́nu bíi Sango àmọ́ pẹlu agbára àwọn àgbà tí àtijọ́ ni wọn fi ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Gbogbo agbára tó ni lo fi ń ṣe bẹ́ẹ̀

" Bí ere tíátà ṣe gbé mi dé ìlú òyìnbó rèé lọ́dún 1965"

Lere Paimo tún mẹ́nubà irinajo rẹ sí ìlú Ọba láti ipasẹ eré tíátà ni ọdún 1965.

O ṣàlàyé pé nígbà tí orilẹ̀èdé Naijiria wo ohun tí awọn ń ṣe, wọn fẹ́ rán àwọn eléré ìbílẹ̀ kan lọ sí Commonwealth Arts Festival nilu London, idije náà sì wà laarin Duro Ladipo, Kola Ogunmola àti Herbert Ogunde.

Paimo ni wọn ṣe idije nilu Ibadan àti Eko láti mọ ẹni tó kúnjú ìwọ̀n, tí ikọ eléré Duro Ladipo sì ṣe ère Ọba Koso, wọn ko ìlú jáde, bàtá àti ijo sì ń lọ, kò pẹ rárá tí wọn sì fi kéde pé àwọn lo gba ipò Kínní.

"Bi a ṣe lọ silu Oyinbo nìyẹn lọ́dún 1965, a ṣeré ni London, Cardiff, Glasgow ati Liverpool, ka to padà sílè"

"Bola Tinubu gbé owó ńlá fún èmi àti Adebayo Faleti torí ipa tí a kó nínú eré Saworo Ide"

Ẹda Onileola ni ère Saworo Idẹ tún jẹ́ ere sinimá kan tó fún òun ní òkìkí lásìkò tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu wá nípò gomina nipinlẹ Eko.

Mo wá lọ kí Bola Tinubu ni Èkó, wọn fún mi jí owo, bákan náà, wọn ní kí n fún alàgbà Adebayo Faleti ni owo pẹlu.

Bi mo ṣe gbé owó náà fún Faleti, kò mọ ohun tó le se mọ, ó sá yanu silẹ ni torí ṣáájú ọjọ́ náà, ní kó rí owó irinṣẹ oko tó yá láti ṣiṣẹ nínú oko rẹ san, táwọn onitoun si ko àwọn irinṣẹ naa lọ.

Owo ti mo fún wọn náà, wọn kò rí irú rẹ rí."

Kódà, Eda Onileola tún mẹ́nubà àwọn àmì ẹyẹ tó tí gba bíi àmì ẹyẹ osere tó dantọ julọ

"Ọjọ́ tí inú mi bajẹ julọ ni ọjọ́ tí manija mi di olóògbé nígbà tí a lọ ra mọto tuntun ni agbegbe Ikare"

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìrírí Manigbagbe rẹ, Lere Paimo ni ọpọ ìṣẹ̀lẹ̀ Manigbagbe rẹ pọ jaburata bíi fífi ojú wina ìjàm̀bá mọto.

"Ọjọ́ tí inú mi bajẹ julọ ni ọjọ́ tí manija mi di olóògbé nígbà tí a lọ ra mọto tuntun ni agbegbe Ikare.

Òun gbé mọto tuntun, èmi wa èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀, àmọ́ bo se gbéra, tó kọjá wá báyìí, lo lọ ha si abẹ tirela, tó sì kú.

Ọjọ́ tí inú mi dùn ni ọjọ́ tí mo gbà lẹ́tà sì mi pé kí n wá gba òye MFR nílẹ̀ Naijiria.

Èmi àti Dangote pẹlu Adenuga là jọ gba àmì ẹyẹ náà. Èmi ti mo ń jó bàtà kiri lásán ni mo wá gba àmì ẹyẹ, ó jé ohun tó jẹ́ ìyàlẹ́nu sì mi."

"Mo rọ àwọn ọmọ wa nìdí isẹ tíátà pe ki wọn máṣe wọ ẹgbẹkẹgbẹ, kò asakasa, wọ aṣọ oníhòòhò tàbí máa bó ara"

Ni akotan ọ̀rọ̀ rẹ̀, Oloye Lere Paimo wá gba àwọn ọdọ tó ń ṣiṣẹ́ tíátà lásìkò yìí ni imọran gidi.

"Ìyànjú mi sí àwọn ọmọ wa tó ń ṣiṣẹ́ tíátà ni pe ki wọn máṣe wọ ẹgbẹkẹgbẹ, kí wọn máṣe kò asakasa, kí wọn sì jawọ nínú wíwọ aṣọ oníhòòhò tàbí máa bó ara.

Bákan náà ni mo ń rọ wọn pé kí wọn máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà, kí wọn sì máa gbé ere tiata tí yoo maa kọ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ síta."

Oloye Lere Paimo dúró, wọn wọ aṣọ agbada olómi Kọfi, wọn si de fìlà aṣọ náà. Wọn lo awo oju.

Oríṣun àwòrán, Lere Paimo

Àkọlé àwòrán, Oloye Lere Paimo

Ta ni Lere Paimo?

Odu, tí kìí ṣe aimọ fún Oloko ni agbo ere tiata ni Oloye Lere Paimo tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Eda Onileola

Ọjọ Kọkàndínlógún oṣù kọkànlá ọdún 1939, eyiun ọdún mẹrindinlaadọrun sẹ́yìn, ni wọn bí Lere Paimo silu Ogbomoso.

Orúkọ agboole rẹ nilu Ogbomoso ni Ile Ikoyi Ẹsọ ni agbegbe Osupa.

O ka ilé ẹ̀kọ́ alakobere ni ilu Ogbomoso, kò tó orile ìlú Ghana níbi tó ti kàwé gba iwe ẹri olùkọ́ ònípò kejì, tó sì ń ṣiṣẹ́ Olùkọ́ nibẹ.

Àmọ́ nígbà tó padà dé, ìlú Osogbo lo tẹdo sì, tó sì ń bá isẹ olùkọ́ lọ nibẹ.

Ọdún 1958 lo dára pọ mọ ẹgbẹ́ òṣèré tíátà Oyin Adejobi, kò tó tún lọ dára pọ mọ ẹgbẹ́ òṣèré Duro Ladipo.

Lára àwọn ere tiata to sọ Lere Paimo di olókìkí ni Ogbori Elemoso, Ọba Koso àti Saworo Ide bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kopa ninu ere tiata tó lè ní igba.

Bákan náà, Lere Paimo tí gbà àmì ẹyẹ lorisirisi nínú isẹ tíátà, tó fi mọ àmì ẹyẹ ilé wa, Member of the Federal Republic, MFR.

Lọ́dún 2014 ni ìròyìn gbalẹ pé alàgbà Lere Paimo ni aisan Rọparọsẹ àmọ́ tí orí tí kò yọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kopa ninu ere tiata mọ láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.