Ẹgbẹ́ ASUU ṣe ìwọ́de rẹ́ àkọ́kọ́ lábẹ́ ìjọba Tinubu, wọ́n lérí ìyansẹ́lódì

Pupọ ninu awọn ipinlẹ to wa ni orilẹede Naijiria ni awọn ọmọ ẹgbẹ olukọ fasiti, ASUU, ti ṣe iwọde lonii ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹjọ, ọdun 2025.
Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU ẹka ti fasiti ilẹ Ibadan naa darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn jakejado orilẹede Naijiria lati ṣe iwọde lori awọn ẹtọ ati ajẹmọnu ti wọn n beere lọwọ ijọba apapọ.
Akọroyin BBC to wa nibi iwọde naa, jabọ pe iwọde to n lọwọ yii ni wọn fi n kilọ fun ijọba saaju iyanṣẹlodi alaini gbedeke to ṣe e ṣe ko waye bi ijọba ba kọ lati ṣe awọn nnkan ti wọn fẹ.
Lati bii ọdun meji sẹyin ni ijọba ti n pẹtu si ẹgbẹ awọn olukọ naa ti wọn ko si gunle iyanṣẹlodi kankan, ṣugbọn iwọde ti wọn ṣe lonii, ọjọ Iṣẹgun, fihan wi pe ijọba ti tan wọn ni suuru.
Ki ni ẹgbẹ ASUU n fẹ gan-an lọwọ ijọba?

Lara awọn nnkan ti ẹgbẹ ASUU n beere lọwọ ijọba Naijiria ni idunadura lori awọn adẹhun ti wọn jọ ṣe l'ọdun 2009.
Wn tun ni awọn fẹ igbesẹ tako eto ẹyawo ti ijọba gbe kalẹ fun ẹgbẹ naa nitori wọn ri eto naa gẹgẹ bii ọgbọn alumọkọrọi ti ijọba n da lati sọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa di ajigbese ati wi pe ko bojumu bi ijọba ṣe sọ wi pe ki ẹgbẹ naa maa ṣe oniduro fun olukọ fasiti to ba fẹ ya owo lọwọ ijọba apapọ.
Bakan naa ni ẹgbẹ naa n ke si ijọba lati mu adinku ba apọju fasiti lorilẹede Naijiria.
Nnkan miran ti wọn tun n fẹ ni pe ki wọn fikun igbayegbadun awọn Ọjọgbọn ati oṣiṣẹ to ku, ki wọn si tu okun lọrun awọn oṣiṣẹ ti wọn fungun mọ ni awọn fasiti kan.
Ẹgbẹ ASUU rawọ ẹbẹ si awọn alẹnulọrọ lawujọ, awọn aṣoju ile igbimọ aṣofin, to fi mọ awọn aṣiwaju ẹsin lati kan an nipa fun ijọba apapọ ki wọn le mu adehun ṣẹ.
Diẹ lara awọn aworan lati ibi iwọde ASUU
Lara awọn nnkan ti awọn aṣoju ẹgbẹ ASUU ni fasiti ilẹ Ibadan sọ ni wi pe ọwọ ti ijọba fi n mu ọrọ ẹgbẹ naa ti da ọpọlọpọ ipenija ati wahala si wọn l'agbada.
Wọn ni pupọ ninu awọn olukọ lo n sun si ọọfiisi mọju laarin ọsẹ nitori ko si owo lati ra epo si ọkọ, bẹẹ si ni pupọ ninu wọn ti pa awọn ọkọ ti wọn n lo ti.
Ẹgbẹ naa fi kun ọrọ wọn wi pe aibikita ijọba apapọ tun n ṣe akoba fun awọn akẹkọọ naa nitori ko si awọn ohun elo amayedẹrun to le mu ẹkọ rọrun fun wọn.
Awọn aṣoju ẹgbẹ naa ṣe alaye wi pe ipade kan yoo waye laarin ẹgbẹ ASUU ati ijọba apapọ laarin ọjọ meji si asiko yii, abajade ipade naa si ni yoo si sọ boya ọrọ naa yoo ni ojutuu tabi ki o yọri si iyanṣẹlodi alaini gbedeke jakejado orilẹede Naijiria.



















