ASUP Strike: Bí ìjọba kò bá dáwa lóhùn, a ṣetán láti fi kún ìyanṣẹ́lódì - Ezeibe

ASUP

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ̀ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe Poly ti ní ó ṣeéṣe kí àwọn fi ọjọ́ kún ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ ọ̀sẹ̀ méjì èyí tí àwọn gùnlé tí ìjọba bá kọ̀ láti ṣe gbogbo ohun tí àwọn ń bèèrè fún.

Ààrẹ ASUP, Anderson Ezeibe ní nǹkan méjì péré nínú márùn-ún tí ẹgbẹ́ àwọn ń bèrè lọ́wọ́ ìjọba ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe.

Ezeibe ní ohun tí ìjọba ṣe ni sísan àjẹ́lẹ̀ owó oṣù tuntun tó kéré jùlọ fún àwọn olùkọ́ àti fífún àwọn ní ohun èlò fún ìbuwọ́lù àwọn ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ láti wà ní ìbámu pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́ ní àgbáyé.

Ó ní àwọn ohun tí àwọn ń fẹ́ gangan, tó jẹ́ àwọn lógún ni kí ìjọba fún àwọn ní bílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún náírà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari buwọ́lù ní ọdún tó kọjà.

Bákan náà ló ní ìjọba kò ì tíì fèsì sí igbe ẹgbẹ́ náà lórí ìfìyàjẹ́ni èyí tí àjọ tó ń rí sí àkósoàti ìmọ̀ ẹ̀rọ (Institute of Management aand Technology), Enugu fi ń jẹ àwọn.

Àkọlé fídíò, Ayodeji Rotinwa ni ìròyìnn òfegè gbé àwòrán rẹ̀ síta pè dókítà tó ń pa àwọn Hausa mùsùlùmí

Ezeibe wìye wí pé kò sí ohun tí ìjọba kò le ṣe nínú gbogbo ìbéèrè àwọn àmọ́ tí wọ́n bá kọ̀ láti ṣe àmúṣẹ àwọn ìbéèrè wọ́nyìí, àwọn ti ṣetán láti fi kún ìyanṣẹ́lódì àwọn.

"Nínú oṣù kẹfà ni ìpàdé gbogbogboò àwọn aláṣẹ wa, tí a bá pàdé, a ó fẹnukò lórí ìgbésẹ̀ mìíràn tí a máa gbé."

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Bí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ṣe ń yan iṣẹ́ lódì náà ni ASUU náà ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì láti inú oṣù kejì ọdún 2022.

Èyí sì ti mú kí ètò ẹ̀kọ́ gbogbo dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga.

Bákan náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń ṣe ìwọ́de láti fi èhónú wọn hàn lórí bí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín ìjọba ASUU àti ASUP ṣe ń ṣe àkóbá fún wọn.