2023 Elections: Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye tó ń ṣojú ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Kogi ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Abuja tẹ́lẹ̀ rí ti tún fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.

Tajudeen Yusuf tó ń ṣojú ẹkùn Kabba/Bunu Ijumu ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ní òun àti Dino Melaye ń dún ipò náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Karùn-ún ni ètò ìdìbò abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ tí kò sì sí ẹni tó mókè nínú àwọn méjééjì nítorí wí pé ìbò méjìdínláàdọ́run ní àwọn méjéèjì ní.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní ètò ìdìbò náà tẹ̀síwájú tí Yusuf sì fi ẹ̀yìn Dino janlẹ̀ pẹ̀lú ìbò 163 sí 99.

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

Nígbà tó ń kí Yusuf kú oríire, Melaye lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó dìbò fún òun àti pé ètò ìdìbò náà tí wáyé, ó sì ti parí.

"Mo kí T.J Yusuf kú oríire, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó dìbò fún mi ní ìgbà àkọ́kọ́ àti èkejì."

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Ó ní bí àwọn ènìyàn ṣe lẹ̀dí àpòpọ̀ tako òun jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu ṣùgbọ́n òun dúopẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run"

Ní ẹkùn ìlà oòrùn Kogi, Victor Adoji ni tíkẹ́ẹ̀tì náà jámọ́ lọ́wọ́ láti díje dupò sẹ́nétọ̀ lọ́dún tó ń bọ̀.