2023 Elections: Aṣòfin Aisha Binani fìdí àwọn ọkùnrin márùn-ún janlẹ̀ níbi ètò ìdìbò abẹ́nú

Aisha Binani

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ààrin gbùngùn ìpínlẹ̀ Adamawa ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní ìlú Abuja, Aishatu Binani ti di obìnrin àkọ́kọ́ tó jáwé olúborí ìdìbò abẹ́nú láti gbé àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú níbi ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023.

Binani tó ń díje lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ló fi ẹ̀yìn àwọn ọkùnrin márùn-ún janlẹ̀ níbi ètò ìdìbò abẹ́nú náà.

Lára àwọn tó bá Binani díje ni adarí àjọ EFCC tẹ́lẹ̀ rí, Nuhu Ribadu, gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Adamawa, Umaru Bindow, Abdulrazak Namdas, Wafari Therman àti Umar Mustapha.

Nígbà tó ń kéde èsì ìdìbò náà, alága ètò ìdìbò abẹ́nú ìpínlẹ̀ Adamawa, Alhaji Gambo Lawal ní Binani ní ìbò ọ̀tàlénírinwó, èyí tó jẹ́ ìbò tó pọ̀ jùlọ.

Àkọlé fídíò, Children Day 2022: Àwa Obìnrin kìí ṣe àpínmógún, àtẹ̀mẹ́rẹ̀; àwa ní iyọ̀ àti ìrèké ayé

Ìkò Ipolongo tí APC yàn sáájú ìdìbò sípò gómínà ní Ekiti rè é…

Asia APC

Oríṣun àwòrán, @APC

Idibo sipo gomina naa yoo waye ni Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Ajọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu APC, National Working committee ti yan eniyan mọkanlelọgọta lati dari eto ipolongo ẹgbẹ naa fun idibo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Ekiti.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa gbe jade ni wọn ti fi lede bẹẹ, ti wọn si rọ wọn lati ṣiṣẹ takuntakun lasiko idibo naa.

Gomina ipinlẹ Kebbi,Atiku Bagudu to jẹ adari ikọ ipolongo naa ni ko si ẹni to gbọdọ sunkun wale ninu wọn amọ ki wọn rẹrin ayọ wale ni.

Awọn to wa ninu ikọ ipolongo naa ni Igbakeji Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Agba, Ovie Omo-Agege; gomina akọkọ labẹ iṣẹjọba tiwantiwa nipinlẹ Ekiti ati minisita fun karakata ati idokowo , Adeniyi Adebayo; minisita fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe, Babatunde Fashola.

Àkọlé fídíò, Ayodeji Rotinwa ni ìròyìnn òfegè gbé àwòrán rẹ̀ síta pè dókítà tó ń pa àwọn Hausa mùsùlùmí

Lara wọn naa ni awọn gomina bii Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, Ben Ayade, Inuwa Yahaya, Abubakar Badaru, Simon Lalong ati Hope Uzodimma ati bẹẹ bẹe ̣lọ.

Bakan naa ni adari ajọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu APC , Sẹnatọ Abdullahi Adamu ni ko si ewu fun gbogbo awọn ti yoo ṣiṣẹ lasiko idibo naa.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Adamu rọ wọn ki wọn ripe ẹgbẹ oṣelu APC lo le iwaju tente ninu idibo sipo gomina ti yoo waye naa.

Idibo sipo gomina naa yoo waye ni Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

labour party logo

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, labour party logo

Ẹgbé òsèlú méje darapọ̀ mọ́ ẹgbé òṣèlú Labour Party fún Ètò ìdìbò Ààrẹ

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa ni láti lé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti APC kúrò ní ètò ìjọba

Ẹgbẹ oselu ADC, PRP, NNPC, ADP, APM, SDP ti kede ìpinnu wọn lati fowosopo pẹlu ẹgbẹ oselu Labour Party.

Ẹgbẹ oselu ADC, PRP, NNPC, ADP, APM, SDP ti kede ìpinnu wọn lati fowosopo pẹlu ẹgbẹ oselu Labour Party ninu igbinyanju lati gba eto ìjọba orile-ede Naijiria kuro lọwọ ẹgbẹ oselu PDP àti APC ninu eto ìdibo ipo aarẹ ọdun 2023.

Eyi waye pẹlu igbinyanju lati gba eto ìjọba orile-ede Naijiria kuro lọwọ ẹgbẹ oselu PDP àti APC ninu eto ìdibo ipo aarẹ ọdun 2023

Ajọ National Consultative Front lọ kede oro naa ni ana ode pẹ ẹgbẹ oselu Labour Party ti di ẹgbẹ oselu kẹta to ni agbara julọ lati bori ninu eto ìdibo to ń bo ni ọdun 2023.

Ajo NCFront jẹ orulẹ fun awọn ẹgbẹ oselu miran yato si ẹgbẹ oselu PDP àti APC.

Ifowosowopo naa lọ waye lẹyin Ipadẹ olooṣu medogun ti awọn oludari Labour Movement ati awọn ẹgbẹ oselu Labour Party ti awọn oga agba fun ọmọ ẹgbẹ osisẹ Naijiria NLC ati TUC labe iṣakoso Ayuba Wabba ati Quadri Olaleye sì le iwaju igbinmo naa ti o sokun fa bi awọn ẹgbẹ oselu naa se Idarapo.

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

Agbenuso NCFront, Bilikis Bello ninu atesita kan sọ pẹ ;

"ibi ẹgbẹ oselu Labour Party gẹgẹ bi ẹgbẹ oselu kẹta to ni agbara julọ ni yio fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria bi ogun milionu ni afani lati darapo mo ẹgbẹ oselu naa, ti iforukosile sì ti wa kaakiri orile-ede Naijiria.

"Awọn ọmọ orile-ede Naijiria tun ni afani lati lọ ayelujara fun iforukosile ati pe ẹgbẹ oselu naa fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria to wa ni oke òkun láti Idarapo

"Awọn oludari ẹgbẹ naa ni Ojogbon Attahiru Jega ti ẹgbẹ oselu People's Redemption Party, Ojogbon Pat Utomi ti ẹgbẹ oselu Labour Party ati Sẹneto Saidu Dansadua tí ẹgbẹ oselu National Rescue Movement pẹlu awọn ẹgbẹ oselu miran ti a yan lati mu ọmọ òye tí yio tu'kọ eto ijoba orile-ede Naijiria."

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

Bello ni awọn oga agba fun ibasepo awọn oselu naa ni o kede fun awon ọmọ orile-ede Naijiria ni osẹ tí wọn sì kede awọn ilana eto ijoba wọn.

"A ma kede awọn erongba ati ilana eto ijoba ti a ni fun itusile orile-ede wa lọwọ awọn alagbara ni osẹ to n bo."

apc logo

Oríṣun àwòrán, others

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹgbẹ Oselu to n dari ẹto ijọba orile-ede Naijiria APC tí sun ayẹwo fun awọn tio fe di ọmọ òye fun ẹgbẹ oselu naa fun ipo aarẹ to yẹ ko waye ni ojo aje oni siwaju.

Agbenuso fun Ẹgbẹ oselu naa, Felix Morka ninu atesita kan to fi sita lana, ni ko si idi kan pataki ti atunse fi wa fun eto ayẹwo fun ìdibo abele fun ipo aarẹ naa.

Ojo ketalelogun oṣu karun-un ni o yẹ ki eto ayẹwo naa waye.

Atesita naa ni;

"Ẹto ayẹwo fun ìdibo abele to yẹ ko waye ni oṣu karun-un ni ati sun siwaju, tí ẹgbẹ oselu naa o sì kede ojo tuntun laipe."

"kosi idi kan pataki ti atunse fi wa si bí eto ayẹwo naa,sugbon gbogbo igbinyanju wa ni lati mu iyapada to da ba ẹgbẹ oselu APC.

"A tọrọ foringin fun leleyi."

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

Ninu wọn lati ri, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Igbakeji Aare orile-ede Naijiria, Yemi Oshinbajo, Gomina ana Ibikunle Amosun, Gomina Kayode Fayemi, Gomina Yahaya Bello, Oluso Aguntan Tunde Bakare, Ojogbon Ben Ayeda ati beẹ bẹe lọ.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Bi eto idibo abele ẹgbẹ oselu naa yio se waye niyii;

Ojọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, ọdun 2022: Idibo abẹlẹ fun awọn oludije si ipo gomina ati aṣojusofin ni Ile Igbimọ Aṣofin apapọ kekere (Governorship and House of Representatives).

Ojọ Eti, ọjọ kétadinlọgbọn, osu karun un ni eto Idibo abẹle fun awọn oludije si Ile Igbimọ Aṣofin Agba ati Ile Igbimọ Aṣofin ti ipinlẹ.

Ojọ Eti, ọjọ kétadinlọgbọn, osu karun un ni Igbẹjọ kotẹmilọrun lori eto idibo sipo gomina ati Ile Igbimọ Aṣofin kekere.

Ojọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun un ni Igbẹjọ kọtẹmilọrun fun idibo abẹle fun ipo aṣofin ni Ile Igbimọ Aṣofin Agba.