Afghanistan: Taliban gbé òfin kalẹ̀ lórí àwọn Obìnrin atọ́kùn ètò, bó ojú rẹ tóo bá fẹ́ ka ìròyìn bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....

Awon akoroyin Afghanistan

Taliban gbé òfin kalẹ lórí àwọn obìnrin atọ́kùn amóhunmáwòrán, bójú rẹ tó bá fẹ ká ìròyìn bí bẹ́ẹ̀ kọ̀...

Awọn obinrin atọkun eto lori amohunmaworan lorile-ede Afghanístàn ti bẹrẹ sí ní boju ka iroyin.

Igbesẹ yii to bẹrẹ lọjọ Aiku w àní ibamu pẹlu aṣẹ ijọba Taliban.

Lọjọ Àbámẹ́ta ọpọ lo tapa si àṣẹ yi ti wọn kò sí boju wọn.

Obinrin atọkun eto kan sọ pe awọn obinrin yari lati tẹle aṣẹ yi ṣugbọn awọn oga ileesẹ ko fi awọn lọrùn sílẹ.

Lẹyìn ti Taliban gba ijọba lọdun to kọja ni wọn ti n gbe orisi idiwọ kalẹ lori awọn obinrin.

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

Kaakiri awọn ileesẹ iroyin bi TOLO news, Ariana Television, Shamshad TV ati 1TV l'awọn obinrin ti wọ Hijaabu ati Niqob lati fi ka iroyin.

Atọkun obinrin kan lori TOLOnews Farida Sial sọ fun BBC pe: "Ko si wàhálà pe a jẹ musulumi ti o sí rọrun fún wa láti borí tabi wọ Hijaabu ṣugbọn o nira lati boju fún nkan bi wakati meji sí mẹta lati maa ka iroyin"

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

O loun fe ki awọn orileede agbaye parọwa sí Taliban lati yi ofin yi pada.

"Wọn fẹ pa awa obinrin rẹ kuro ninu isẹmi ayé àti agbo oselu ni"

Ṣaaju ni ileesẹ to wa nidi eto itẹsiwaju ihuwasi ọmọluabi ni abẹ ìjọba Taliban kéde pé kí gbogbo awọn obinrin máa wọ iboju n'ita bi bẹẹ kọ wọn yóò koju ijiya.

Ofin yi ni wọn nawọ rẹ dé ọdọ awọn obinrin atọkun lori ẹrọ amounmaworan ní ọjọ Àbámẹ́ta.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Awọn obinrin kan kọkọ yari ṣugbọn wọn padà gba nigba tí Taliban l'awọn yóò bá àwọn alagbatọ ati oga ileesẹ wọn sọrọ.

Ohun tí eyi tunmọ sí ni pe wọn yóò gbé ijiya kalẹ lori wọn bí wọn kò bá gba.

Púpọ awọn obìnrin atọkun ati akọroyin ni ko dunu sí igbesẹ yi ti wọn sì ṣe àpèjúwe rẹ gẹgẹ bí pe àwọn wa ninu 'idaro nla'

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Ọgá àgbà ileesẹ iroyin kan sọ pé ohun t'awọn n bẹru bayi ni pe wọn yoo gba awọn obìnrin yọ kuro lori amounmaworan patapata.

Ọpọ àwọn Musulumi lagbaye ni ko ka wíwọ iboju ni ita gbangba gẹgẹ bi ohun tó pọn dandan labẹ ofin ẹsin wọn.

Nigba ti Taliban sí kọkọ gbà ijọba wọn ṣe bi ẹni pe won fẹ dẹwọ́ diẹ.

Amọ lẹnu lọọlọ yi won ti n gbe awọn ofin kan kale lori awọn obinrin to fi mọ pé kí wọn máa lo Aaye inaju ni ọjọ tí o yatọ sí tàwọn ọkunrin.

Bẹẹ wọn ni wọn kò lè ririn ajo to ba jina lalae ṣe pé okùnrin tẹle wọn.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?