Lagos Island Building Collapse: LASEMA ti yọ ènìyàn márùn-ún láàyè, mẹ́ta ní òkú nínú ilé tó dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, lasema
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA sọ pe eeyan marun-un ni oun ti ri yọ jade labẹ àlàpà ile to wo ni Lagos Island lọjọ Satide, ọjọ́ kọkànlá, oṣù Karùn-ún, ọdun 2022.
Atẹjade ti agbẹnusọ ajọ LASEMA, Omowe Damilola Oke-Osanyintolu fi sita ni owurọ kutu ọjọ Aiku, sọ pe wọn tun yọ oku eeyan mẹ́a ni abẹ ile naa loru mọju.
Ọ̀mọ̀wé Osanyintolu sọ pe awọn ti de àjà tó kẹ́hìn nínú ilé nàá.
Èyí tó túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ìdóòlà ti parí.

Oríṣun àwòrán, Channels
Ilé nàá tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní ojúle kẹrin, Alayaki Lane, ní agbègbè Freeman, Lagos Island ló kọ́kọ́ gbẹ̀mí ènìyàn kan lásìkò tó dàwó.
Lásìkò tí òjò ńlá ń rọ̀ lọ́wọ́ ni ilé náà dàwò lulẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA, ṣe kọ́kọ́ ṣọ, iye ènìyàn tó ṣì há sábẹ́ ilé náà kò jẹ́ mímọ̀.
Adarí àjọ LASEMA, Ọ̀mọ́wé Olufemi Oke-Osanyintolu ní ènìyàn méjì ni àwọn kọ́kọ́ rí yọ láàyè , tí iṣẹ́ sì ń lọ́wọ́ láti yọ àwọn mìíràn tó há sábẹ́ ilé náà.
- 'Iye àwọn táa rí yọ láàyè, 23, àwọn tó kú sábẹ́ ilé alájà mẹ́ta ní Ibadan, Ebute Meta jẹ́ 10'
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
- Ó di dandan kí a wa iṣu dé ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí ó wó ní Ikoyi-Tinubu
- Ta ló gbé òkú ènìyàn sí pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed l'Ekoo? FAAN bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Anthony Albanese di olóòtú ìjọba Australia, ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rèé
- Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn dáná sun ilé mẹ́fà, ṣọ́ọ̀bù méje ní Bauchi lórí ẹ̀sùn sísọ̀rọ̀ òdì sí Islam
- Ìjọba Eko fún àwọn ọlọ́jà Alaba Rago ní gbèdéke láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún àtúnṣe
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí mẹ́fà lórí ikú "Sound Engineer"
- Àjọ tó ń mójútó iléeṣẹ́ Reluwé fagilé ìwọlé ìgbòkègbodò lójú irin Abuja-Kaduna
- Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbìyànjú láti dóòlà Deborah, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèrò borí wọn - Gómìnà Tambuwal
- Ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark pa ìyàwó rẹ̀ ọmọ Naijiria àti ọmọ wọn l'Eko, ìjọba dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún un
Ìṣẹ̀lẹ̀ ilé wíwó kò jẹ́ tuntun ní ìpínlẹ̀ Eko
Ní ọjọ́ kìíní, oṣù karùn-ún ni ilé alájà mẹ́tà kan dàwó ní agbègbè Ebute Metta tí ènìyàn tó sì bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ tó mẹ́wàá.
Láti ìgbà náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti fi òfin dè é wí pé wọn kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tó ju àjà mẹ́ta lọ mọ́ ní Ebute Metta.
Láti inú oṣù kọkànlá ọdún 2021 ní ìṣẹ̀lẹ̀ kí ilé máa dàwó tí ń wọ́pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko.


















