Australian Election: Anthony Albanese léwájú ẹgbẹ́ òṣèlú Labor borí ìdìbò lórílẹ̀èdè Australia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Anthony Albanese ni yoo di olotu ijọba tuntun lorilẹede Australia lẹyin tọ ko ẹgbẹ oṣelu Labor Party lorilẹede naa sodi lọ gbe'gba oroke fun igba akọkọ ninu eto oṣelu orilẹede naa lọjọ Abamẹẹta.
Albanese jẹ ọkan lara awọn oloṣelu ti ọjọ rẹ ti pẹ diẹ lagbami oṣelu orilẹede Australia. Ileri ayipada to dara lo ṣe fawọn eeyan orilẹede naa bi oun atẹgbẹ oṣelu rẹ ṣe n yọ ọwọ kilanko ajọṣepọ ẹgbẹ oṣelu Conservative Liberal-National coalition to ti wa lakoso ijọba lati ọdun 2013, iyẹn ọdun mẹsan an sẹyin kuro lawo iṣakoso orilẹede naa.
- A kò fẹ́ kí Kumuyi wá ṣe ìsọjí ìta gbangba nílùú Abia – IPOB
- Ki láwọn olóṣèlú Nàìjíríà rí tí wọ́n fi ń ṣé àbẹ̀wò sí ìyá arúgbó yìí ní Katsina?
- Fásitì fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kọ̀ọ́ tó tọ̀ sórí ẹrù èkejì rẹ̀ nítorí ẹ̀yà
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
Lẹyin wahala ajakalẹarun COVID-19 eyi to mu ọpọ awọn ipinlẹ lorilẹede naa lati bẹgi dina ajọṣepọ pẹlu awọn ipinlẹ miran ti wahala isede si mu ki ọpọlọpọ awọn ilu nlanla nibẹ o di ọmọ iya awusa, mimu iṣọkan pada di koko fun aṣiwaju tuntun ti orilẹede Australia ṣẹṣẹ yan naa.
"Mo fẹ mu awọn ọmọ orilẹede Australia pada di ọkan ṣoṣo. Mo fẹ ṣe ilepa awọn afojusun to so gbogbo wa pọ, ki n si tubo mojuto iṣọkan ati iwuri lati tẹsiwaju di[po ibẹru ati ipinya" ni ọrọ ti Anthony Albanese sọ alsiko to fi n ba awọn eeyan orilẹede naa sọrọ lẹyin to bori ninu idibo naa.
Ta ni Albo?
Ọgbẹni Albanese jẹ oloṣelu ti ọpọ mọ gẹgẹbi eeyan to n dide ja fun eto ilera ọfẹ, ati ẹtọ awọn eeyan abẹya kan naa lo, iyẹn LGBT ti o si tun fẹran ere idaraya Rugby pupọ.
Ẹni ọdun mọkandinlaadọta ni Anthony Albanese ti inagijẹ rẹ n jẹ 'Albo.'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iya rẹ lo wo o dagba pẹlu owo ifẹyinti awọn akanda, (disability pension) to n gba. Oun pẹlu kii si ye tọka si iriri ipilẹ aye rẹ gẹgẹ bi ara oun to mu ko maa lepa igbayegbadun fun araalu.
Ero rẹ ni pe baba oun ti ku ki wọn to bi oun saye, amọsa lati igba ewe rẹ lo ti mọ pe nṣe ni iya oun loyun fun arakunrin kan to ni iyawo sile lasiko ti arakunrin naa fi n kaakiri ilẹ Yuroopu- to si ṣeeṣe ko ṣi wa laye bi a ṣe n sọrọ yii.
Lẹyin ọdun mẹta si eyi lo ṣawari baba rẹ, Carlo Albanese.
O ni mama oun sa ipa rẹ lati rii pe oun lanfani si igbe aye irọrun ti oun ko ni. Pẹlu atilẹyin rẹ lo si fi di ẹni akọkọ ninu ẹbi rẹ ti yoo lọsileewe titi kan fasiti.
O ni ilepa ati fi igbe aye to tun rọrun, ju eyi ti oun pẹlu gbe lọ, silẹ fun ọmọ oun lo n ṣe koriya fun iṣẹ isinlu ti oun rawọ le.
Lọdun 2019 lo pinya pẹlu iyawo rẹ ti wọn fẹra fun ọdun mọkandinlogun bi o tilẹ jẹ pe ololufẹ rẹ, Jodie Haydon darapọ pẹlu rẹ lasiko ipolongo ibo rẹ gbogbo.
Aṣofin fun ọdun marundinlọgbọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọgbẹni Albanese ti di ipo aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu Labor Party mu fun ọdun mẹta, lẹyin to yẹ aga mọ aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa tẹlẹ Bill Shorten nidi nibi idibo to waye lọdun 2019, esi ibo naa si jẹ eyi to ya ọpọlọpọ eeyan lẹnu.
Amọṣa lati igba to ti wa ni ọmọ ogun ọdun le diẹ lo ti n ṣe oṣelu pẹlu ẹgbẹ oṣelu Labor.
Ni ọdun 2007, nigba ti ẹgbẹ oṣelu Labor bọ si oju awo iṣejọba labẹ Kevin Rudd, Ọgbẹni Albanese lo di minisita fun irina ati ohun elo igbayegbadun.
Imọlẹ rẹ ko si wọ okunkun nigba ti ẹgbẹ oṣelu naa ko sinu iji lile lẹyin ti wọn fi Julia Gillard rọpo Ọgbẹni Rudd lọdun 2010.
Nigba ti Ọgbẹni Rudd pada si ipo olotu ijọba ldun 2013, Albanese di igbakeji olotu ijọba nitori atilẹyin to ṣe fun Rudd. Amọṣa ko pẹ pupọ ni ipo naa. Ko lo ju ọsẹ mẹfa lọ nibpo naa ki ẹgbẹ oṣelu Labor to padanu idibo apapọ nibẹ.












