America Army: Wo ohun tí iléeṣẹ́ ológun ṣe fun obìnrin yìí lẹ́yìn ọdún Mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí wọ́n gba àkàrà òyìnbó lọ́wọ́ rẹ̀

Meri Mion

Iléeṣẹ́ Ológun orílẹ̀ èdè Amerika ti ra àkàrà òyìnbó fún ọmọbìnrin kan lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí iléeṣẹ́ ológun gba àkàrà òyìnbó rẹ̀.

Arábìnrin ẹni àádọ́rùn-ún ọdún náà, Meri Mion gbà ẹ̀bùn àkàrà òyìnbó fún ọjọ́ ìbí rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ológun Amerika lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọ́n gba àkàrà òyìnbò tó fẹ́ fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kẹtàlá rẹ̀.

Mion, ẹni tó pé àádọ́rùn-ún ọdún ní ọjọ́ Ẹtì wà ní ọdún mẹ́tàlá nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ogun wáyé ní ìlú rẹ̀ ní San Pietro ní ẹ̀bá Vicenta láàárín àwọn ọmọ ógun Amerika àti ti Germany.

Ìyá Mion ti ṣe àkàrà òyìnbó fún un láti fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà ṣùgbọ́n àwọn ológun Amẹ́ríkà tí ebi ń pa lásìkò náà gbà á lọ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì jẹ ẹ́.

Ó ní ọjọ́ tí òun kò lè gbàgbé nínú ìgbásí ayé òun ni ọjọ́ náà jẹ́.

Àwọn ológun ń gbé àkàrà òyìnbó lé Mion lọ́wọ́

Pẹ̀lú omijé ní arábìnrin Meri Mion tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Italy fi gba ẹ̀bùn àkàrà òyìnbó náà tó sì ní òun àti àwọn mọ̀lẹ́bí òun ni àwọn yóò jọ jẹ àkàrà òyìnbó náà.

Ní ọdún naa, Mion sá sí ibodè kàn pẹ̀lú ìyá rẹ nígbàtí tí ógun na bẹ̀rẹ̀ ni ó kú ọlá sì ọjọ́bi rẹ kí àwọn ọmọ ológun tó sọ ọjọ́ náà di ọjọ́ ìbànújẹ́ fún un.

"Emi àti àwọn mọ̀lébí mí ni a ó jẹ àkàrà òyìnbó náa láti ṣe ìrántí ọjọ málegbàgbé náà."

Ọga Àgbà ọmọ ológun Amerika, Sgt. Peter Wallis, ní o jẹ ìwúrí fún òun láti rí i pé àwọn dá àkàrà òyìnbó náà padà lẹ́yìn ọdún pípé.

"ìwúrí lọ je fún wà láti dá ẹ̀bùn ọjọ́ pípé náà padà fún arábìnrin náa.

Ọjọ́ ìdùnnú ẹ ní àwọn ọmọ ológun sọ di ọjọ́ ibanujẹ ṣùgbọ́n inú àwọn ọmọ ológun Amẹrika dùn láti ṣe ìdápadà lẹ́yìn ọdún pípẹ́."

Lẹ́yìn ayẹyẹ náà ni wọn kọrin ọjọ́ ìbí ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Italo.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua