Mwila Chansa lọ ṣiṣẹ́ àlááfíà ní Central African Republic, ó gba ọmọ tọ́

Captain Mwila Chansa

Oríṣun àwòrán, Mwila Chansa

Ọgagun kan nileeṣẹ ọmọ ogun Zambia to jẹ obinrin, Mwila Chansa ti sọrọ lori ohun to la kọja ninu igbiyanju rẹ lati gba ọmọ kan tọ lasiko to lọ ṣisẹ alaafia labe aisa United Nations ni Central African Republic.

Iya ọmọ naa loyun ibeji, amọ o dagberere faye ni kete to bi ọmọ akọkọ tan, ti ọmọ keji si ku ko to bi ọmọ naa.

Ọgagun Chansa gbọ itan aye ọmọ jojolo naa nigba to ṣabẹwo si Birao, to wa ni ala ilẹ Chad ati Sudan.

Lẹyin naa lo pinnu lati gba ọmọ naa tọ, amọ o ṣoro fun nitori ofin ẹsin Musulumi to wa nilẹ naa.

Obinrin naa sọ fun BBC pe "Mo lọ soju opo Google lati ṣe iwadii bi mo ṣe le gba ọmọ tọ lorilẹ-ede CAR,

ṣugbọn gbogbo ohun ti mo n ri nibẹ ko kọja ti USAid lọ ati bi awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ṣe le gba ọmọ tọ nibẹ, n ko ri nnkankan nipa bi ọmọ Zambia ṣe le gba ọmọ ni CAR."

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o gba lati koju oniruru ipenija ko le gba ọmọ naa tọ ko to ri gbe lọ silu Luzaka ni Zambia.

O ni "Ọrọ ọmọ naa mu mi ranti itan to wa ninu bibeli."

"Gbigba ọmọ tọ dabi igba ti eeyan ba yofẹ ni, ọpọ okunrin ni yoo kọ ẹnu ifẹ si obinrin amọ ẹyọkan ṣoṣo lo maa mu ninu wọn."

Iha wo ijọba Zambia kọ si igbesẹ naa?

Aarẹ Zambia, Hakainde Hichilema gbe oṣuba kare fun Chansa fun ifẹ ọmọniyea to ni lọkan, eyii to jẹ ko gba ọmọ naa tọ.

Igbeṣe Aarẹ naa jẹ ki ọpọ eeyan mọ si nipa ohun ti obinrin naa ṣe.

Àkọlé fídíò, Mothers day: Lẹ́yìn Olorun, Ìyá mi ló kù- Papa Ajasco, Abiodun Ayeyinka

O ni "Ọpọ eeyan lo n pe mi lori aago lẹyin igbeṣe naa, o si jẹ iyalẹnu fun mi."

Ọgagun naa ti sọ orukọ ọmọ ọhun ni Thabo bayii, o si ni oun ni erongba ati iran ọjọ iwaju rere fun ọmọ naa.

Chansa sọ pe "Erongba mi fun ọmọ naa ni pe ko di Aarẹ orilẹ-ede Central African Republic lọjọ iwaju, mo si gbagbọ pe yoo ri bẹẹ."

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya