Polygamy: Fífẹ̀ ju ìyàwó kan lọ ni àṣírí ẹ̀mí gígùn'

IGBEYAWO

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àwọn oluwadii kan ni Fasiti Sheffield ni orile-ede United Kingdom, ti sọ pe fifẹ iyawo meji ni aṣiri si ẹ̀mí gigun.

Lootọ ni ọpọ ọkùnrin le ro pe iyawo kan ní wahala tiẹ, sugbọn iwadii kan sọ pe kọ́kọ́rọ́ kan ṣoṣo to si ilẹkun ẹ̀mí gigun, ni ki ọkùnrin fẹ iyawo keji.

Àwọn oluwadii ọhun ni awọn ṣe iwadii naa laarin awọn ọkunrin ti ọjọ ori wọn ti le ni ọgọ́ta, kaakiri ogoje orile-ede.

Ohun ti wọn ṣàkíyèsí, gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Fox News, ṣe sọ, ni pe ẹ̀mí wọn gùn pẹlu ìdá mejila ju ti awọn akẹgbẹ wọn to wa ni awọn orile-ede ti ko faaye gba ile olorogun.

Gẹ́gẹ́ bi iroyin naa ṣe sọ, ọsẹ to kọja ni wọn kede abọ iwadii naa, nibi ipade apero International Society for Behavioral Ecology, n'ilu New York.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Ni ti awọn obinrin, awọn oluwadii naa sọ pe riri ati titọju awọn ọmọ-ọmọ wọn, ma n fun awọn obinrin ni ẹmi gigun.

Sugbọn o yatọ si ti awọn ọkunrin.

Bi iyawo ti wọn fẹ ba ṣe pọ to, ni iye ọmọ ti wọn bi naa yoo ṣe pọ, nitori pe wọn ni anfaani lati bímọ titi di ọjọ ogbó.

"Jijẹ baba fun ọpọlọpọ ọmọ, jẹ idi pataki ti iru àwọn ọkùnrin bẹẹ fi ma n tiraka lati pẹ laye ju awọn to fẹ iyawo kan ṣoṣo, to si tete n dawọ ọmọ bibi duro."

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi