Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára
Ipob: Awọn ọmọ ikọ ẹgbẹ agbesunmọmi to n gbe oju opo ayelujara da rugudu silẹ
Iwadii ileesẹ iroyin BBC kan ti tu asiri lori bi awọn ọmọ ikọ Ipob kan se n lo ojuopo ayelujara lati maa fi tan ọrọ inunibini ati ipaniyan ka lori awọn to tako idasilẹ Biafra.
Ikilọ ree, o ni awọn aworan kan ninu apilẹkọ yi ti ọkan rẹ le kọ.Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
Loju opo Facebook Live,Efe Uwanogho taa tun mọ si Omote Biafra n se ipolongo ọrọ inunibini sawọn ololufẹ rẹ.
O wọ jakẹẹti kan ti wọn ya aworan idanimọ Biafra si.
''Ẹ wa awọn obilẹjẹ yi kan, awọn leeyan to yẹ ki wọn bẹ lori.Awọn lo yẹ ki wọn dana sun di eeru''
O n pe fun ikọlu fawọn to ka si alatako idasilẹ Biafra eleyi ti yoo mu ki ilẹ Igbo ya pa kuro lara Naijiria.
- Ààrẹ Buhari pàrọwà sí ASUU láti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Fí fún ẹkùn tàbí ẹ̀yà kan ní tíkẹ́ẹ̀tì 'zoning' kò sí nínú òfin ẹgbẹ́ wa - PDP
- Wo àwọn mínísítà ìjọba Nàìjíríà tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí àṣẹ Ààrẹ Buhari
- Mọ̀ síi nípa IPOB tó ń gbé orí ayélujára dá rúgúdú sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ Biafra
- Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn
- Ọ̀rọ̀ pátà dídọ̀tí tún rúná sí ìjà láàrin Nkechi Blessing àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Falegan
- Èèyàn 60 l'erin ti pa láàrín ọdún yìí nìkan lórílẹ̀èdè Zimbabwe
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó bẹntiró ń rúgbó bọ̀- IPMAN ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
- Àwọn olùfẹ̀hónúhàn dáná sun dúkìá bí ìwọ́de ṣe ń le si
- Ọwọ́ tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìtura, wo nǹkan tí ọlọ́pàá ká mọ lọ́wọ́
Ipolongo ominira Biafra yi jẹ eyi to ni akọsilẹ itajẹsilẹ latẹyinwa.
Lọdun 1967.awọn ajijagbara lati ilẹ Igbo kede ominira ilẹ Biafra.
Ọdun mẹta ni wọn fi ba ijọba Naijiria jagun eleyi ti wọn fidirẹmi ninu rẹ.
Eeyan to ku le ni miliọnu kan.Ọpọ si wa lati ọdọ awọn ajijagbara yi.