Aiye Confraternity: Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye méjìdínlógún kò sí pámpẹ́ ọlópàá Ekiti lásìkò

Egbe Okunkun

Oríṣun àwòrán, Others

Ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti t i kéde pe awọn ti ribi mu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mejidinlogun ni ipinlẹ naa.

Awọn olubi yi la gbọ pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ti wọn si fura si pe wọn mọ nípa iku Ajayi Sunday ati Owolabi Moses ni oṣu kẹta ọdun yi.

Komisana ọlọpaa Ekiti, Moronkeji Adesina, sọ pé ni Ikole Ekiti láwọn ti mu afurasi mejidinlogun yi nibi ayẹyẹ igbanisẹgbẹ.

Bẹẹ lo ní wọn sì jẹwọ pe awọn mọ nípa iku awọn eeyan meji yi.

Kini ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti so?

Adesina, ti alukoro ọlọpaa Ekiti Sunday Abutu, soju fún ṣafihan awọn afurasi yi ati awọn metadinlogun mii fún oríṣi ẹsẹ miran bi ijinigbe ati jiji maalu gbe.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Abutu so pé "Ni nkan bi ago mẹjọ owurọ ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣù kẹrin ni awọn ìkọ wa yabo ibuba awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun nibi ti wọn ti n ṣé Ipade"

O darukọ awọn afurasi naa ti ọwọ tẹ gẹgẹ bi:Alayerogun, Fatoye, Ogunsakin, Oluwadare, Bimbola, Afolabi, Adelola, Ogundola, Adeyemo, Johnson, Kolawole, Babalola, Fanimo, Awoyemi, Charles, Thomas, Obanla ati Anjorin.

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

O fikun pe awọn ọlọpaa ṣí n tọ ipasẹ awọn to sa ninu wọn.

O daruko awọn nkán ìjà oloro ti wọn ká mọ wọn lọwọ bi ibọn,ada meji, ati awọn alupupu mẹwàá tí wọn fí n ṣe iwa aburú wọn.

Abutu tẹ siwaju pe awọn ọlọpaa tun ri awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meji mii mu ni ọjọ kẹẹdogun oṣù karun.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?

O ni wọn ṣe ikọlu s'àwon akẹ́kòó fásítì Ekiti ni ibùgbé wọn tó wà ní Iworoko-Ekiti.

O ni awọn afurasi meji naa Akinbo ati Shodipe jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ Aiye lawon.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa ṣe afihan awọn mi to jẹ adigunjalè to lọwọ nínú ikọlu si ile okowo pamọ́ Wema lọdun 2020.