Oyo Suspends Doctor and Nurse: Ìwà aṣemáṣe gbaṣẹ́ lọ́wọ́ dókítà àti nọ́ọ̀sì ní Oyo

Ẹ̀rọ aṣàyẹ̀wò

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àjọ tó ń mojútó àwọn ilé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ Ọyọ ti ní kí dókítà àti nọ́ọ̀sì kan lọ rọ́kún nílé fún ẹ̀sùn aṣemáṣe.

Alága àjọ Hospitals Management Board ìpínlẹ̀ Oyo, Dókítà Gbọla Adetunji nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2022 ní àwọn ní kí dókítà àti nọ́ọ̀sì ọ̀hún lọ rọ́kún nílé lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ́ àjọ náà jókòó lórí ẹ̀sùn wọn.

Adetunji ní ìwádìí àwọn ṣàwárí rẹ̀ wí pé àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì ọ̀hún jẹ̀bi ẹ̀sùn dídárí aláìsàn lọ sí ilé ìwòsàn aládàni láti lọ ṣe iṣẹ́ abẹ pàjáwìrì.

Ó ṣàlàyé pé aláìsàn tí àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì ọ̀hún darí lọ sí ilé ìwòsàn aládàni náà ló kọ̀wé takò wọ́n tí àjọ náà fi ṣe ìwádìí wọn.

Bákan náà ló fi kun pé ìwádìí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sí náà jẹ̀bì ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Èyí ló fà á tí wọ́n fi ní kí wọ́n lọ rọ́kún nílé fún ìgbà kan ná.

Ó sọ síwájú pé ìwà tí àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì náà wù lódí sí òfin iṣẹ́ ìjọba àti pé ó le ṣàkóbá fún iṣẹ́ ribiribi tí àwọn kan ń ṣe láti mú àgbéga bá àwọn ilé ìwòsàn tó jẹ́ tí ìjọba.

Adetunnji tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn tí jíròrò pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ náà láti yíwà wọn padà kí iṣẹ́ le máa lọ létòlétò.

"Ohun tí àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì ṣe yìí jẹ́ ohun tí kò tọ̀nà lẹ́nu iṣẹ́ wọn tó sì dàbí ẹni pé wọ́n fẹ́ bá iṣẹ́ tí gómìnà Seyi Makinde ń ṣe lẹ́ka èto ìlera jẹ́ ni."

Bákan náà ló ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn mìíràn láti kọ́gbọ́n láti ara àwọn tí wọ́n dá dúró náà nítorí àwọn yóò máa gbé ìgbásẹ akin lórí ẹnikẹ́ni tí adé ìwà ìbàjẹ́ bá ṣí mọ́ lórí.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...