English Premier League: Láàrín Manchester City àti Liverpool, ta ni yóò gba ife ẹ̀yẹ Premier League ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sáà 2021/2022 ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣe Manchester City ni yoo bori idije Premier League ilẹ Gẹẹsi tọdun yii ni tabi Liverpool? Ṣe Tottenham yoo lee moribọ wọ ipo kẹrin lati kopa ni idije Champions League saa to n bọ tabi orogun wọn lagbegbe North London, iyẹn Arsenal ni yoo pap fi ogun ẹyin ja wọn? Ewo ninu Burnley ati Leeds ti yo ja si agbami ifidirẹmi 'Relegation'eyi ti yoo sọ wọn di ero liigi keji ilẹ Gẹẹsi, iyẹn Championship?
Awọn ibeere wọnyii ni idahun yoo wa fun loni ọjọ Aiku ọjọ kejilogun oṣu karun un ọdun 2022 ti idije premier league ilẹ Gẹẹsi fun saa 2021 si 2022 yoo wọ ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba.
- Buhari yọ ikọ̀ D'Tiger, D'Tigress kúrò nídíje bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ lágbáyé fún ọdún méjì, ohun tó fàá nìyí
- FIFA ní kí àjọ bọ́ọ̀lù ní Nàìjíríà, NFF ó san N156m owó gbà máà bínú fún Gernot Rohr
- Ṣé Cristiano Ronaldo yóò dúró tàbí kò ní dúró n'Manchester United fún sáà líìgì tó ń bọ̀?
- Jurgen Klopp tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tuntun pẹ̀lú Liverpool di 2026
Igba akọkọ niyi laarin ọdun mẹwaa ti ifẹsẹwọnsẹ lati mọ olubori, awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrin ti yoo kopa ni Champions league ati awọn ti yoo jabọ si agbami 'Relegation' yoo wọ ọjọ to kẹyin ni saa liigi kan.
Laarin Manchester City ati Liverpool, ta ni yoo gba ife ẹyẹ Premier league lọdun yii?
Ami kan ṣoṣo ni Manchester city fi n la Liverpool lori atẹ igbelewọn liigi premiership ilẹ Gẹẹsi titi di ifẹsẹwọnsẹ to gbẹyin ni saa ligi naa lọjọ Aiku lẹyin ti man City ta ọmi pẹlu Westham ti Liverpool si ja fitafita lati bori Southampton lsẹ to kọja.
Iwọnba eeyan perete lo n lero pe Manchester city yoo sọ ife naa nu, nitori pe ko tii si igba kankan ninu itan premier league ti ẹgbẹ agbabọọlu to n lewaju atẹ igbelewọn liigi naa wọ ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin ni saa kan sọ ọ nu ri.

Idi ti ọpọ fi n nigbagbọ pe Mancity ni yoo papa gba ife ẹyẹ liigi ti ọdun yii ko ju bi ikọ naa ti ṣe yọ bi ọjọ tan bi oorun lati igba ti ifẹsẹwọnsẹ saa liigi yii ti bẹrẹ.
Akọnimọọgba Ikọ Manchester city, Pep Guardiola yoo maa ko ikọ rẹ sodi lọ koju Aston Villa ni ibuba wọn ni papa iṣire Etihad to wa ni ilu Manchester lai ni gbagbe pe bi awọn ba ti le bori Aston Villa aba lasan ni esi ifẹsẹwọnsẹ laarin Liverpool ati Wolves yoo jẹ.
Bi Mancity ba lee gba ife ẹyẹ liigi premiership ilẹ Gẹẹsi tọdun yii, yoo bu itura si ọgbẹ ijakulẹ wọn ni idije champions league ọdun yii lọwọ Real Madrid, pẹlu ifidirẹmi wọn lọwọ Liverpool ni ipele to kangun si aṣekagba ife ẹyẹ FA cup ilẹ gẹẹsi.
Bakan naa ni yoo bẹgina ilepa ife ẹyẹ mẹrin ni saa kan ṣoṣo eyi ti Akọnimọọgba Liverpool, Jurgen Klopp atawọn agbabọọlu rẹ n lepa lọwọ.
Liverpool ti gba ife ẹyẹ Carabao ati FA sinu aka wọn bayii, meji to ku naa ni liigi ati ife ẹyẹ Champions League fun saa yii.
Saa liigi ọdun ni yii ni igba kẹta ninu saa liigi mẹrin ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ati Liverpool yoo maa du ipo kini ati ikeji liigi premiership ilẹ Gẹẹsi mọ ara wọn lọwọ.
Yoo si jẹ igba keji lẹyin saa liigi ọdun 2018 si 2019 ti yoo maa jẹ pe ami kan ṣoṣo ni yoo la awọn mejeeji laarin.
Itakangbọn North Londo fun ipo kẹrin lori atẹ liigi ilẹ Gẹẹsi

Ọpọ igba lawọn eeyan maa n fi ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham Hotspur ṣe yẹyẹ pe wọn kii ye sọ ifa nu lasiko ti wọn ba ti wa niwaju to si yẹ ki wọn lo anfani ti wọn ni lati bori.
Yoo jẹ ohun ti yoo niran diẹ fun wọn lati tun padanu kikopa ni idije Champions league ilẹ Yuroopu ni saa to n bọ n bọ.
Bibori ti wọn tiraka lati bori Burnley lọjọ Aiku to kọja, ti Arsenal si fidirẹmi lọdọ Newcastle lọjọ Aje fihan pe Tottenham ni yoo wọ ifẹsẹwọnsẹ ọjọ to kẹyin ninu saa liigi 2021/2022 gẹgẹ bi onipo kẹrin ti wọn si fi ami meji kọja Arsenal lori atẹ igbelewọn Premier league ilẹ Gẹẹsi.
Ọmi lasan yoo fi ẹsẹ Tottenham rinlẹ bii kọnkere ni ipo kẹrin lori atẹ igbelewọn naa.
Arsenal si gbọdọ bori Everton ki wọn to le ni ireti ati yi aga pada mọ Tottenham nidi, iyẹn bi Tottenham ba yọ ṣubu lọdọ Norwich.
Ta ni yoo mu aye Europa kan to ku?

Yatọ si ọrọ Tottenham ati Arsenal, Manchester United ati Westham naa yoo maa ta kangbọn lati mọ ẹni ti yoo mu aye kan to ku fun idije Europa ni saa to n bọ ati ẹni ti yoo ja bọ sinu idije Europa Conference league.
Bi Manchester United ba bori Crystal Palace, a jẹ pe awọn ni yoo mu ipo kẹfa bi otiwulẹ ki esi ifẹsẹwọnsẹ West Ham ati Brighton o ja si.
Bi Manchester United ba lọ yọ gẹrẹ lasan, ilẹkun ṣi fun West Ham niyi, iyẹn bi awọn pẹlu ba lee gbiyanju ati na Brighton.
Burnley tabi Leeds, tani yoo jabọ si agbami 'relegation'?

Ipadabọ Everton nibi ifẹsẹwọnsẹ awọn ati Crystal Palace lọjọbọ nibi ti wọn ti yirapada lati goolu meji wa pada bori pẹlu mẹta si meji lo yọ wọn kuro ninu ọgbun agbami 'relegation'
Nibayii, ọrun Burnley ati Leeds ti ọran wa bayii.
Ọkan alara ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yii yoo ja si agbami 'relegation' ti yoo gbe lọ dara pọ mọ ikọ Norwich ati Watford ti wọn ti ri sinu ọgbun naa ṣaaju.
Burnley yoo gbalejo Newcastle, bẹẹni Leeds yoo l ba Brentford lalejo.
Ta ni yoo di atamatase ati goli to ta lẹnu julọ?
Lara awọn ibeere ti yoo ma nilo idahun lọjọ Aiku nigba ti ifẹsẹwọnsẹ to gbẹyin fun saa liigi premiership ilẹ Gẹẹsi 2021/2022 ba n kogba wọle ni ta ni yoo gba ami ẹyẹ agbabọọlu atamatase, iyẹn Striker to pegede julọ?
Bakan naa ni goli aṣọle to pegede julọ naa yoo tun nilo idahun.
Mohammed Salah, atamatase Liverpool to gba goolu mejilelogun si awọn alatako ni saa yii, Son Heun-min ti Tottenham lo n gbemu tii pẹlu goolu mọkanlelogun ti Chrristiano Ronaldo si ni goolu mejidinlogun.
Salah ti gba ami ẹyẹ yii ri ni saa 2017-18 ati 2018-2019.
Igba akọkọ ni yoo jẹ fun Son to ba gba a.
Ni ti awọn goli, yoo wa laarin Ederson aṣọle manchester city pẹlu Alisson to jẹ aṣọle Liverpool.
Ifẹsẹwọnsẹ ogun ni awọn mejeji yii ti gba ninu eyi ti awọn alatako ko ri awọn wọn da lu.













