Jurgen Klopp: Akọ́nimọ̀ọ́gbá Liverpool tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tuntun tí yóò múu wà nípò di ọdún 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, ti buwọlu adehun afikun ọlọọdun meji kun adehun rẹ to wa nilẹ tẹlẹ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu naa.
Lọdun 2024 lo yẹ ki adehun rẹ to wa nilẹ tẹlẹ pari, ṣugbọn adehun tuntun to fọwọsi bayii ti sun un di ọdun 2026 bayii.
Ni ọdun 2015 ni Klopp darapọ mọ Liverpool ki o to sọ ọ bi ẹna loṣu kẹta ọdun 2022 pe o ṣeeṣe ki oun gba isinmi kuro lẹnu iṣẹ akọnimọọgba lasiko ti saa adehun oun ba pari lọdun 2024.
- Láì tíì pé ọ̀sẹ̀ kan tó kéde akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun, Man U tún jẹ àjẹranjú ìyà lọ́wọ́ Arsenal pẹ̀lú góòlù Mẹ́ta sí ẹyọkan
- Àwọn olùwòran fàbínú yọ bí Super Eagles ṣe já kulẹ̀ láti lọ sí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé
- Ghana sọ ìrètí Naijiria láti kópa ní World Cup 2022 di òfo pẹ̀lú 1-1
- FIFA pàṣẹ pé Russia kò gbọdọ̀ díje pẹ̀lú àṣíá orílẹ̀èdè rẹ̀
Ife ẹyẹ marun ni Klopp ti gba pẹlu Liverpool lati igba to ti dara pọ mọ wọn.
Nigba to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu naa lọdun 2015, Klopp ṣeleri ati mu idunnu wa fawọn ololufẹ agbabọọlu naa lati mu wọn di ẹni to ni igbagbọ to jinlẹ ninu ilepa ikọ agbabọọlu naa lati ṣe aṣeyọri.
Nigba naa, Liverpool ko tii gba ife ẹyẹ liigi ilẹ Gẹẹsi lati ọdun 1990.
Klopp ko ikọ naa sodi gba ife ẹyẹ Champions League Yuroopu ni saa liigi ọdun 2018 si 2019 ki o to ko wọn sodi gba ife ẹyẹ liigi lọdun 2020.
Mo ti yo ifẹ Liverpool- Jurgen Klopp

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba to n buwọlu adehun tuntun naa, Klopp ni "inu oun dun, ayọ oun kun, oun si rii gẹgẹ bi anfani nlanla"
Klopp fi kun un pe " Nigba tawọn to ni ẹgbẹ agbabọọlu naa mu aba adehun tuntun tọ mi wa, mo bi ara mi leere ibeere ti mo maa n beere ni gbangba lọpọ igba. Ṣe mo ni agbara ati okun lati ṣiṣẹ naa lẹẹkansi lati ṣe awọn ohun ti ẹgbẹ agbabọọlu to dara yii nilo latọdọ ẹni to di ipo akọnimọọgba mu?"
"Ko gba mi lọpọ akoko lati ri idahun sii..ifẹ ibi yii ti gba ọkan mi."
Bakan naa lawọn amugbalẹgbẹ rẹ, Pep Lijnders ati Peter Krawietz naa ti tọwọ bọ iwe adehun tuntun pẹlu.












