Arsenal vs man United: Láì tíì pé ọ̀sẹ̀ kan tó kéde akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun, Arsenal j'ojú Man U pẹ̀lú góòlù Mẹ́ta sí ẹyọkan ní Emirate

Oríṣun àwòrán, Premierleague.com
Ọsẹ yii ṣẹnuure fun ikọ agbabọọlu Arsenal atawọn ololufẹ rẹ pẹlu bi wọn tun ṣe digbolu Manchester United lọsan ọjọ Abamẹta pẹlu goolu mẹta si ẹyọkan.
Iṣẹgun ti Arsenal ri lori Manchester United yii lo gbe wọn lọ si ipo kẹrin ṣaaju Totteham to ṣi ni ifẹsẹwọnsẹ tiwọn lọsan ọjọ Abamẹta kan naa.
Nuno Tavares lo kọkọ ṣide ojo goolu to rọ fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju naa wọ iṣẹju kẹta.
Laipẹ rẹ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejilelọgbọn ni Busayọ Saka ba tun fọba lee pẹlu pẹnariti lẹyin ti wọn gbe e ṣubu loju ile Manchester United.
Christiano Ronaldo, to ṣẹṣẹ pada sori papa lẹyin to padanu ọmọ rẹ ọkunrin laipẹ yii, da ẹyọ kan pada ki Bruno Fernades to sọ pẹnariti nu fun Manchester United lẹyin ti Tavares fi ọwọ gbe bọọlu loju ile Arsenal.
goolu ti Christiano Ronaldo gba wọ awn Arsenal yii ni yoo di goolu ọgọrun ti gbajumọ agbabọọlu naa yoo maa gba wọ awọn ni idije Premier league.
Ni ọjọ kini oṣu kọkanla ọdun 2003, tii ṣe ọdun marundinlogun sẹyin ni C. Ronaldo kọkọ gba goolu si awọn ni idije Premier League ninu ifẹsẹwọnsẹ Manchester United pẹlu Portsmouth ni gbede Old Trafford

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Granit Xhaka lo pa oju goolu de pẹlu bọọlu to gba sawọn eyi ti ọwọ gooli manchester United, David De Gea ko to.
Ten Hag ni yoo maa ṣakoso ikọ naa ni saa to n bọ.
Esi ifẹsẹwọnsẹ Manchester united pẹlu Arsenal yoo si wa lara awọn ohun ti yoo maa gbe yẹwo lati mọ pe omi n bẹ laamu fun oun lasiko to ba bẹrẹ iṣẹ pẹlu wọn.












