FIFA ní kí àjọ bọ́ọ̀lù ní Nàìjíríà, NFF ó san N156m owó gbà máà bínú fún Gernot Rohr akọ́nimọ̀ọ́gbá rẹ̀ tẹ́lẹ̀

Gernot Rohr

Oríṣun àwòrán, other

Gbese ẹgbẹrun lọna ọrinlelọọdunrun o din meji dọla ilẹ Amẹrika, ($378,000) ni ajọ bọọlu ni Naijiria, NFF jẹ akọnimọọgba ikọ agbabọọlu Super Eagles tẹlẹ, Gernot Rohr fun lile akọnimọọgba naa kuro lẹnu iṣẹ ṣaaju ọjọ to wa lori iwe adehun igbanisiṣẹ rẹ.

Ni oṣu kejila ọdun 2022 ni ajọ NFF yọ Rohr lẹnu iṣẹ nigba to ku ọsẹ mẹrin ki wọn bẹrẹ idije ife ẹyẹ bọọlu forilẹede Afirika lorilẹede Cameroun.

Wọn yan Austin Eguavoen rọpo rẹ.

Lootọ ni pe NFF ti gba tẹlẹ lati san owo oṣu fun akọnimọọgba naa titi di igba ti adehun iṣẹ rẹ yoo fi pari.

Rohr gbe ajọ NFF lọ siwaju ajọ bọọlu lagbaye, FIFA lati beere fun ẹkunwo si owo naa fun gbigba iṣẹ lọwọ oun lati ọjọ.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Miliọnu kan pọun owo ilẹ Gẹẹsi ni Rohr beere fun niwaju igbimọ olugbẹjọ FIFA, ṣugbọn ọrinlelọọdunrun o din mẹtalelogun ati diẹ dọla ($377,879.46) ni wọn fọwọ si fun un.

Ọjọ marundinlaadọta si ni FIFA fun ajọ NFF lati fi san owo gba maa binu naa fun Gernot Rohr, bibẹẹkọ, wọn yoo tun fi alekun owo itanran gbara.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

"Bi owo gba maa binu yii ko ba di sisan laarin ọjọ marundinlaadọta lẹyin idajọ yii, olujẹjọ (Ajọ NFF) yoo fi awọn itanran miran jora bii gbigbẹsẹle awọn ida kan ninu owo iṣuna idagbasoke ti wọn maa n gba, titi di igba ti wọn ba san owo naa pari."

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'