Cristiano Ronaldo update: Ṣé Cristiano Ronaldo yóò dúró tàbí kò ní dúró n'Manchester United fún sáà líìgì tó ń bọ̀?

Christiano Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibi ti ọrọ Christiano ronaldo de duro ni yii..

Eekan ẹlẹsẹ ayo agbaye ni, Cristiano Ronaldo to n gba bọọlu jẹun lẹgbẹ agbabọọlu Manchester United bayii nilẹ Gẹẹsi lawọn ololufẹ bọọlu lagbaye ti n jẹ ọrọ rẹ lẹnu pe boya yoo ko kuro lẹgbẹ agbabọọlu naa ti saa yii ba parii tabi yoo duro.

Ọrọ diduro Ronaldo atọpọ odu agbabọọlu ni ikọ Manchester United fun saa bọọlu to n bọ lọpọ awọn ololufẹ bọọlu paapaajulọ awọn ti Manchester United n jẹ lẹnu pẹlu ṣubudide ẹgbẹ agbabọọlu naa ni saa liigi Gẹẹsi to n kogba wọle bayii.

Iroyin lati awọn iwe iroyin kan ni ilẹ Gẹẹsi n sọ pe Cristiano Ronaldo ti yọọ sọ fun awọn akẹgbẹ rẹ kan pe oun yoo duro si Manchester United ni saa to n bọ bi o tilẹ jẹ pe ikọ naa ṣeeṣe ko kuna kikopa ni idije Yuroopu ni saa to n bọ.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Amọṣa, o ni iduro oun yoo da lori boya akọnimọọgba tuntun ti Manchester United ṣẹṣẹ gba ba fẹ oun ninu ikọ naa.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn manigbagbe agbabọọlu to ti wọ aṣọ manchester United ri, Dennis Beckham ti fi erongba rẹ han pe inu oun yoo dun bi Christiano Ronaldo ba lee duro pẹlu Amn United di saa to n bọ.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

"Cristiano Ronaldo ati leo (Lionel Messi) jẹọkan lara awọn agbabọọlu to lamilaaka julọ lagbaye lati nnkan bii ọdun marundinlogun sẹyin"

Beckham ni, "diduro rẹ lẹgbẹagbabọọlu United ṣe pataki fun awọn oloolufẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa. O ṣe pataki fun oun naa pẹlu nitori pe a mọ bi o ṣe nifẹ awọn ololufẹ ikọ Manchested United to."

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'