Pastor allegedly demand N310,000 from members: Ọlọ́pàá Ekiti fi ọ̀rọ̀ síta tó tàn 'mọ́lẹ̀ sí ẹ̀sùn Pásítọ tó fẹ́ gba N310K fi kó ọmọ ìjọ lọ s'ọ́run

Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lori ọ̀rọ̀ to kọkọ jọ bíi awuyewuye àmọ́ ti awọn ọlọrọ funrawon si ti sọ pe bẹẹ lo ri ti wọn si salaye fun BBC Yoruba, ọpọlọpọ lo ti n sọ oríṣiríṣi lori ayelujara lara eyi to jẹ wipe "o yẹ ki ijọba da sii".

Nibayii Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ náà tí dá sii. Wọn ni "ẹ má ṣe bẹru"!

Nínú atẹjade kan ti agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti fọwọ́ si to si fi sọwọ si awọn oniroyin, "Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti fẹ ki gbogbo araalu gbọ pé a ti ṣe iwadii Pásíto ìjọ Christ High Commission Ministry, Pasito Noah Abraham fun ẹ̀sùn pe o n gba owo lọwọ awọn ọmọ ìjọ rẹ pẹlu ileri pe oun yoo ko wọn lọ si ọrun lẹyin ti igbasoke ba sẹlẹ eyi ti o wa ninu Bíbélì amọ arákùnrin naa sọ pe ilu Araromi Ugbeshi-Ekiti ni yoo ti waye.

Bákan naa ni awọn Ọlọpaa ni ilaniloye ti awọn ń ṣe yii ṣe pataki lati dena awọn ọrọ àìgbọ́yé ti ko yẹ tabi fífi òfin mu ni lọ́nà aitọ.

"A fẹ ki araalu mọ pe iṣẹlẹ yii ko jẹ ajoji si wa pẹlu bi ariwo rẹ ṣe gba ilu kan, a si ti n gbe igbesẹ àti eto to yẹ".

Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

Latari itanilolobo to bọ si ọwọ awọn Ọlọpaa ni ọjọ Kẹẹdọgbọn oṣù Kẹrin ọdún 2022, ẹ̀ka Ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Omuo-Ekiti ni awọn dari ikọ agbofinro lọ si ibi ipagọ Ṣọọṣi naa ni Araromi Ugbeshi-Ekiti.

"Lẹyin rẹ la pe Pasito naa si agọ wá fun iwadii".

Sunday Abutu, alukoro Ọlọpaa Ekiti to fi ọrọ naa síta ni kete lẹyin iwadii ni wọn sọ ọrọ naa di ẹjọ́ ofin.

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀gá ni ooru Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ orílẹ̀èdè ti mo ti wálé; Bí mo ṣe parí iṣẹ́ 'AC' tó ń ló iná òòrùn rèé'

Àmọ́ ṣá, nigba ti BBC Yoruba lọ fi ọrọ wa Pasito naa lẹ́nu wo, inu ọgba ipagọ wọn la ti ba Pasito Noah Abraham àtàwọn ọmọ ìjọ rẹ.

Awọn eeyan to wa nibẹ pọ ti Pasito naa n ṣe àlàyé fun wa pe bukata pupọ lára wọn, ọrun òun lo wa.

Àkọlé fídíò, 'Gbogbo àgbáyé kódà America ló ń bọ̀ wá sí Omuo-Ekiti láti wá forí balẹ̀ ní Ààfin ńlá tí yóò sọ̀kalẹ̀ látọ̀run'

Eyi ṣeéṣe ko jẹ pe awọn Ọlọpaa pè é fun iforowanilenuwo ni Ileeṣẹ wọn àmọ́ wọn jẹ ki Pasito naa padà si ile rẹ.

Atẹjade Ọlọpaa naa eyi ti Abutu fọwọ́ si lórúkọ Komisona wọn wa sọ pe awọn ṣe ileri lati ṣe amojuto to sunmọra daadaa láti mọ boya iwa to tó furasi n ṣẹlẹ̀ láti ọwọ ẹnikẹ́ni tabi àkójọ àwọn èèyàn jakejado Ìpínlẹ̀ naa lati rii daju pe ẹ̀mí ati dúkìá awọn araalu wa ni ìpamọ́ dáadáa.

A kò mọ pásítọ̀ tó fẹ́ kó ọmọ ìjọ rẹ̀ lọ sí ọ̀run rí - CAN

Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi nipinlẹ Kaduna ti kede pe awọn ko mọ pasitọ Ade Abraham to ni oun yoo ko awọn ọmọ ijọ lọ si ọrun.

Ko mọ nibẹ, o ni ki wọn san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun le mẹwa Naira ki oun baa le ko wọn lọ.

Alaga ẹgbẹ Ajọ CAN nipinlẹ Kaduna, John Joseph Hayab lo kede bẹẹ.

Hayab ni bo tilẹ jẹpe iye ti pasitọ naa n gba lọwọ awọn ọmọ ijọ rẹ kere si eleyii ti awọn agbesunmọmi n gba lọwọ awọn to wa ni panpẹ wọn, to fi mọ awọn ajinigbe.

Ninu atẹjade ti CAN fi lede, wọn ni awọn ko tii ri ẹnikẹni to mọ ile ijọsin pasitọ naa tabi adirẹsi agbegbe, tabi ijọba ibilẹ to wa ni Kaduna.

''Pasitọ ti ko si ẹni to mọ ile tabi ọna rẹ yii le mu ki awọn eniyan tabuku ẹsin Kristẹni.''

''Nitori titi di asiko yii, ko si ẹni to mọ pasitọ Ade Abraham.''

Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

''A n rọ awọn eniyan to ba mọ wọn ni Kaduna lati jade, ki a le tọ ipasẹ iru pasitọ to fẹ ko awọn eniyan lọ si ọrun yii.''

O tẹsiwaju ninu atẹjade naa pe '' O ṣeeṣe ko jẹpe ki Ade Abraham to di onigbagbo lo ti kuro ni Kaduna abi ko wa ki eniyan ni Kaduna.''

''Bawo ni iru pasitọ naa a ṣe wa ni agbegbe kan ko ma si ẹnikẹni to mọ ọ to fi mọ awọn oniroyin?''

O ni nitori naa, Ijọ ọmọlẹyin Kristi ni Kaduna n rọ ẹnikẹni to ba mọ pasitọ naa ati ibi ti ijọ rẹ wa ni ipinlẹ Kaduna ko fi ṣọwọ si wọn.

Ajọ CAN nipinlẹ Kaduna gbagbọ wi pe eleyii le fa rugudu ni ipinlẹ naa lasiko ti eto aabo dẹnukọlẹ patapata ni awọn agbegbe kan. nipinle ọhun.

Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

Ọlọ́run mi ló ní kí n bèèrè fún N310,000 lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ mi láti kó wọn lọ sí ọ̀run - Pásítọ̀ Noah Abraham

Oniwaasu ajinrere kan ni Naijiria ti orukọ rẹ n jẹ Pasitọ Ade Abraham ti ko awọn ọmọ ijọ rẹ jọ si ipinlẹ Ekiti nibi to ti sọ fun wọn pe ẹnu ọna ibode si ọrun mbẹ ni ilu Araromi-Ugbeshi ni agbegbe Omuo-Ekiti ti o sí ṣe ibudó ipagọ sí.

Pasitọ Ade Abraham ni ọkan lára àwọn ọmọ ijọ rẹ ti fi ẹsun kan pe o gba ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́wàá náírà (310k) lọwọ wọn lati fi mu wọn lọ si ijọba ọrun títún.

Iroyin kan sí ti gba gbogbo aye kan pe Pasito ti kọ ibudó tuntun kan ni ipinlẹ Ekiti nibiti o ti sọ pe ẹnu-ọna ọrun wa nibẹ.

Amọṣa, BBC ko le fi idi ọrọ yii mulẹ pe ootọ ni eeyan kan le ko awọn eeyan gba oju ọna kan lọ si ọrun.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

BBC Yoruba gbera lati lọ wo boya lootọ ni Pasitọ naa kọ ipagọ kan si Ekiti taa si rii pe lootọ ni wọn n ṣe ipejọpọ tabi isin nibẹ.

Ọkan lara awọn ọmọ ijọ naa ti Pasitọ Noah Abraham ko jọ sí ibùdó ipagọ to fẹ pada lọ si ile rẹ pẹlu iyawo ati awọn ọmọ rẹ meji, ṣugbon ti iyawo rẹ kọ gidigidi lati pada lọ si ilè wọn ní Kaduna ti o sí sọ pe igbasoke nbọ laipẹ fi ẹjọ tó àjọ ọlọpa leti pe kí won gba oun o.

Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

Ìkọ iroyin BBC News Yoruba gbera lo sí ilu Araromi-Ugbeshi ni agbegbe Omuo-Ekiti lati fi oju ri gbogbo nkan se ri, ti a sì bá pasitọ Abraham ni gbólóhùn.

Nibo gan ni ṣọọṣi Pasitọ̀ Noa Abraham wa?

Ijọ Pasitọ Abraham bẹrẹ ni ilu Kaba ni ipinle Kogi ti o sí tẹsiwaju ni ipinlẹ Kaduna lẹyin opolopo awuyewuye pẹlu awọn ara ilu naa ki o to pada fi àbọ sí ilu rẹ ni ilu Araromi-Ugbeshi ni agbegbe Omuo-Ekiti.

Pasitọ Abraham ni ajihinrere Òjíṣẹ Ọlọrun tí o ma nlọ kaakiri ni oun, ti isẹ iransẹ oun sì má n ran ọpọ eniyan ati ìdílé lọwọ ni ọna kan abi omiran.

Pasitọ Abraham ati ọmọ ijọ

Ootọ ni mo sọ fun awọn ọmọ ijọ mi pe ki wọn san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun o le mẹwaa naira

Pasitọ Abraham sọ fun ìkọ iroyin BBC News Yoruba pe lootọ ni oun sọ fún àwọn ọmọ ijọ pe kí wọn san owo N310,000.

"Nigbati wahala wọn pọ pe wọn fẹ wa sí ipagọ ọlọdọọdun ti a ma n ṣe ti mo sì ni àṣẹ Ọlọrun tí o pe mi ni lati fi ṣe ìdánrawò fún gbogbo àwọn tí o fẹ sìn Oluwa tọkàntọkàn".

Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

Olùdásílẹ̀ ijọ naa tun fi idi rẹ mu'lẹ pe oun ko tii gbà owo kankan lọwọ ọmọ ijọ kankan ti àjọ ileeṣe ọlọpa ipinle Ekiti sí ti dá sí ọrọ naa.

"Ajọ Ọlọpa ti wa síbí lati ri nkan ti o nsẹlẹ, Ọga Ọlopa agba ipinlẹ Ekiti ti pe mi fún iwadi àti gbogbo àwọn ọmọ ijọ ti wọn ba nigbati wọn wa, ti gbogbo wọn sí ti kọwe silẹ lọdọ wọn fún iwadi òtítọ".

Pasitọ Ade Abraham tun fi idi rẹ mu'lẹ pe ibudó tuntun kan ti oun wa yi ni ipinlẹ Ekiti ni ibi ti ẹnu-ọna ọrun wa ti ọlọrun sì fi sọ fun oun bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere
Pasitọ Noah ní ọgba ipagọ Ekiti

Ikọ BBC News Yoruba tun ba arabinrin ti ọkọ rẹ ti tori tiẹ lọ fi ẹjọ sun Ọlọpa pe kini idi ti ko fi tẹle ọkọ rẹ pada si Kaduna nigbati o ni ilọ yaa ti arabinrin na sì fi ye wa pe ìpinnu ọkọ òun ṣe ajoji sí oun torípé ko jọ tipatikuuku ni ọkọ fi mú òun darapọ mọ ìjọ Pasito Abraham leyin ọdún kan toun fariga.

Arabinrin naa ni àìmọye igba ni oun fi pe ọkọ rẹ ati ẹbẹ pe kini idi ipinnu òjìji rẹ pe Kaduna ya ti ko sí ni alaye kankan ṣe fún ohun.

O sọ fun BBC Yoruba pe oun naa sì ti pinnu pé ti ọkọ òun o ba sọ ohun tó n sẹlẹ fún òun, oun yíò ba wọn pari ipagọ náà ni kí oun to pada ti ipinle Kaduna. O tun fi ye wa pe ojojumọ ni oun ati ọkọ òun má n sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ.

Pasitọ Abraham ati ọmọ ijọ

Alukoro awọn Ọlọpa ni ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu fi idi ọro náà múlẹ pe iwadii n'lọ lọwọ lori ẹsun naa.