Adisa Olashile and Adeniji Ayangbenle: BBC bá bàbá onílù tí àgùnbánirọ̀ dá lọ́lá sọ̀rọ̀

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Ṣe ẹ ranti Baba Onilu Ibadan ti ọdọkunrin agunbanirọ ya fọto rẹ to si ta a lori ayelujara fi pa miliọnu kan naira?

BBC Yoruba ti wa àti baba onilu ati agunbanirọ naa kan lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.

Baba Onilu

Baba naa, Adeniji Ayangbenle jẹ agbalagba to maa n lọ kaakiri ibi inawo tabi apejọpọ lati lu ilu fi gba owo.

Agunbanirọ naa, Adisa Olashile ni awọn n ṣe iṣẹ ilu lọwọ gẹgẹ bi agunbanirọ tawọn si ṣẹ pari ni baba wa lu ilu fun awọn.

Baba Onilu

"Ọrẹ mi fun baba ni N100 amọ emi o ni owo ti mo le fun wọn, mo wa fi anfani pe ọrẹ mi ti fun baba ni ọgọrun naira, mo fi ya fọto baba".

Bi ọrọ fọto lasan ti baba ro pe Adisa ni ki oun rẹrin niwaju igi elewe ṣe di eyi to sọ baba di oloriire niyẹn.

Agunbanirọ Adisa

Adisa sọ fun baba pe oun yoo pada wa o si ṣe bẹẹ. O ri anfani lati ta fọto naa lorii aapu ori ayelujara kan ti wọn n pe ni Open Sea gẹgẹ bi ẹda aworan NFT eyi to tumọ si iṣẹ ọna to dara.

Baba Ayangbenle sọ pe ojoojumọ ni oun maa n ṣe adura fun ọmọ Agunbanirọ to mu inu oun dun.