Amotekun àti iléeṣẹ́ ọmọ ogun fi ṣìkùn òfin mú afurasí 37 l'Ondo

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Inside9jadaily

Ikọ Amotekun ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu awọn afurasi mẹtadinlogoji lori oniruru ẹsun kaakiri ipinlẹ naa.

Igbesẹ ọhun lo waye ni ifọwọsowọpoọ pẹlu ẹka ileeṣẹ ọmọ ogun 32 Artillery Brigade niluu Akure.

Eto naa, ti wọn bẹrẹ lawọn ọjọ diẹ sẹyin ni wọn sọ pe o wa fun fifọ ipinlẹ Ondo mọ lọwọ awọn kọlọrọsi ẹda to n da omi alaafia ipinlẹ naa ru.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá

Adari ikọ Amotekun l'Ondo, Adetunji Adeleye lo fi oju awọn afurasi naa lede.

Lasiko to n fi oju wọn lede, to si n jabọ isẹ naa fun awọn akọroyin nilu Akure, Adeleye sọ pe wọn fi ṣikun mu awọn eeyan naa lori oniruru ẹsun bii ijinigbe, idigunjle, lilu jibiti ori ayelujara, titapa si ofin to tako fifi ẹran jẹko laarin igboro, atawọn ẹsun mii.

O ni ikọ Amotekun, ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ileeṣẹ eto abo mii l'Ondo ti pinnnu lati ri daju pe awọn ọdaran ko ni ibuba ni ipinlẹ ọhun.

Adeleye sọ pe Amotekun n ri atilẹyin ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ọmọ ogun, ajọ NSCDC ati DSS ni gbogbo igba.

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso

Ko si ẹnikẹni lakata awọn ajinigbe mọ

O tẹsiwaju pe ọwọ awọn tẹ ẹgbẹ awọn ajinigbe kan to n ṣọṣẹ lẹba ala ipinlẹ naa.

O ni "Lẹyin ogun ti a gbe ti awọn ajijinigbe naa, wọn jọwọ awọn ti ji gbe silẹ, bayii, ko si ẹnikẹni ni akata awọn ajinigbe mọ nipinlẹ Ondo."

"Fun ẹyin agbẹ, a fẹ ki ẹ pada sinu oko yin bayii, a si fi da yin loju pe abo to peye yoo wa fun yin ninu oko yin."

Àkọlé fídíò, Èmi nìkan ni ikú Alaafin dùn jù ní gbogbo ayé yìí torí èmi nìkàn ṣoṣo ni mo mọ̀ ǹkan ... - Baba Kekere

Adeleye pari ọrọ rẹ pe ko si wahala kankan laarin ikọ Amotekun ati ileeṣẹ ọmọ ogun ni ipinlẹ naa nitori ajọṣẹpọ to dan mọran lo wa laarin awọn mejeji.

Ọjọ Ẹti to kọja ni Amotekun ati ileeṣẹ ọmọ ogun bẹrẹ eto oni wakati mẹrinlelogun lati gbogun ti iwa ọdaran ṣaaju ati lẹyin ọdun Itunu Awẹ.

Lasiko eto naa ni wọn kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun ipinlẹ Ondo lati fọ ipinlẹ naa mọ.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua