Antonio Guterres visit Nigeria: Bí àbẹ̀wò sí Naijiria rè yóò ṣe lọ nìyíi

Aworan akọwe agba UN

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akọwe Ajọ Iṣọkan Agbaye, Antonio Guterres yoo ṣabẹwo si orilẹede Naijiria fun Ọjọ meje bẹrẹ lati Ọjọ Iṣẹgun.

Eyi ni igba ikẹta ti Ọga agba iṣọkan agbaye yio ṣabẹwo si iha Guusu Ilẹ Afrika, igba akọkọ si ni yii ti yoo wa si ilẹ Naijiria.

O wa si Naijiria ni asiko ti ohun gbogbo ko lọ deedee lorilẹede Naijiria paapaa eto oṣelu ati ni agbaye,ogun to n ṣẹlẹ ni Ukraine .

Lasiko abẹwo rẹ si Naijiria, yoo ṣe ipade pẹlu Aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osinbajo.

Bakan naa ni yoo ṣe ipade pẹlu awọn adari ẹsin, awọn obinrin ,awọn olori ọdọ ati awọn olori oṣiṣẹ iṣẹ adani .

Guterres yoo ṣabẹwo si gomina ipinlẹ Borno, Babangana Zulum,ni olu ilu ipinlẹ naa ni Maiduguri.

Nibẹ ni yoo ti ṣabẹwo si awọn mọlẹbi awọn eyan ti ikọ Boko Haram ti ṣe akọlu si nibẹ.

Akọwe Ajọ Iṣọkan Agbaye yoo tun sabẹwo si awọn agbegbe ti oju ọjọ ti ko ṣe deedee ti ṣakoba fun.

Nkan ti o yẹ ki ẹ mọ nipa Akọwe Ajọ Iṣọkan Agbaye si Naijiria?

Ipaya ti ohun ṣẹlẹ ni agbaye nitori ogun ilẹ Ukraine ati Russia. Ogun naa ti fa adinku ohun elo 'hydrocarbon' ati ọwọngogo epo (wheat) ni awọn orilẹede kan ni Ilẹ Afrika.

Ipaya ti o de ba awọn eniyan ni ki ọwọngogo ounjẹ ati iyan mase bẹ silẹ.

Antonio Guterres ninu ọrọ rẹ¸ni 'ogun ti ohun ṣẹlẹ ni Ukraine ti fa ọwọngogo ounjẹ,ina ati owo.'

Bakanna ni Ọga Ajọ UN naa yoo ṣabẹwo si ilẹ Senegal lati ṣe atuntọ iwe ofin ilẹ wọn.

Orilẹede mẹta ni ilẹ Afrika ni awọn ologun ti gbajọba.

Bakanna ni Naijiria,Chad,Niger ati Cameroon ni awọn agbebọn ati agbesunmọmi ti ṣọṣẹ, ti wọn si ti pa ọpọlọpọ awọn eniyan nibẹ.

Ọmọ orilẹede Naijiria,Aminat Ahmed ni igbakeji ọga patapata fun Antonio Guterres ni olu ileeṣẹ wọn ni New York, ni orilẹede Amẹrika.