Russia-Ukraine War: Ohun tí a fẹ́ ṣe láti dènà ìyàn oúnjẹ ní Naijiria rè é

Oríṣun àwòrán, others
Bí a ṣe fẹ́ dènà ìyàn oúnjẹ ní Naijiria rè é - Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti gboriyin fun Ileeṣẹ Banki Apapọ Ilẹ Afrika, Africa Development Bank (AfDB) fun akitiyan wọn lati koju iyan ounjẹ latari ogun to n lọ lọwọ laarin orilẹede Ukraine ati Russia.
Buhari sọ eyi lasiko ti Aarẹ Banki AFDB, Akinwunmi Adesina ṣe abẹwo si lati ṣalaye igbesẹ ti wọn n gbe lati koju iyan ounjẹ to ṣẹṣẹ ko bẹ silẹ kaakiri ilẹ adunlawọ nitori ija to n waye ni Ukraine.
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
- NDLEA sàmì sí ilé Abba Kyari mẹ́fà àti ilé ìtàjà tó ní ṣọ́ọ̀bù 100 ní Maiduguri fún ìwádìí
- Lukman gbẹ̀yín ẹbí lọ bẹ́ orí ìkókó ti wọ́n sìn ní Abeokuta, àṣírí tú bó ṣe fẹ́ tàá
- Èsì àyẹ̀wò ohun tó ṣekú pa gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu ti jáde
- 'Ètò ayẹ́yẹ́ ìsìnkú Oba Lamidi Adeyemi kòí tíì wáyé, àfọ̀mọ́ Aàfin ń lọ lọ́wọ́'
- Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo
- Èèyàn bí méjì kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò tí àwọn afurasí ọmọ Auxiliary àti Isota kọlu ara wọn ní Ibadan
Kini Akinwumi Adesina sọ lori ọrọ ounje yii?
Adesina ni ogun Russia ati Ukraine yoo da wahala silẹ ni agbaye paapaa ni Afrika nitori awọn orilẹede yii ni wọn ti n ko ounjẹ wọle si Naijiria.
'Lọwọlọwọ bayii iye ti wọn n ta epo(wheat) ti lọ si oke ju ti tẹlẹ lọ, to fi mọ ọwọngogo agbado ati awọn ounjẹ miran.
Ipa wo ni Ajilẹ a ko ninu eto yii?
'O ṣeeṣe ki eroja nkan ọgbin bi fertilizer wọngogo, eleyii ti yoo ṣe akoba fun iye ti wọn n ta ounjẹ.''
'Ilẹ Afrika yoo padanu biliọnu mọkanla dọla ni iwọn ounjẹ lasiko yii ti a ko ba tete wa nkan ṣe si.''
'Eleyii si lewu pupọ lasiko ti awọn eniyan ṣẹṣẹ jajabọ ninu arun Coronavirus to gba gbogbo agbaye kan.''
Akinwunmi ni ohun ti awọn ṣe lati dena ọwọngogo ounjẹ ati iyan ni lati pese biliọnu kan o le dola fun ipese ounjẹ pajawiri ni ilẹ Afrika.
O ni owo yii yoo pese epo, agbado, irẹsi, Sorgum ati Soya fun awọn agbẹ lati koju ọwọngogo naa.
'O kere tan awọn agbẹ ni Naijiria to to miliọnu marun un ni wọn yoo ran lọwọ lati da oko agbado, irẹsi ati bẹẹ bẹẹ lọ''
''Eyi yoo fun Naijiria ni anfaani lati pese ounje lopo yanturu paapaa ni awon ipinle bii Kano, Ogun, Oyo, Kaduna, Imo, Cross River ati Abuja.
Kini Aare Buhari fi pari ọrọ rẹ?
Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Buhari dupẹ lọwọ Banki apapọ ilẹ Afrika naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati doola ẹmi awọn eniyan nitori iyan ati ẹbi.
Buhari ni awọn mọ riri ounjẹ fun awọn araalu ni awọn ṣe ti gbogbo ibode ki ayederu ounjẹ ye wọ Naijiria, eleyii ti awọn si ri ṣe daradara.
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà

















