Abba Kyari: NDLEA sàmì sí ilé Abba Kyari mẹ́fà àti ilé ìtàjà tó ní ṣọ́ọ̀bù 100 ní Maiduguri fún ìwádìí

Oríṣun àwòrán, @Abba Kyari
Iléẹjọ́ ti sún ìdájọ́ Ọ̀gá Ọlọ́pàá Abba Kyari si iwaju
Oṣù Kẹfà ni Abba Kyari yóò gba ìdájọ́ lórí ẹ̀sun gbájuẹ̀
Ijọba Ilẹ Amerika fi ẹsun kan an pe alabaṣiṣẹ Abbas Ramon, Hushpuppi ti wọn fi ẹsun alọnilọwọgba ati iwa jibiti kan ni.
- Ohun tó yẹ kó mọ nípa ìyípadà òfin tó dé ijinigbe ní Nàìjíríà rèé
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Ajé àti ọjọ́ Ìṣẹ́gun fún ìsinmi ọdún àti àyájọ́ ọjọ́ Òṣìṣẹ́
- Indonesia fòfin de títa epo pupa rẹ̀ sílẹ̀ òkèèrè, wo ipa tí yóò ní lára Naijiria àti Africa lápapọ̀
- Mo ti 'ùnfollow' ẹ lórí 'social media'; Ọlọ́run a ṣe idajọ fún ẹyin méjèèjì- Iyawo Yul-Edochie
- Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló kú ikú àìtọ́jọ́ nítorí ẹnubodè tíjọba àpapọ̀ tì pa- Àwọn ènìyàn ìlú Idiroko tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀
- Ìgbẹ́jọ́ Ilànà Ọmọ oodua àti Náìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Ekiti
- Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Morenikeji Lasisi, olórí ẹrú tó ti bá Aláàfin mẹ́ta ṣiṣẹ́
- Ìj̀à tó bẹ́ sílẹ̀ ní Sudan ti gbẹ̀mí ènìyàn 200 lára àwọn tó sá àsálà fún ẹ̀mí wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Janjaweed
Ileẹjọ giga ti sun igbejọ Abba Kyari di Ọjọ Keji, Oṣu Kẹfa, ọdun yii lori ẹsun gbajuẹ ti wọn fi kan an lati orilẹede Amẹrika.
Ileẹjọ yoo sọ boya Kyari le lọ jẹ ẹjọ ni Amerika gẹgẹ bi aṣẹ ti ẹka idajọ ni orilẹede ọhun beere lọwọ Naijiria.
Adajọ ileẹjọ giga naa, Inyang Ekwo ni oun sun igbẹjọ naa lati fi aye silẹ fun agbẹjọro ti ijọba lati tun ile re to lọna ati mu itẹsiwaju ba igbẹjọ naa.
Kyari ti wọn ni ko lọ rọkun nile fun igba diẹ ni igbakeji kọmisọnna ọlọpaa ni Naijiria ati Ọga Agba Ọlọpaa to n risi ikọ ọtẹlẹmuyẹ.
Ẹsun wo ni wọn fi kan Abba Kyari?
Ijọba Ilẹ Amẹrika fi ẹsun kan an pe alabaṣiṣẹ Abbas Ramon, Hushpuppi ti wọn fi ẹsun alọnilọwọgba ati iwa jibiti kan ni.
Olotu ijọba ati minisita fun eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami ni ijọba ilẹ Amẹrika n bere ki wọn yọnda Kyari fun wọn ni ọrọ naa ṣe de ile ẹjọ.
Amọ, agbẹjọro Kyari, Nuremi Jimoh ni wọn ko tii fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si oun ki gbogbo eto le to.
Bakan naa ni igbẹjọ ko le e tẹsiwaju nitori awọn agbẹjọro naa ko le e fi gbogbo iwe igbẹjọ to yẹ lede, eleyii to mu u sun si iwaju di Ọjọ Keji, Oṣu Kẹfa, ọdun 2022.
NDLEA sàmì sí ilé Abba Kyari mẹ́fà àti ilé ìtàjà tó ní ṣọ́ọ̀bù 100 ní Maiduguri fún ìwádìí
NDLEA bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ilé Abba Kyari mẹ́fà àti ilé ìtàjà tó ní ṣọ́ọ̀bù 100 ní Maiduguri.
Ajọ to n gbogun ti tita ati lilo egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti sami si awọn dukia kan to jẹ ti ọga ọlọpaa tẹlẹ, Abba Kyari.
Lara awọn dukia naa ni ileegbe mẹfa, ati ile itaja nla kan niluu Maiduguri wa.
Ile itaja nla naa to jẹ alaja meji, Asurance Plaza, to wa loju ọna ileegbe Giwa Barracks, lo ni ṣọọbu bii ọgọrun un.
- Adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó gbé Abba Kyari lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ní Abuja
- Ẹ dákun ẹ má kó wa lọ sẹ́wọ̀n! - Abba Kyari
- Kíni àwọn ojúṣe olórí àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ̀ Nàìjíríà?
- Ta ni Tunji Disu ti wọ́n kéde láti rọ́pò Abba Kyari?
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
- FBI àti ìjọba Amẹ́ríkà tẹ ẹ̀tọ́ Nàíjíríà lójú lórí ẹ̀sún tó fi kan Abba Kyari
- Ọwọ́ FBI yóò tẹ Abba Kyari, òǹyẹ̀ kankan kò lè yẹ̀ ẹ́ - Femi Falana
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá, ẹ ríi dájú pé ẹ tú gbogbo àṣírí nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Abba Kyari àti Hushpuppi - Àpapọ̀ Agbẹjọ́rọ̀
- Wo ohun méjé tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abba Kyari, ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn
Yati si eyii, NDLEA tun sami si awọn ileegbe mẹfa mii to wa ni New GRA, eyi ti wọn ni o jẹ ti Kyari.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ọjọ meji ti ọwọ NDLEA tẹ baba olowo ti wọn fẹsun kan pe oun lo ni oogun Tramadol ti iye rẹ to biliọnu mẹtala naira ti ikọ Kyari gbẹsẹle ṣaaju.
Ọjọ oṣù kejì, ọdún 2022 ni NDLEA ti nawọ́ gán Abba Kyari lẹ́yìn tí wọ́n kéde rẹ̀ bí ẹni tí wọ́n ń wá fun ẹsun pé ó lọ́wọ́ nínú gbígbé egbòogi olóró wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti orílẹ̀ èdè Brazil àti Singapore.
Láti ìgbà náà ni Kyari ti ń kojú ẹ̀sùn lílọ́wọ́ nínú gbígbé egbògi olóró wọ orílẹ̀ èdè yìí tó sì ti ń jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́.
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
- NDLEA sàmì sí ilé Abba Kyari mẹ́fà àti ilé ìtàjà tó ní ṣọ́ọ̀bù 100 ní Maiduguri fún ìwádìí
- Lukman gbẹ̀yín ẹbí lọ bẹ́ orí ìkókó ti wọ́n sìn ní Abeokuta, àṣírí tú bó ṣe fẹ́ tàá
- Èsì àyẹ̀wò ohun tó ṣekú pa gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí, Osinachi Nwachukwu ti jáde
- 'Ètò ayẹ́yẹ́ ìsìnkú Oba Lamidi Adeyemi kòí tíì wáyé, àfọ̀mọ́ Aàfin ń lọ lọ́wọ́'
- Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo
- Èèyàn bí méjì kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò tí àwọn afurasí ọmọ Auxiliary àti Isota kọlu ara wọn ní Ibadan
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abba Kyari ní òun kò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun, ilé ẹjọ́ kọ̀ láti fún-un ní ìdáǹdè.
Kyari jẹ ogboju ọdẹ ninu igbo irunmọlẹ laarin awọn akẹgbẹ rẹ, o si ti gba oniruru ami ẹyẹ fun iṣẹ takun-takun rẹ nidi iṣẹ ọlọpaa ki aṣiri awọn ohun to ṣe ni ikọ to tu si gbangba.















