Indonesia ban export of palm oil: Ọ̀nà wo ni ìgbésẹ̀ yìí yóò fi ni ipa lára Naijiria àti Africa lápapọ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹ-ede Indonesia ti fi ofin de tita epo pupa lọ si awọn orilẹ-ede miran.
Indonesia, to wa ni Gusu Asia, lo n pese ìpín to ju ilaji lọ ninu gbogbo epo pupa ti wọn n lo ni agbaye.
Nkan to fa igbesẹ tuntun yii ko ṣẹyin bi awọn ọmọ orilẹ-ede Indonesia ṣe bẹrẹ iwọde tako bi owo epo pupa ṣe wọn lọdọ wọn.
Ọwọ gogo naa n waye nitori bi awọn olokoowo ṣe n ko eyi to pọ ninu epo naa lọ si awọn orilẹ-ede miran.
Ibeere to gba ọkan gbogbo eeyan ni pe, nibo ni ilẹ Africa, to n ra epo pupa ju, yoo ti ma a ri epo ra bayii?
- Àwọn ènìyàn Nàìjíríà fi ìdùnnú hàn bí ìjọba ṣe ṣí àwọn ibodè mẹ́rin mìíràn
- Bí o bá san owó fún ìtúsílẹ̀ ẹnikẹ́ni láhámọ́ ajínigbé, ẹ̀wọ̀n ọdún 15 wà níkàlẹ̀ fún ọ
- Àwọn ológun pa ikọ̀ Boko Haram ogún, wọ́n dóòlà àwọn obìnrin tó wà ní ìgbèkùn
- Óṣe! Àwọn ọmọdé mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí wọn bí wáyà iná ṣe já lé wọn lórí
- Mo ti 'ùnfollow' ẹ lórí 'social media'; Ọlọ́run a ṣe idajọ fún ẹyin méjèèjì- Iyawo Yul-Edochie
- Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló kú ikú àìtọ́jọ́ nítorí ẹnubodè tíjọba àpapọ̀ tì pa- Àwọn ènìyàn ìlú Idiroko tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀
- Germany gbé ìgbésẹ̀ láti fi ọkọ̀ ogun sọwọ́ sí Ukraine láti kojú Russia
Lọdun 2021 nikan, biliọnu marun-un Dọla ni Africa na lati ra 'metric tonnes' epo pupa, lati Indonesia ati Malaysia.
Nilu Kuala Lumpur, olu ilu Malaysia, $1,850, ni wọn n ta toonu epo kan.
Laarin $150 si $200 si ni wọn fi n gbe tọọnu kan.
Eyi tumọ si pe bi ẹgbẹrun meji Dọla ni tọnu epo kan n ba de Africa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣe na abayọ wa fun awọn orilẹ-ede to n ra epo ju lati ilẹ okeere?
Fun awọn orilẹ-ede bi India, Bangladesh ati Pakistan, o ṣe e ṣe ki wọn o bẹrẹ si ra epo pupa wọn ni Malaysia.
Ṣugbọn ko daju pe Malaysia to jẹ oril-ede keji to n ta epo pupa ju l'agbaye, ma le pese gbogbo nkan ti wọn n fẹ, nitori ọwọn oṣiṣẹ.
Indonesia lo n pese bi ilaji epo pupa ti wọn n lo ni India.
Ti Pakistan ati Bangladesh si n ra bi ida ọgọrin ti wọn lati Indonesia.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Anfaani nla ni bi Indonesia ṣe fi ofin de tita epo silẹ okeere jẹ fun Africa
Connie Magomu, to jẹ oludari ajọ to n mojuto ipese epo pupa ni Uganda, sọ pe ilẹkun anfaani nla lo ṣi, bi Indonesia ṣe ṣe ofin tuntun.
Magomu sọ pe o jẹ anfaani fun awọn orilẹ-ede ni Africa, lati mu idagbasoke ba ẹka ọrọ aje epo pupa wọn.
O ni "nkan ọgbin to ma n din ìṣẹ́ kù ni epo pupa, nitori pe igi ọpẹ kan ṣoṣo ma n pese epo fun ogun ọdun si ọdun mẹẹdọgbọn".
Igbesẹ ti Indosia gbe yii ṣe e ṣe ko mu ki oju ṣi si Naijiria
- 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'
- Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
- Ìgbẹ́jọ́ Ilànà Ọmọ oodua àti Náìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Ekiti
- 'Ẹran ẹtu ni mo yìnbọn sí, àmọ́ òkú ìmáàmù ni mo bá nígbà tí mo fẹ́ gbe e'
- Ẹ yé fi ìpapòdà àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo kọmi lọ́rùn - Gómìnà Seyi Makinde
- "Kòríkòsùn lèmi àti Alaafin ṣùgbọ́n kété táwọn kan kẹ́ẹ́fín pé èmi láàyò ni gbogbo nǹkan dojúrú." Badirat Ajoke, olorì tẹ́lẹ̀ kẹ́dùn Alaafin
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn
- Mo ti gbà báyìí pé ohun gbogbo tó n dán kọ́ ni wúrà - Olori Badirat Adeyemi
- Ìjọba àpapọ̀ ṣí ẹnubodè Idiroko àti àwọn mẹ́ta mìíràn, wo ohun tí BBC bá bọ̀ níbẹ̀
Naijiria ni olupese epo pupa julọ ni Africa lọwọlọwọ, oun si ni l'agbaye ṣaaju ọdun 1970.
Bayii, o ṣe e ṣe ki owo awọn nkan elo ti wọn n fi epo pupa ṣe bii ororo, ọṣẹ, ipara, bọta ati awọn nkan jijẹ ati aṣaraloge miran, ko wọn si.
Uganda ti n mu idagbasoke ba ẹka epo pupa rẹ diẹdiẹ, ṣugbọn o ṣi nilo ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeka ilẹ, ko to o le pọ yanturu.
Awọn orilẹ-ede Africa mii ti anfaani tuntun yii le mu idagbasoke ba ni Naijiria, Ghana, Ivory Coast, Sierra Leone, Uganda, Burundi, DRC Congo ati Tanzania.


















