Palm Oil production: Wo ìdílé tí ìyá àti gbogbo ọmọ kara bọ iṣẹ́ ṣíṣe epo tà

Àkọlé fídíò, Wo ìdílé tí ìyá àti gbogbo ọmọ kara bọ iṣẹ́ ṣíṣe epo tà

Epo pupa wa lara awọn nkan gboogi ti wọn maa n lo fi ṣe o fẹrẹẹ to idaji gbogbo nkan tawọn eeyan ma lọ n ra lawọn ile itaja nla nla kaakiri agbaye gẹgẹ bi ajọ kan to n polongo lori ọrọ ayika ṣe sọ ọ.

Bakan naa ni Naijiria, ko sẹni to lee fọwọ rọ sẹyin ninu ohun gbogbo to ni ṣe plu ounjẹ ti wọn si tun maa n lo fun ohun ile bii ọṣẹ.

Lonii, ọpọlọpọ idile lo jẹ pe ọna ti wọn fi n bọ ara wọn lati ri jẹ ri mu ni ṣiṣe epo ta.

Idile Ogbona n jẹ iṣu ati epo

Fun Ezinma Ogbona ati idile rẹ, ọdun ti pẹ ti wọn ti n ṣe eyi atohun atawọn ọmọ rẹ ni wọn si kara bọ ọ. Wọn ti pin bi wọn ṣe n ṣe e. Ọdọmọkunrin ni yoo gun igi ọpẹ lọ lati lọ maa fi ada ge idi ẹyin silẹ.

Awọn obinrin ni yoo ko o lọ ile lati yọ ẹyin kuro lara idi.

Agbẹ to n gbin ẹgẹ to si n ṣe epo pupa ni arabinrin yii jẹ, isẹ yii lo si n ṣe to fi n ran idile rẹ lọwọ lati san owo ileewe awọn ọmọ.

Bi oun ati awọn ọmọ rẹ ṣe n pawọpọ ṣe iṣẹ epo pupa yii jẹ iwuri gidi gan.