Lóòtọ́ la mú ọkùnrin kan pẹ̀lú agbárí èèyan, ṣùgbọ́n kìí ṣe pásítọ̀-Ọlọ́pàá Ondo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ṣalaye wi pe lootọ ni ọwọ awọn tẹ arakunrin kan pẹlu agbari eniyan ati apa meji ni ikawọ rẹ.
Iroyin kan n ja rayinranyin lori ayelujara pe pasitọ kan ti bọ si panpẹ awọn ọlọpaa nigba ti wọn muu pẹlu ika ọwọ mẹtadinlogun ati oniruuru ẹya ara eniyan miran l'agbegbe Alagbaka ni ilu Akurẹ.
- Ọmọ Italy tó kọ́kọ́ kó Coronavirus wọ Eko tún lọ́ sí ìpínlẹ̀ Ogun nàá
- Ó yẹ kí o mọ̀ nípa ọ̀nà láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ Coronavirus
- ''Kazeem ṣèlérí pé oun máa mú mi lọ ìlú òyìnbó k'àwọn SARS tó pá á''
- Ambode m'òfo nílé ẹjọ́ lóríi pé k'áwọn aṣòfin yéé tojú bọ ọ̀rọ̀ ọkọ̀ bọ́ọ̀sì 820 tó rà
- Sagamu: Ìkọlù wáyé bí ará ìlú ṣe gbéná wòjú ọlọ́pàá torí ikú agbábọ́ọ̀lù
Iroyin naa fi kun pe awọn ọlọpaa ikọ SARS kan tun kọlu agbabọọẹu kan nibẹ, ati pe pasitọ ni ọkunrin ti wọn ba ẹya ara eniyan lọwọ rẹ.
Ṣugbọn nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Fẹmi Joseph ṣalaye pe irọ funfun balau ni iroyin naa ati pe ko si igba kankan ti awọn ọlọpaa ni ipinlẹ naa mu pasitọ kankan pẹlu ẹya ara eniyan.
O ni ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ naa tẹ arakunrin, ẹni aadọta ọdun kan ni owurọ oni ni ilu Idoani pẹlu agbari eeyan kan ati apa meji ti wọn ti dana sun guruguru.
Ọgbẹni Joseph tun sọ pe afunrasi naa ṣalaye pe ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Alhassan lo ran oun, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti mu awọn mejeeji bayii.
O wa rọ awọn araalu lati jinna sawọn to n gbe iroyin ofege to lee da họwuhọwu silẹ lawujọ.









