Coronavirus in Nigeria: Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọ̀nà láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ Coronavirus

An oṣiṣẹ eto ilera

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarun Coronavirus ti wọ orilẹede Naijiria bayii, eyi kii sii ṣe iroyin tuntun mọ bayii.

Amọ, bi ọrọ ti ṣe jẹ bayii, awọn ọna wo ni o lee fi daabo bo ara rẹ lọwọ arun yii.

Gẹgẹ bi atẹjade ajọ ilera agbaye, WHO, lootọ orilẹ€de China ni arun yii ti gbera ṣugbọn awọn orilẹede to ti ran de ti pọ, leyi ti orilẹede Naijiria naa si ti wa darapọ mọ wọn bayii.

Pupọ awọn to ba kọlu aarun yii maa n ni ailera diẹ, wọn o si tun pada bọ sipo ilera wọn pada, ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ri fun fun awọn miran.

Eyi ni ọna ti o lee gba daabo bo ara rẹ atawọn miran lọwọ arun Coronavirus:

Maa fọ ọwọ rẹ loorekoore pẹlu ọṣẹ ati omi to mọ gaara:

awọn ọmọde kan n fọ ọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Rii daju pe o n fọ ọwọ rẹ loorekoore pẹlu ọṣẹ ifọwọ ati omi to mọ.

Ki ni idi? Fifọ ọwọ rẹ pẹlu ọṣẹ ati omi mimọ yoo pa awọn kokoro arun to n gbe ni ọwọ rẹ.

Yago fun awọn to ba n wukọ tabi sin

Obinrin kan bo imu rẹ lati daabo bo ara rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Rii daju pe o rin jina fun bi iwọ ẹsẹ bata mẹta si ẹnikẹni ti o ba kẹẹfin pe o n wukọ tabi ṣe ọfinkin.

Ki ni idi? Bi eniyan ba n wuks tabi sin, iwọn omi diẹ to ba n jade ni imu tabi ẹnu wọn lee ni koko arun yii. Bi o ba wa sunmọ wọn ju bi o ti yẹ lọ, iwọ naa lee koo simu pẹlu kokoro arun yii bi o ba jẹ pe onitọun ni kokoro arun COVID-19.

Ṣọra fun fifi ọwọ kan oju, imu ati ẹnu rẹ

oṣiṣẹ ilera n ṣe ayẹwo fun obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọwọ rẹ ti o ti fi kan oniruuru nnkan lee ti kan kokoro arun yii. Bi ọwọ ba si ti kan an , o lee taare rẹ si oju rẹ, imu tabi ẹnu rẹ. Nipasẹ bẹẹ kokoro arun yii lee wọ ara rẹ ki o si sọ ọ di alailera.

Bi o ba ni iba, ikọ tabi iṣoro lati mi, tọ awọn dokita lọ

Duro si ile rẹ bi o ba ṣakiyesi pe ara rẹ ko ya. Bi o ba ni iba, ikọ ati iṣoro lati mi, tete tọ awọn oniṣegun oyinbo lọ fun ayẹwo ati itọju. Pe wọn ni ile iwosan naa silẹ, ki wọn lee ti gbaradi de ọ.

Àkọlé fídíò, Omidan jáde láyé lẹ́yìn tí ìlú lù ú, jáa sí ìhòhò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀

Tẹti leko fun iroyin to kuna lori arun yii ki o Ma si ṣe gbagbe lati maa tẹle awọnilana eto ilera tawọn alaṣẹ ijọba lagbegbe rẹ ba fi sita.

Oniruuru iroyin lo n lọ kaakiri lori ọna ti o lee gba dena arun yii ati ohun gbogbo ti o nilo lati mọ nipa COVID-19 ti a mọ si coronavirus.

Ma si ṣe gbagbe lati maa tẹle awọnilana eto ilera tawọn alaṣẹ ijọba lagbegbe rẹ ba fi sita.

Awọn