Nigeria Basketball: Buhari yọ ikọ̀ D'Tiger, D'Tigress kúrò nídíje bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ lágbáyé fún ọdún méjì, ohun tó fàá nìyí

Awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin D'Tiger

Oríṣun àwòrán, D' Tigers/Nigeria Basketball

Ijọba apapọ Naijiria ti pinnu lati yọ ikọ agbabọọlu alapẹrẹ, (Basket ball) Naijiria ko gbọdọ kopa ni idije agbaye kankan fun ọdun meji

Bakan naa nijọba tun fẹ tu ajọ bọọlu alapẹrẹ NBBF ka nitori wahala adari to n suyọ nibẹ.

Ileeṣẹ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ lorilẹede Naijiria lo paṣẹ yii ti aarẹ Muhaamadu Buhari si buwọlu u.

Lẹta kan ti ileeṣẹ ere idaraya ijọba apapọ Naijiria kọ ṣalaye ohun top ṣokunfa igbesẹ naa.

O ni pe wọn yọ ọwọ awọn ikọ ọkunrin ati obinrin agbabọọlu apẹrẹ naa kuro lawọn idije bọọlu alapẹrẹ lagbaye nitori"oniruuru wahala ati awuyewuye to n waye eyi to ti "fẹrẹ sọ ere idaraya bọọlu alapẹrẹ di ẹdunarinlẹ" ni Naijiria.

"Eyi yoo fun Naijiria laaye lati tun ile rẹ to lẹka bọọlu alapẹrẹ bẹrẹ lati ẹsẹ kuku titi kan awọn liigi abẹle rẹ gbogbo.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Ohun to han si BBC ni pe wọn gbe igbesẹ yii lati dena ipinnu awọn agbabọọlu apẹrẹ Naijiria lati wọde lawọn idije agbaye kan tako ajọ naa ati ijọba.

Bakan naa ni inu awọn alakoso ileeṣẹ ere idaraya ni Naijiria ko dun si bi awọn agbabọọlu alapẹrẹ ṣe n da siedeaiyede to n waye laarin awọn adari lajọ ere bọọlu alapẹrẹ Naijiria ti wọn si n gbe lẹyin igun kan ninu edeaiyede naa.

Awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin D'Tigeress

Oríṣun àwòrán, D' Tigers/ Nigeria Basketball

Ki ni ewu to wa ni igbesẹ yii fun Naijiria?

Labẹ ofin ajọ ere bọọlu alapẹrẹ lagbaye, FIBA, ajọ naa koro a maa koro oju si awọn orilẹede yoowu ti ijọba ba ti n da si ọrọ iṣakoso awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ nibẹ.

Àkọlé fídíò, Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa?

Igbesẹ ti ijọba orilẹede Naijiria gbe yii lee mu ki ajọ FIBA gbegile orilẹede Naijiria lagbo ere idaraya bọọlu alapẹrẹ lagbaye- eyi si lee tumọ̀ si pe aikọ agbabọọlu alapẹrẹ orilẹede Naijiria, awọn ẹgbẹ agbabọọ̀lu alapẹrẹ gbogbo atawọn oṣiṣẹ rẹ gbogbo ko ni lanfani si awọn idije agbaye gbogbo ati ipade wọn.

BBC ti kan si ajọ FIBA fun alaye lori eyi.

Awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin D'Tiger

Oríṣun àwòrán, D' Tigers/ Nigeria Basketball

Ki ni eyi tumọ si fun ikọ agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria ?

Itumọ eyi ni pe ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin Naijiria ko ni lee kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye fawọn obinrin agbabọọlu alapẹrẹ ti yoo waye lorilẹede Australia loṣu kẹsan an ọdun 2022.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Kan lara awọn agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, Upe Atosu ni ibanujẹ ọkan nla ni igbesẹ naa jẹ fun wọn ati pe o yẹ ki ijọba atawọn alaṣẹ ere idaraya ni Naijiria o mọ pe ere idaraya kii ṣe ayo ọlọpọn ti eeyan a daaru ki o to tun un to.

"Ọna to dara julọ lati yanju ọrọ yii kọ niyi."

Awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin D'Tigeress

Oríṣun àwòrán, D' Tigers/Nigeria Basketball

Wahala wo lo ṣẹlẹ gan?

Awuyewuye eto idibo sipo awọn alakoso ajọ ere bọọlu alapẹrẹ orilẹede Naijiria, NBBF to waye lọdun mẹfa sẹyin lo ṣokunfa wahala laarin awọn alakoso nibẹ.

Lọpọ igba si ni wahala ti fẹrẹ da igbaradi awọn agbabọọlu alapẹrẹ naa fun awọn idje agbaye gbogbo ati liigi rẹ labẹle ru.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Wahala naa tun ṣe akoba fun owo oṣu akọnimọọgba ikọ obinrin agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, Otis Hugley to ko ikọ naa lọ kopa fun ati pegede fun ere idaraya agbaye Tokyo 2020, ife ẹyẹ ilẹ adulawọ fawọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ ati ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2022 titi kan bibori France pẹlu.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Bakan naa lawọn agbabọọlu alapẹrẹ lobinrin pẹlu n waako pẹlu ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alapẹrẹ ni Naijiria, NBBF ati ileeṣẹ ere idaraya lori kikuna lati san owo ajẹmọnu wọn tawọn wahala to nii ṣe pẹlu iṣakoso ikọ naa lasiko ti wọn lọ kopa ni idije Olimpiiki lorilẹede Japan.

Àkọlé fídíò, Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá