Murder in Anambra: Àjọ CAN ní ̀ìṣekúpani aláboyún Harira àti ọmọ mẹ́rin ti kọjá àlà

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ibi to ṣe ni ipinlẹ Anambra nibi ti wọn ti pa alaboyun ati awọn ọmọ rẹ mẹrin lẹẹkan naa.
Arabinrin Harira Jibril to jẹ ọmọ ilu Adamawa ni awọn agbebọn ṣekupa pẹlu oyun inu rẹ ni ipinlẹ Anambra.
Iroyin ni o ṣeeṣe ko jẹ awọn afurasi agbebon to jẹ ọmọ ẹgbẹ IPOB to n pe fun idasilẹ Biafra lo ṣe iṣẹ laabi naa.
- Òní lònìí ń jẹ́, BBC Yorùbá ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ Ipàdé Itagbangba ní Ekiti pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gómìnà
- Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina
- Ṣé lóòtọ́ ni Ààrẹ Buhari ti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele?
- Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò Jubril- ọkọ aláboyún Anambra
- Ọmọdé 19 ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣekúpani ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀ Texas
- ASUP ṣetán láti fi kún ìyanṣẹ́lódì - Ezeibe
- Irọ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dà nínú Timothy Adegoke- Ẹlẹ́rìí Adegoke
- MC Oluomo, òpin ti débá gbígba owó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko - Iléẹjọ́
- Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye
Olè, ọ̀lẹ, ẹranko to kan n dunkoko lasan ni awọn agbebọn ni Naijiria - CAN
Ninu atẹjade ti Ajọ Ọmọlẹyin Kristi nipinlẹ Kaduna fi lede ni wọn ti ni iṣekupani naa ti kọja ala, ti ko si ye ẹnikẹni mọ.
Ajọ CAN ṣapejuwe awọn apaniyan yii gẹgẹ bi ole ati ọlẹ ti kii ṣe eniyan amọ ẹranko ni wọn.
CAN ni awọn aṣekupani naa kan n halẹ, ti wọn si n dunkoko mọ awọn araalu, to fi mọ awọn ọmọde ti ko mọ nkankan.
Bakan naa ni wọn kesi ijọba apapọ lati koju oro si awọn agbebọn afurasi ikọ IPOB bi wọn ṣe se ikọ agbẹsunmọmi Boko Haram.
Iṣẹlẹ iṣekupani yii ti to gẹ! - AREWA
Ninu ọrọ ti wọn, ̣egbẹ ọdọ Ajọ Arẹwa ti iha Ariwa orilẹede Naijiria ni o ti to gẹ lori iṣekupani ojoojumọ kaakiri orilẹede Naijiria.
Bakan naa ni wọn bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbaagba lati agbegbe Guusu ila oorun Naijiria ko ṣe fọhun si iṣẹlẹ naa.
Wọn ni eleyii ko le e mu idagbasoke ba Naijiria, ti wọn si kesi ijọba lati gbe igbesẹ ni kiakia.
Bẹẹ si ni wọn kesi awọn gomina ni Guusu ariwa Naijiria lati gbe igbesẹ ki opin de ba ipaniyan awọn ara Ariwa Niajiria ti ko lẹṣẹ lọrun.
- Afurasí 4,000 la fi ṣìkùn òfin mú láàrín ọṣù márùn ún- Amotekun Ondo
- Kò sí ààyè fawọn ọdaràn tó ń ṣiṣẹ́ ibi mọ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra- Gómìnà Soludo
- Ta ni Anamekwe Nwabuoku tí ìjọba yàn láti delé sí ipò olùṣirò owó àgbà ní Nàìjíríà (AGF)?
- Àwọn Jàǹdùkú kọlù alága àjọ tó ń ṣètò eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- A kò ní sinmi títí tí àlááfíà yóò fi padà sí Naìjíríà- Buhari
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye méjìdínlógún kò sí pámpẹ́ ọlópàá Ekiti lórí ikú èèyàn méjì
- Àwọn ọmọ bíbí Arewa ní àwọn ọlọ́kada láti orílẹ̀-èdè míràn ló ń dáràn nípínlẹ̀ Eko
Awọn to ṣekupa oloyun ati awọn ọmọ rẹ ko ni lo lai jiya - Gomina ipinlẹ Anambra.
Gomina Ipinlẹ Anambra, Ọjọgbọn Chukwuma CharLes Soludo ti ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣelẹ iṣekupani Harira ati awọn ọmọ mẹrin ni ilu Anambra.
O ni bio tilẹ jepe wọn ko tii le sọ awọn to wa ni idi iṣẹlẹ naa amọ o fi da awọn eniyan loju pe idajọ otitọ yoo jọba lori iṣẹlẹ naa.
Gomina naa fikun un pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ni awọn yoo fi jofin.
Bakan naa lo ni gbogbo ọmọ Naijiria lo laṣẹ lati gbe ibi to wu wọn lai fi iti ẹya, ẹsin tabi ẹlẹyamẹya ṣe.
Gomina ipinlẹ Anambra naa fi da awọn ọmọ Naijiria to n ṣe karakata ni ipinlẹ Anambra loju pe ijọba ti n gbe igbesẹ lati ripe aabo to daju wa fun gbogbo awọn olugbe agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Soludo tv
Gomina ipinlẹ Anambra Chukwuma Soludo ti fi ẹmi ifarajin ijọba rẹ han lati koju ipenija aabo to deba ipinlẹ rẹ.
Kò sí ààyè fawọn ọdaràn tó ń ṣiṣẹ́ ibi mọ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra- Gómìnà Soludo
O fi ọrọ yi lede lasiko ipade kan pẹlu awọn oludije ipo labẹ asia ẹgbẹ oselu All Progressives Grand Alliance (APGA) eyi to waye ni ile ijọba ni Amawbia, lọjọ Aje.
Soludo tẹpẹlẹ mọ pe awọn ọdaran kan lo wa nidi iwa ijinigbe, ipaniyan ati awọn iwa ọdaran orisirisi eleyi to yapa kuro lọna awọn to ni erongba oselu lọkan.Inú Nnamdi Kanu kò dùn sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó ń wáyé ní Anambra- Agbẹjọ́rò Kanu
O sọ pe ''Wọn ti ṣe doju rẹ bayi...ko si ibi ti yoo gba awọn ọdaran ni Anambra lati ṣe iṣẹ aburu wọn nitori ijọba n gbe gbogbo igbesẹ lati koju ipenija aabo yi ati dida alaafia pada sipinlẹ wa''.
- Ta ni Anamekwe Nwabuoku tí ìjọba yàn láti delé sí ipò olùṣirò owó àgbà ní Nàìjíríà (AGF)?
- Ẹgbé òṣèlú PDP kédé èsÌ ètò ìdìbò abẹ́lé tó wáyé ni ìpínlè Ọ̀yọ́
- Wo ohun tó yẹ kóò mọ̀ nípa aàrùn 'Monkeypox' tó gbòde kàn ní àgbáyé
- Ẹgbé òsèlú méje darapọ̀ mọ́ ẹgbé òṣèlú Labour Party fún Ètò ìdìbò Ààrẹ
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Àwọn ọmọ bíbí Arewa ní àwọn ọlọ́kada láti orílẹ̀-èdè míràn ló ń dáràn nípínlẹ̀ Eko
- A kò ní sinmi títí tí àlááfíà yóò fi padà sí Naìjíríà- Buhari
- Àwọn Jàǹdùkú kọlù alága àjọ tó ń ṣètò eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Oyo
Kini awọn ọdọ guusu ila oorun n sọ bayii?
Ẹwẹ, awọn agbarijọpọ ẹgbẹ ọdọ kan ni ilẹ Igbo ti ke gbajare lori ọwọja ipaniyan to n waye ni ipinlẹ Anambra.
Wọn ni iwa jijẹ eeyan bi ẹran lati ọwọ awọn alaburu yi ti wa gbalẹ kaakiri ilẹ Igbo.
Wọn rọ Gomina Soludo lati se agbekalẹ ikọ alaabo ti yoo da alaafia pada si ipinlẹ ọhun.
Lasiko ti wọn n fẹdun ọkan han lori ipaniyan awọn eeyan meje kan ati asofin ilẹ naa to fi mọ pipa abiyamọ kan ati awọn ọmọ rẹ mẹrin, wọn ni awọn alaburu yi ti sọ ilẹ igbo di aayẹ ipaniyan ni ipakupa.
Bakan naa ni Kọmisọnna ọlọpaa Anambra ti fajuro lori bawọn abule ati ileto se n fa tikọ lati ta awọn alasẹ lolobo nipa igbesẹ awọn ọdaran lagbegbe wọn.
Kọmisọnna Echeng Echeng, sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ to si ni awọn agbofinro ti mọ awọn ọdaran yi ati pe awọn ko ni pe mu wọn.
- Ilé ẹjọ́ wọ́gilé àfikún ẹjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ pè tako Nnamdi Kanu
- A bá òkú Akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan nílé ìyàgbẹ́ to ṣì dì ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ mú - Aráàdúgbò
- Ohun tó yẹ kí ìjọba ṣe nìyí bí wọ́n ṣe ń dá ẹ̀jọ́ ìkú Deborah Samuel- Agbẹjọrò Kayode Ajulo
- A kò fi ti gbèdéke June 1 ṣe, a ti fòfin de ọ̀kadà, kèké ní Eko
- "₦20,000 ló kàn mí lẹ́yìn tí a ja Iléeṣẹ́ rédíò Yinka Ayefele lólè ní Ibadan"
- Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn dáná sun ilé mẹ́fà, ṣọ́ọ̀bù méje ní Bauchi lórí ẹ̀sùn sísọ̀rọ̀ òdì sí Islam
Echeng ni irọ lasan ni ọrọ pe ko si ẹni to mọ awọn agbebọn yi tawọn eeyan fi n pe wọn ni ''unknown gunmen.''.
O ni orukọ to yẹ wọn kọ niyi bi kii se pe ki wọn pe wọn ni ọdaran ti wọn jẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Inú Nnamdi Kanu kò dùn sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó ń wáyé ní Anambra- Agbẹjọ́rò Kanu
Nnamdi Kanu fajúro lẹ́yìn tí wọ́n gé orí aṣòfin ní Anambra
Ọkan lara awọn agbẹjọro, Nnamdi Kanu, Ifenayi Ejiofor, ti sọ pe inu ajijagbara naa ko dun si awọn iṣẹlẹ iṣekupani to n waye ni ipinlẹ Anambra.
Ejiofor sọ ninu atẹjade kan pe o jẹ ohun iyalẹnu fun Kanu funra rẹ pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ n waye ni ipinlẹ ọhun.
Ọrọ yii lo n jade lẹyin iku ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Okechukwu Okoye, ti wọn ge ori rẹ lẹyin ti wọn kọkọ ji gbe tan.
- Ẹgbé òsèlú méje darapọ̀ mọ́ ẹgbé òṣèlú Labour Party fún Ètò ìdìbò Ààrẹ
- A kò ní sinmi títí tí àlááfíà yóò fi padà sí Naìjíríà- Buhari
- Àwọn Jàǹdùkú kọlù alága àjọ tó ń ṣètò eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe, ẹ̀gbè òsèlú APC sún àyẹ̀wò fún àwọn olujide fún ipò Ààre síwájú
- Àwọn ọmọ bíbí Arewa ní àwọn ọlọ́kada láti orílẹ̀-èdè míràn ló ń dáràn nípínlẹ̀ Eko
Ṣaaju ni awọn agbebọn kan ti kọkọ ji Okoye ati alabaṣiṣẹ rẹ, Cyril Chiegboka gbe niluu Aguluzigbo Umiona, to wa ni ijọba ibilẹ Aguata, ni ipinlẹ naa.
Ejiofor ni "Ko ṣeeṣe ki inu adari ẹgbẹ ajigbara Biafra dun si bi wọn ṣe pa Okechukwu Okoye ni ipakupa."
"Ẹyin ọmọ Igbo, awọn ẹlẹmi mujẹ-mujẹ ti wọ ilẹ wa."
"Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe idarudapọ ti de ba eto abo iha Guusu ila oorun Naijiria, o si ti kọja ojuẹ."
"Amọ mo fẹ ko ye yin ni wakati yii pe onibara mi, Nnamdi Kanu funra rẹ gan yoo banujẹ lori irufẹ ifẹmiṣofo to n waye nilẹ wa."
Ọlọpaa bẹrẹ iwadii:
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn kan ṣe bẹ ori amofin to jẹ ọmọ ipinlẹ Anambra.
Ọlọpaa ni awọn ṣawari oku Okechukwu Okoye lẹyin nnkan bii ọsẹ kan ti awọn ti n wa okunrin naa.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe pa amofin naa ni ipakupa.
Gomina ipinlẹ, Anambra Charles Soludo, ti juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyii ti ko bojumu, to si buru jai.
Soludo ti wa kede ẹbun owo fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa.
Amọ titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, a ko tii le sọ awọn to wa nidi iṣekupani ọhun

Oríṣun àwòrán, Others
Soludo kéde ẹ̀bùn N10m fún ẹni tó bá mú agbébọn tó gé orí aṣòfin Anambra, Okechukwu
Èyí ni bí àwọn agbébọn ṣe pa Họ́nọ́rébù Okechukwu Okoye tí wọ́n sì gé orí rẹ̀ sọnù ní ìpínlẹ̀ Anambra
Gomina ipinlẹ Anambra, Ojogbon Chukwuma Suludo tí oun setan lati fun ẹnikẹni ti o ba ran ìjọba lọwọ lati mu awọn agbebon to se iku pa ọmọ ilẹ asofin Okechukwu Okoye ni milionu mewa naira.
Gomina ni iṣẹlẹ naa jẹ oun ibanuje fun ara ipinlẹ Anambra, tí àwọn sí setan lati fi ida ofin mu awọn ọmọ agbebon naa lai fi asiko sofo.
Okoye ẹni ti o soju apa Aguata kejì ni ile asofin ipinlẹ pẹlu amugbalegbe rẹ ni awọn ọmọ agbebon jigbe ni ojo keedogun ni apopana.
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní iṣẹ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí Alàfáà tí wọ́n jígbé ní Ondo
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye méjìdínlógún kò sí pámpẹ́ ọlópàá Ekiti lórí ikú èèyàn méjì
- 'Panel Beater' méjì ya odi òjijì lẹ́yìn tí alága ẹgbẹ́ mọkáláìkì tẹ́lẹ̀ gbá wọn l'étí ní Eko
- Ọlọ́pàá ìpínlẹ Ogun mú olùkọ́ tó fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lòpọ̀
- Ìjọba Eko fún àwọn ọlọ́jà Alaba Rago ní gbèdéke láti fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún àtúnṣe
- Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbìyànjú láti dóòlà Deborah, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèrò borí wọn - Gómìnà Tambuwal
- Wo ohun tí iléeṣẹ́ ológun ṣe fun obìnrin yìí lẹ́yìn ọdún Mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí wọ́n gba àkàrà òyìnbó lọ́wọ́ rẹ̀
Soludo ninu atesita kan tí agbenuso, Christian Aburime buwolu lati ba awọn molebi kẹdun sọpe pẹlu ibanuje ọkan ni oun fi gbo iroyin nípa iku asofin naa.
"Awọn ọmọ agbebon yii ni o sẹku pa awọn olopaa mẹta níbi ọdun meji sẹyin, a mọ ìjọba ipinlẹ Anambra ti setan lati fowosopo pẹlu awọn ara ilu ati pe ìjọba ipinlẹ Anambra yio fun ẹnikẹni ti o ran ìjọba lọwọ lati mu awọn ọmọ agbebon yìí ni milionu mewaa naira.
Gomina Soludo wa fi ọkan awọn ara ilu balẹ pe ìjọba ipinlẹ labe oun pẹlu ajosepo awọn eleto abo yio dẹkun awọn iwa ajinigbe ti o ti gba ilu

Oríṣun àwòrán, okechukwu okoye / facebook
Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ?
Awọn agbebọn kan ti ẹnikẹni ko mọ nipa wọn ti pa ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Anambra kan, Okechukwu Okoye.
Wo bí àwọn agbébọn ṣe pa Okechukwu Okoye, aṣòfin kan ní ìpínlẹ̀ Anambra tí wọ́n sì gé orí rẹ̀ sọnù
Awọn agbebọn naa ti ọpọ mọ si "Unknown gunmen" ji aṣofin Okoye to n ṣoju ẹkun idibo Aguata II nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Anambra ati amugbalẹgbẹ rẹ, Cyril Chiegboka gbe ni ọjọ karundinlogun, oṣu karun un, ọdun 2022 lasiko ti wọn fi n rinrinajo kan.
- Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ilé mẹ́fà, ṣọ́ọ́bù méje ní Bauchi nítórí obìnrin tí wọ́n ló bú Ànọ́bì lórí Whatsapp
- Wo ohun tí iléeṣẹ́ ológun ṣe fun obìnrin yìí lẹ́yìn ọdún Mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí wọ́n gba àkàrà òyìnbó lọ́wọ́ rẹ̀
- Fífẹ̀ ju ìyàwó kan lọ ni àṣírí ẹ̀mí gígùn'
- "Ogun ló gbé mi lọ sí Central African Republic, àmọ́ ọmọ ni mo gbé bọ̀"
Aṣofin Okechukwu Okoye lo n ṣoju ẹkun idibo ilu ti gomina ipinlẹ Anambra, Charles Soludo, ti wa.
Ni agbegbe Aguluzigbo Umiona, ni wọn ti ji aṣofin Okechukwu Okoye gbe gẹgẹbi ọlọpaa ṣe sọ ki wọn to wa ri oku rẹ lọjọ Abamẹta.
Alaye lori bi wọn ṣe ji aṣofin Okechukwu Okoye gbe
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra, DSP Ikenga Tochukwu, ṣalaye ninu atẹjade kan pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati tu u silẹ ni kete ti iroyin tẹ wọn lọwọ pe wọn ti ji aṣofin naa gbe.
Ati wi pe igbesẹ naa ṣi n lọ lọwọ lasiko ti awọn kan ri oku kan ti wọn ti ge ori rẹ kuro ni opopona Nnobi si Ideani ni nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ.
"Ayẹwo nipa ara naa fihan pe ara aṣofin Okechukwu Okoye ni. A si ti gbe e si ile igbokupamọsi"
Lẹyin eyi ni wọn ri ori rẹ ti wọn ge kuro lọjọ kan naa lagbegbe ijọba ibilẹ Gusu Nnewi ni bi ti wọn fi kọ si.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra ti ṣapejuwe iku Họnọ̀rebu Okoye gẹgẹ bi iwa ika to buru jai.
Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ naa, Echeng Echeng ni awọn ko ni ṣalai mu awọn to pa aṣofin naa bi o ti wulẹ o mọ
Gomina Charles Soludo ṣeleri ẹbun owo N10 miliọnu lori iku Họnọrebu Okoye
Gomina ipinlẹ Anambra, Ọjọgbọn Charles Chukwuma Soludo ti bu ẹnu atẹ lu iku aṣofin Okechukwu Okoye ti ọpọ mọ si "Okey Di Okay."
O tun ṣeleri miliọnu mẹwa Naira gẹgẹ bi ẹbun owo fun ẹnikẹni to ba lee mu iroyin ti yoo ran awọn agbofinro lọwọ lati ṣawari awọn amokunṣika ẹda to ṣe iṣẹ laabi naa.

Oríṣun àwòrán, Soludo tv
"Pẹlu ẹdun ọkan ati ibanujẹ nlanla ni Ọjọgbọn Chukwuma Charles Soludo gbọ iroyin bi wọn ṣe pa Họnọrebu Okechukwu Okoye, aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Aguata II nileegbimọ aṣofin ipinlẹ yii ati amugbalẹgbẹ rẹ Cyril Chiegboka.
"Ni jọ karundinlogun oṣu karun un lawọn apaniyan wọnyii ji Họnọrebu Okoye ati Cyril Chiegboka gbe loju ọna."
Gomina Soludo ba awọn mọlẹbi aṣofin naa nilu Isuofia kẹdun.
O ni o ṣeeṣe ki awọn to pa honọrebu Okoye jẹ ẹgbẹ ọdaran kan naa to kọlu oun lọdun meji sẹyin ti wọn si pa ọlọpaa mẹta.
O ni awọn ọdaran yii ko lee gba ijọba lẹkun Usofia tabi ni ipinlẹ Anambra.
O wa ṣeleri lati mu awọn ọdaran to ṣiṣẹ laabi naa ati gbogbo awọn to n da ipinlẹ naa laamu.





















